Ìwádìí BBC rèé lórí ẹ̀sùn àjẹbánu ₦44m táwọn aṣòfin Ondo fi kan Olórí ilé tí wọ́n fi ni kó fipò sílẹ̀

Aworan ile asofin ipinlẹ Onod to jẹ alaja kan, mọto mẹta wa ni ayika rẹ

Oríṣun àwòrán, Ondo House of Assembly

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lati bii ọjọ meji sẹyin bayii ni oniruuru awuyewuye ti n jẹ jade lori awọn aṣofin ile igbimọ aṣofin ni ipinlẹ Ondo.

Iroyin ni awọn aṣofin naa fun olori ile aṣofin ti i ṣe Olori wọn; Olamide Oladiji,ni gbedeke di ọjọ Aiku, ọjọ Kẹrindinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2026 lati kọwe fipo rẹ silẹ bibẹẹkọ awọn maa yọ nipo.

Eyi lo mu BBC News Yoruba kan si alaga igbimọ ile lori iroyin, Olatunji Fabiyi lati mọ idi ti ile fi n gbe igbesẹ lati yọ olori ile naa nipo rẹ.

Olamide Oladiji, Abẹbugan ile igbimọ aṣofin

Oríṣun àwòrán, Olamide Oladiji/ Facebook

Ẹsun ti ile igbimọ fi kan olori wọn

Nigba to n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun BBC News Yoruba, Fabiyi sọ pe idi ti awọn fi gbe igbesẹ naa ko ṣẹyin ẹsun pe olori ile aṣofin naa ati igbakeji rẹ, ṣagbeyẹwo aba isuna ajọ to n ri si idagbasoke awọn ẹka to n pese epo rọbi ni ipinlẹ Ondo, (OSOPADEC).

O ni wọn si buwọlu u lorukọ gbogbo awọn ọmọ ile aṣofin lai si imọsi awọn nibẹ.

O fi kun pe olori ile naa tun gbe miliọnu mẹrinlelogoji naira ninu aba isuna ajọ naa gba oko ibomiran.

Fabiyi sọ pe awọn aṣofin mọkanlelogun ninu awọn mẹrindinlọgbọn to wa nile aṣofin naa ni wọn ti buwọlu iwe pe awọn ko fẹ ki olori ile naa dari awọn mọ nitori o ti tapa si ofin to de ọfiisi rẹ.

O fi kun pe ọrọ naa ko fa ija tabi mu ifanfa dani rara, nitori gbogbo awọn ọmọ ile to n binu lori iṣẹlẹ naa ti fi ọrọ naa to gomina leti to si ti ba awọn da si.

O ṣe afọmọ rẹ pe ki i ṣe pe awọn n ditẹ mọ ijọba tabi gbiyanju lati tapa si awọn alaṣẹ, bikoṣe pe awọn fẹ fi han pe iwa ti olori ile naa hu lodi si ofin, to si jẹ ohun to le gbe de ọgba ẹwọn.

O fi kun un pe awọn ko ba olori ile fa ijangbọn, awọn wulẹ sọ fun un pe ko kọwe fipo silẹ ni, amọ ẹbẹ lo n bẹ.

"Gomina ko dawa lọwọ kọ lori igbesẹ yii, o ni ka ni suuru di ọjọ Aiku ni"

Nigba to n ṣalaye nipa ipa ti Gomina Lucky Aiyedati wa n ko lori ọrọ yii, Fabiyi sọ pe gomina ni olori ilu, o ti gbọ nipa ọrọ naa o si ti da si i.

O ni Gomina Aiyedawati ko da awọn lọwọ kọ lori igbesẹ tawọn fẹ gbe, o kan ni kawọn ni suuru di ọjọ Aiku ni.

"Gomina ni ka ni suuru di ọjọ Isinmi ọsẹ yii, o ti pe wa lẹẹmeji tẹlẹ a si ti dahun, a n reti ipe rẹ lẹẹkẹta si i.

N jẹ bi gomina ba ni ki wọn ma yọ Oladiji nipo, ṣe wọn yoo gba si I lẹnu ni BBC beere lọwọ Fabiyi, o si dahun pe aarin awọn ati gomina ni iyẹn wa.

Amọ gbogbo aayan BBC News Yoruba lati gbọ ti ẹnu olori ile asofin nipinlẹ Ondo, Olamide Oladiji, lori awọn ẹsun ti wọn fi kan, lo ja si pabo.