'Ẹ̀yin nìkan kọ́ ló ń kojú ìṣòro iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì' - Ààrẹ Adama Barrow sọ̀rọ̀ lórí ìwọ́de ìdákúrekú iná tó ń wáyé ní Gambia

Aworan iwọde naa ati aarẹ Barrow

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ orilẹede Gambia Adama Barro ti rọ awọn eeyan orilẹede naa lati fi ọkan balẹ nitori ọrọ idakureku ina ọba to n waye lẹnu lọwọlọwọ yii lorilẹede naa pẹlu idaniloju pe arun to n ṣe ọgọfa lo n ṣọọdunrun, ohun to n ṣe abọyade gbogbo ọlọya lo n ṣe. Idakureku ina kii ṣe ọrọ tiwọn nikan, ọpọ orilẹede lẹkun iwọ oorun Afrika lo n ṣe.

Ni ọjọ Aje ọpọlọ iwọde lo waye lalẹ ọjọ naa ni ilu Banjul tii ṣe olu ilu orilẹede Gambia atawọn agbegbe rẹ lori aisi ina mọnamọna eyi tawọn eeyan kan lorilẹede naa sọ pe o ti n lọ fun bii wakati mejidinlaadọta.

"Nigba ti ẹ ba sun sinu okunkun ati oru yii, ẹ ranti pe ẹyin nikan kọ lẹ wa ninu okunkun naa", ni alaye ti Aarẹ Barrow ṣe fun awọn eeyan rẹ pẹlu ileri lati tubọ ṣe alekun ina mọnamọna lorilẹede naa nigba ti yoo ba fi di osu to n bọ.

Yatọ si ina to n pese albẹlẹ, orilẹede Gambia tun maa n ra ina mọnamọna lati amuleti rẹ, iyẹn orilẹede Senegal ati Guinea.

Aworan awọn to n jo ina lati ṣe iwọde.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lati oṣu kẹfa ọdun yii ni idakureku ina ti bẹrẹ, leyi to ti mu ki mimu ina mọnamọna lọ di eyi to n waye lemọlemọ, to ba si waye bẹẹ wọn kii tete mu u wa pada lasiko yii to jẹ wi pe akoko oru lo jẹ nibẹ, eyi to mu ki pataki ina ọba tubo ga sii.

Bi ọrọ ṣe ri yii lo mu ki awọn oluwọde kan lorilẹede naa fọn si igboro ilu Banjul ti wọn n jo taya ọkọ, ti wọn si n di awọn ọna gbogbo nibẹ lati fi ẹhonu han lori idakureku ina ọba nibẹ.

Awọn ọlọpaa lo afẹfẹ tajutaju tia gaasi lati fi tu awọn oluwọde naa ka lagbegbe Westfeild bi wọn ṣe n kọri si olu ileeṣẹ ipese ina mọnamọna, Nawec, ti awọn kan si n pariwo. "Barrow gbọd lọ".

Awọn oluwọde tun ko ara jọ si iwaju ile igbakeji aarẹ orilẹede naa ni ilu Farato, nibi ti wọn ti ba awọn aṣọ alakọle ẹgbẹ oṣelu National People's Party to n ṣe ijọba lorilẹede naa jẹ.

Ki ni Aarẹ Barrow sọ̀ nipa iwọde naa?

Aworan awọn to n jo ina lati ṣe iwọde ati ọkunrin kan to kunlẹ pẹlu ọwọ ọtun rẹ loke, awọn ọkọ ọlọpaa wa lokeere.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu ọrọ to ba awọn eeyan orilẹede naa sọ lori mohunmaworan lalẹọjọ Iṣẹgun, aarẹ orilẹede Gambia Barro ka sawọn eeyan orilẹede naa lati dakun dabọ fiye denu nitori pe oun ko ṣa mọ inira ti aisi ina mọnamọna n mu ba ẹnikọ̀ọkan wọn, amọ o ṣekilọ pe biba awọn dukia ilu jẹ kọ ni ọna abayọ nitori pe ori bibẹ kọ logun ori fifọ. O ni owo to yẹ ki ijọba fi ṣe awọn nnkan miran fun anfani ilu ni yoo tun maa na fi ṣa atunṣe awọn ohun to ba bajẹ.

O ni lootọ kudiẹkudiẹ wa lawọn eto ti ijọ̀ba gbe kalẹ, ilana akojọ ina mọnamọna ati amojuto rẹ, to si tọka si iṣẹlẹ idakureku ina naa gẹgẹbi "ipenija nla fun ọrọ abo" ati iṣẹlẹ "pajawiri".