Kí ló mú Arsenal lulẹ̀ pẹ̀lú èròngbà rẹ̀ láti ra Osimhen àti Alvarez wá sí Premier League? Ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awuyewuye ṣi n lọ lori ayelujara lori ọja kata kara awọn agbabọọlu Premier League to wa sopin lalẹ ana ọjọ Iṣẹgun.
Awọn agbabọọlu kan lanfaani lati darapọ mọ ikọ agbabọọlu tuntun, nigba ti awọn mii ko rọna lọ si ẹgbẹ agbabọọlu tuntun.
Ni ṣe ni ori ayelujara n yọ eruku lala lati aarọ ọjọ kinni oṣu Kẹsan an ti i ṣe gbedeke ọjọ ti ọja kata kara awọn agbabọọlu wa si opin ni Premier League to fi di alẹ ana.
Agbabọọlu bii Enzo Fernandez lanfaani lati darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Man City lọjọ Iṣẹgun yii, amọ, nnkan ko ṣẹnu ire fun Arsenal latari bi ẹgbẹ agbabọọlu naa ṣe kuna lati ra agbabọọlu kankan lọjọ Iṣẹgun ti ọja kata kara awọn agbabọọlu wa sopin.
Wọnyii ni awọn agbabọọlu to lanfaani lati darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu tuntun atawọn ti ko rọna lọ si ẹgbẹ agbabọọlu tuntun.
Victor Osimhen
Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal gbiyanju lati ra ẹlẹsẹ ayo ọmọ Naijiia, Victor Osimhen, to n gbabọọlu fun Galatasaray lorilẹede Turkey.
Koda, iroyin fi idi rẹ mulẹ pe Arsenal ba Galatasaray sọrọ lori ati gbe Osimhen wa si ilu London lati maa gbabọọlu fawọn Gunners.
Amọ, lẹyin o rẹyin, Osimhen ko kuro ni ikọ agbabọọlu Galatasaray nitori Arsenal kuna lati ra a wa si ilu London.
Julian Alvarez
Ẹlẹsẹ ayo, Julian Alvarez, jẹ agabọọlu mii ti Arsenal fi erongba rẹ han lati ra ki o le darapọ mọ ikọ Gunners.
Bo tilẹ jẹ pe Alvarez to n gbabọọlu fun Atletico Madrid lorilẹede Spain ti sọ pe ikọ agbabọọlu Barcelona loun fẹ darapọ mọ, Arsenal ṣi gbagbọ wi pe o ṣee ṣe ki ẹlẹsẹ ayo Argentina naa yi ọkan rẹ pada lati darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Gunners.
Ikọ agbabaọọlu Atletico Madrid yari wi pe awọn ko ni ta Alvarez fun orogun awọn Barcelona laelae.
Lẹyin o rẹyin, Arsenal pada mofo tori Alvarez ko darapọ mọ wọn, bakan naa si ni Atletico ko jẹ ko lọ si Barcelona.
Eyi tumọ si pe Atletico Madrid ni Alvarez yoo ṣi maa ṣoju ninu ere bọọlu lati asiko yii titi digba ti ọja kata kara awọn agbabọọlu mii yoo fi ṣi.
Enzo Fernandez
Agbabọọlu aaringbungbun fun orilẹede Argentina, Enzo Fernandez, darapọ mọ ikọ agbabọọlu Manchester City lọjọ kinni oṣu Kẹsan an ti i ṣe ọjọ ti ọja kata kara awọn agbabọọlu Premier League wa sopin.
Man City ati Chelsea ti n sọrọ tipẹ lori iye ti Chelsea fẹ gba lori Enzo to si dabi ẹni pe ẹnu wọn ko ni ko.
Ṣugbọn o ya ọpọ lẹnu nigba ti Man City ra Enzo fun obitibiti owo £125m lati Chelsea ti o si darapọ mọ iko akọnimọọgba Enzo Maresca.
Lamine Camara
Enzo Fernandez lanfaani lati darapọ mọ Man City, amọ, Chelsea kuna lati ra Lamine Camara ti wọn fẹ fi rọpo rẹ lati ikọ agbabọọlu Monaco lorilẹede France.
Camara yoo si duro si ẹgbẹ agbabọọlu Monaco bayii lẹyin ti igbiyanju Chelsea lati ra a fun £47.1m foriṣanpọn.
Agbabọọlu ọhun to jẹ ọmọ ọdun mejilelogun ṣe ayẹwo ara rẹ ṣaaju ko to darapọ mọ Chelsea nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, amọ, ọrọ bẹyin yọ lẹyin ti ọja kata kara wa sopin laago mọkanla alẹ ọjọ Iṣẹgun.



























