BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Wo àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ láti kékeké tí àyẹ̀wò DNA sọ pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni wọ́n
Ile ọmọ alainiya ni obi ọtọọtọ ti gba Meena Geltink ati Minal Tijssen tọ ni nnkan bi ogoji ọdun o le diẹ sẹyin ni orilẹede Netherlands.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ Iru Ekun yóò máa lo ìfúnpá, olóńdè àti ayẹta yàtọ̀ sí ìbọn - Sunday Igboho ṣàlàyé níbi ìfilọ́lẹ̀ Iru Ekun ní ìpínlẹ̀ Èkó
Igboho tun fi idi rẹ mulẹ wi pe ijọba yoo ṣe igbaradi fawọn ẹṣọ Iru Ekun ni ipinlẹ Eko ki wọn to bẹrẹ iṣẹ.
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé o lè ta epo bẹntiróòlù fúnra rẹ láì nílò ìrànlọ́wọ́ ẹnikẹ́ni nílé epo? Ohun tí o ni láti ṣe rèé
Eto ti NNPC ṣẹṣẹ gbe kalẹ yii ti fawọn onibaara lanfaani lati ra epo sinu ọkọ tabi jẹrika funra wọn lai nilo iranwọ ẹnikẹni nile epo.
Akẹ́kọ̀ọ́ 24 jóná mọ́lé níléẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀, 21 míràn wà lẹ́sẹ̀-kan-ayé-ẹsẹ̀-kan-ọ̀run
Ọmọdebinrin mọkandinlogun ati ọmọdekunrin marun un ni ina naa jo pa.
Ṣé dátà 100mb yóò tó akẹ́kọ̀ọ́ láti kàwé lórí ayélujára lóòjọ́?
Ijọba ni awọn akẹkọọ lati ile ẹkọ girama agba titi de fasti ni ọrọ naa yii kan.
Mo ti tẹ̀ fún Ọlọ́rùn, mi ò lè yẹ̀bá fún èèyàn mọ́, ẹ lọ fọkàn balẹ̀, mo máa dupò Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo lọ́dún 2027 – Oriyomi Hamzat
Oriyomi toun ati Họnarebu Olakunle Busari tawọn eeyan mọ si Gudugudu jọ n sọ pe awọn mejeeji ni oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ Oyo sọrọ yii ninu fọnran kan to fi lede lori ayelujara.
Àrùn diphtheria tó pa ọmọdé méje ní Imo ti rápálá wọ ìpínlẹ̀ Eko, wo bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ
Kọmiṣọna eto ilera, Akin Abayomi to fi ikede naa sita lọjọru sọ pe awọn ti n ṣetọju eeyan mẹfa to ko nigba awọn ti bẹrẹ si n wa awọn eeyan ti awọn eeyan naa ti farakan ṣaaju.
Ìpolongo ìbò Gómìnà bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ètò ìdìbò 2027, àmọ́, ìgbà wo ni Oriyomi àti Gudugudu yóò mọ ìpín wọn fẹ́gbẹ́ Accord l'Oyo?
Oṣisẹ ajọ INEC kan to sọrọ ṣalaye wi pe edeaiyede to wa ninu ẹgbẹ oṣelu Acoord ni ko jẹ ki orukọ oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu naa ko wa lara awọn orukọ awọn ti yoo dije dupo gomina ipinlẹ Oyo lati ẹgbẹ oṣelu naa.
Orí mi ni Garuba fẹ́ gé féú, ọwọ́ tí mo fi dáàbòbo ara mi, ló padà fi àdá ọwọ́ rẹ̀ gé – Adájọ́ tí olújẹ́jọ́ fi àdá gé lọ́wọ́ lásìkò ìgbẹ́jọ́ sọ̀rọ̀ síta
Awọn eeyan to wa ninu yara igbẹjọ lo ka ọkunrin naa lọwọ ko, gba ada ọwọ rẹ ti wọn si gbe adajọ lọ sile iwosan fun itọju
Ṣé òótọ́ ni pé àgbo jẹ̀dí tí wọ́n fi ògógóró pò ló gbẹ̀mí ọ̀gọ̀rọ̀ èèyàn l'Ondo?
Oniruru ilu ni iku naa ti waye ninu eyii ti Odigbo, Newtown ati Orita wa lara rẹ, to fi mọ Araromi-Obu.
APC fagilé ẹjọ́ tí wọ́n pè tako èsì ìdìbò gómìnà ìpínlẹ́ Osun tó gbé Adeleke wọlé fún sáà kejì
Amofin Seyi Oyagbile lo pe ẹjọ naa lọjọ kẹjọ oṣù Kẹsán an yii lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC ati lorukọ oludije ẹgbẹ naa, Bola Oyebamiji.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
'Aago meji oru ni mo dele; ọ́fíìsì ni màá sùn lọjọru' - aráàlú kojú ìnira, ìdádúró ọ̀pọ̀ wákàtí lópópónà Eko sí Ibadan nítorí àtúnṣe afárá Kara, ìgbà tí yóò parí
Akọroyin BBC to gba oju ọhun jabọ pe sunkẹrẹ-fakẹrẹ naa bẹrẹ lati ọsan, o si gun lati afara Kara nipinlẹ Ogun titi de agbegbe 7Up niluu Eko.
Wo bí ètò ìsínkú gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Temitope Osoba tó jáde láyé láìpẹ́ yìí yóò ṣe lọ
Titi di asiko yii ni awọn oṣere tiata, to fi mọ awọn ololufẹ ere tiata nilẹ Naijiria ati kaakiri agbaye ṣi n kẹdun iku obinrin naa, ti wọn si n sọ pe awọn yoo ṣafẹri rẹ, paapaa lori awọn igbesẹ akikanju to gbe nigba aye rẹ.
Kí ló tún wú ọ̀rọ̀ àkọsílẹ̀ Tinubu pẹ̀lú ọlọ́pàá FBI Amẹrika nípà egbòogi olóró síta? Àlàyé rèé
Ọpọ eeyan papaa julọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ni Naijiria lo beere wi pe ki Amẹrika gbe akọsilẹ igbẹjọ Tinubu lori ọrọ egboogi oloro jade.
Kí ni èrè rẹ nínú ilẹeṣẹ ìfọpo Dangote bayìí tí iléeṣẹ́ náà yóò bẹ̀rẹ̀ sí ń ta ìpín rẹ̀? Àlàyé rèé
Dangote sọ pe iye to kere julọ ti eeyan kan le ra ninu ipin naa ni mẹwaa pere, ti iye rẹ jẹ N5,250.
Ṣé lóòótọ́ ni wọ́n lẹ òkò mọ́ Peter Obi ní Benue? Ohun tí a mọ̀ rèé
Peter Obi lo lọ si ipinlẹ Benue pẹlu erongba lati kẹdun ikọlu to waye lagbegbe Yelwata laipẹ yii, nibi ti ọpọ eeyan ti ba ikọlu naa lọ sọrun aremabọ, ti ọpọ si farapa.
''Ọmọ mi mẹ́ta ni mo tà, N300,000 ni mo ta ìbejì mi, ṣọ́ọ̀bù tí mo ti ń tàgbo tó jóná ló sọ mí di gbọ́mọ-gbọ́mọ''
Afurasi gbọmọ-gbọmọ naa sọ pe obinrin kan tawọn jọ ṣiṣẹ pọ lọja Ogeere lo kọ oun bi eeyan ṣe maa n ji ọmọ gbe.
APC sẹ́, PDP sẹ́, ta ló wá pe ẹjọ́ tako gómìnà Adeleke níléẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìdìbò gómìnà l'Osun?
Akọroyin BBC Yoruba to lọ si ọọfisi igbimọ naa, to si fi oju gaani iwe ipẹjọ ọhun fidi rẹ mulẹ pe APC ati PDP lo pe ẹjọ naa.
Kí ló dé tí àwọn ẹ̀yà Tigray ní Ethiopia ṣe ń sọ pé àgbà Olóyè Obasanjo kò tolé?
Ẹgbẹ ajijagbara TPLF fẹsun kan Ọbasanjọ pe o n ṣegbe lẹyin igun kan.
Kí ló ṣokùnfà ikú gbajúmọ̀ òṣèrèbìnrin, Nimmy Ferrari tó jáde láyé lásìkò tó ń palẹ̀mọ́ láti ṣí ilé tuntun tó kọ́?
Ọkan lara awọn oṣerebinrin nni, Oluwakemisola Apesin, ẹni tọpọ mọ si Anti Sidi lo tufọ iku oloogbe naa lori ikanni ayelujara.
Ṣé lóòótọ́ ni Tinubu buwọ́lù ẹ̀wọ̀n gbére fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá kùnà láti dá owóòyá NELFUND padà fún ìjọba? Àlàyé rèé
Lọdun 2024 ni Tinubu buwọlu ofin idasilẹ ajọ NELFUND to n ri si eto owooya fawọn akẹkọọ ti ko rọwọ họri lawọn ile ẹkọ giga ni Naijiria.
Sẹ́nétọ̀ Buba sọ̀rọ̀ lórí fídíò tó gba orí ayélujára pé ó ṣàtìlẹyìn fáwọn agbébọn
Ninu fidio naa ni Hassan ti fẹsun kan pe niṣe ni Sẹnetọ naa n idanilẹkọọ fawọn agbebọn to pe orukọ wọn ni Babangida ati Lema.
Bàlúù yà wọ ojú pópó, kọlu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ́, ẹ̀mí márùn ún lọ síi, ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lọ́gán
Pupọ awọn to farapa naa lo jẹ pe wọn ha mọ inu tabi abẹ ọkọ ni to si jẹ pe awọn panapana ni lati sa ipa kikankikan ki wọn to le yọ wọn.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn èèyàn kan wà tí wọn kò ní ilà ọwọ́? Ohun tó fà á ree
Aini ila ọwọ tabi tẹsẹ ti oloyinbo n pe ni adermatoglyphia jẹ nnkan ti wọn maa n bi mọ eeyan, amọ, iru rẹ ko wọpọ rara.
Mo fẹ lọ fún ìsinmi díẹ̀ kí ara lè tù mí láti lé sin àwọn èèyàn Osun dáadáa - Gómìnà Adeleke
Irinajo isinmi naa n waye lẹyin ọsẹ mẹta ti Adeleke bori eto idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Ọṣun.
Wo àwọn alága EFCC tẹ́lẹ̀rí tí wọ́n ti fẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ kàn
Alaga ajọ EFCC tẹlẹri, Abdulrasheed Bawa, dero atimọle ajọ ọtẹmulẹyẹ DSS lọdun 2023 lori ẹsun ṣiṣe ṣowo ilu kumọ kumọ, ṣiṣi ipo lo ati didari owo dukia ijọba ti EFCC ta si ibomiran.
Ẹ yàgò fún òṣèlú kí epo má baà ta sí àlà yín, Makinde kìlọ̀ fún àwọn Ọba Oyo
Gomina naa tun ke si awọn ori ade ki wọn tẹsiwaju lati maa gbe ni alaafia pẹlu awọn ti wọn jẹ ọba le lori.
Kí ló ṣokùnfà ikú ọmọ ìyá mẹ́ta lọ́jọ́ kan náà l'Ondo? Ohun tí a mọ̀ rèé
Ẹkun sọ lẹyin ti wọn ri oku awọn mẹtẹẹta ninu odo kekere kan, lẹyin ti wọn ti n wa wọn kiri.
Ilé aṣojú-ṣòfin rí àpò àṣùwọ̀n owó 58 tó so mọ́ Adeniyi Adeyemi, bó ṣe wẹ Gbajabiamila mọ́ pé kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa ayédèru iléeṣẹ́ PFIPC
Bakan naa ni wọn fidi rẹ mulẹ pe Gbajabiamila lo n ṣiṣẹ tako idasilẹ awọn ayederu ileeṣẹ yii, ti aṣiri rẹ fi tu sita fun gbogbo araye.
Sunday Igboho sọ̀rọ̀, orí ayélujára tún gbóná jain-jain, áláyé rèé
Ninu fidio kan to gba ori ayelujara ni Igboho ti n sọ fun awọn ẹṣọ aabo naa pe agbebọn ti wọn ba ti ba ibọn lọwọ rẹ ninu igbo ni ki wọn pa lẹyẹ o sọka.
Àlàyé rèé lórí bí a ṣe ṣàwárí, dóòlà àwọn tí ajínigbé gbé ní Oriire, ọ̀nà táwọn èèyàn mẹ́sàn-án gbà kú àti ọ̀pọ̀ òfegè ìròyìn nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà - Ọ̀gá DSS
Awọn ti ko din ni mẹrindinlaadọta, olukọ meje ati akẹkọọ mọkandinlogoji ni awọn janduku agbebọn naa jigbe wọnu igbo lọ.
Àṣírí ibi tí wọ́n ti n ṣe ayédèrú owó Euro tú n'ibadan, àwọn afurasí há
Ẹgbẹrun mẹjọ ati ẹẹdẹgbẹrun owo Euro ti gbogbo rẹ ayederu ni ọlọpaa sọ pe awọn gba lọwọ awọn afurasi naa.
Báyìí ni ìgbẹ́jọ́ awakọ̀ Anthony Joshua tún ṣe lọ àti àwọn kókó ẹ̀sùn mẹ́rin tí olùpẹ́jọ́ gbé kalẹ̀
Wọn sọ fun ile ẹjọ pe niṣe ni Joshua atawọn ọrẹ rẹ ti sun lọ ninu ọko Lexus SUV ti wọn wa nigba ti wọn n lọ si ilu Sagamu ki ijamba naa to waye.
Kí ló fá ikú ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń jí epo rọ̀bì fà ní Okrika, ìpínlẹ̀ Rivers? Ohun tí a mọ̀
Nnkan bi agogo mejila ori, Ọjọbọ, ọsẹ yii, ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni iṣẹlẹ naa waye ni adugbo Okari Jetty, iyẹn lagbegbe Okrika Mainland.
Àṣírí gbọ́mọgbọ́mọ méjì tó ń wọ Hijab láì ṣe Mùsùlùmí tú lásìkò tí wọn tún fẹ́ jí ọmọ míì gbé
Eyi lo n waye lẹyin ọjọ diẹ tawọn ẹṣọ aabo n kọminu lori bi ijinigbe awọn ọmọde ṣe n waye lemọlemọ lẹnu ọjọ mẹta yii ni ilu Abuja atawọn agbegbe mii ni Naijiria.















































































