30,000 Fulani agbébọn àtàwọn ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ míí ló ń pa ọ̀pọ̀ èèyàn, sọ ọ̀pọ̀ di aláìnílé lórí mọ́ ní Nàíjíría - Àbọ̀ ìwádìí àjọ Amẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Ajọ kan nilẹ Amẹrika to wa fọrọ ominira ẹsin ni agbaye, USCIRF ti ke gbajare pe o to ẹgbẹrun lọna ọgbọn awọn Fulani agbebọn to n soro bii agbọn yika orilẹede Naijiria.
Ikede naa lo waye ninu agbejade abọ iwadii ajọ naa fun osu karun ọdun 2026 yii nipa ikọlu to n waye nilẹ Naijiria.
Ajọ naa salaye pe awọn agbebọn naa lo wa ni onikọjikọ, ti ikọ kọọkan si ni ọmọ ẹgbẹ mẹwa si ẹgbẹrun kan.
Abọ iwadi ajọ to wa fun ominira ẹsin lagbaye naa fikun pe awọn agbesunmọmi yii lo tii buru julọ, ti wọn si n tẹ ofin ominira ẹsin loju lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Ọpọ awọn ikọlu agbebọn lo dojukọ awọn agbegbe tawọn Krisitẹni pọ si, bi o tilẹ jẹ pe awọn agbegbe to jẹ tawọn musulumi naa n fara gba ninu ikọlu naa"
Ninu abọ naa ni wọn ti salaye bawọn agbebọn to jẹ ẹya Fulani naa ti n tẹnpẹlẹ mọ ikọlu wọn lawọn agbegbe to wa lẹkun guusu ati aarin gbungbun Naijiria, ti wọn si n gbẹmi ẹgbẹlẹgbẹ eeyan.
Bakan naa ni iwadii naa fihan pe ọpọ awọn eeyan lawọn agbegbe ti ikọlu yii ti n waye ni wọn ti di alainilelori, eyi to mu ki ibẹru maa wa laarin awọn ikọ ẹlẹsin yika Naijiria.
Yatọ si eyi, iwadii naa tun fihan pe ọpọ awọn ikọlu yii lo dojukọ awọn agbegbe tawọn Krisitẹni pọ si, bi o tilẹ jẹ pe awọn agbegbe to jẹ tawọn musulumi naa n fara gba ninu ikọlu naa.
Lasiko awọn ikọlu yii, iwadi naa ni awọn agbẹbọn ọhun n yabo awọn eeyan agbegbe ti wọn ba kọlu pẹlu ohun ija oloro, ko wọn ni ẹru lọ, pa ọpọ wọn tabi ji ọpọlọpọ gbe lọ.
Abọ iwadi ajọ to wa fun ominira ẹsin ni agbaye fikun pe "Nigba tawọn Fulani agbebọn yii n se ikọlu aladani wọn, awọn eeyan miran naa tun fi ọwọ sowọpọ pẹlu wọn."

Oríṣun àwòrán, United States Commission on International Religious Freedom
"Wọn maa n fi ida wọn soke, ti wọn yoo si kọlu agbegbe igberiko ni alẹ, wọn yoo dẹru ba awọn eeyan lati sa fun wọn, wọn yoo si gba akoso ilẹ awọn eeyan to ba wu wọn"
Lara wọn la ti ri awọn ikọ agbebọn to n wa ọna lati sọ ara wọn di olowo, to fi mọ awọn ẹgbẹ agbesunmọmi to n lo ọna ipa lati tumọ ohun ti ẹsin Islam jẹ."
Iwadi naa tun sisọ loju rẹ pe awọn ikọ afẹjẹwẹ naa maa n doju ikọlu wọn kọ awọn agbegbe to w ani igberiko ni alẹ tabi oru, ti wọn si n lo Ọkada atawọn ohun ija oloro.
"Wọn maa n fi ida wọn soke, ti wọn yoo si kọlu agbegbe igberiko ni alẹ, wọn yoo dẹru ba awọn eeyan lọna ati jẹ ki wọn sa fun wọn, ti wọn yoo si gba akoso ilẹ awọn eeyan to ba wu wọn."
Ajọ USCIRF wa laa mọlẹ pe ikọlu awọn ikọ agbebọn Fulani atawọn ikọ agbebọn miran ti sọ awọn eeyan to to milliọnu kan ati ọọdunrun eeyan di alainilelori mọ ni aarin gbungbun Naijiria.
Isẹlẹ naa ni iwadii ọhun sọ pe o ti mu ki ọpọlọpọ eeyan yii maa gbe ninu awọn agọ to kun ni akunfaya, lai si eto aabo ati imọtoto to peye.

Oríṣun àwòrán, United States Commission on International Religious Freedom
"Ikọlu kan ni ipinlẹ Benue losu kẹfa ọdun 2025 pa igba eeyan"
Abọ iwadi naa wa salaye ọpọlọpọ ikọlu tawọn agbebọn yii ti se laarin ọdun 2025 si 2026, to fi mọ isẹlẹ isekupani ọlọgọọrọ eeyan ni ipinlẹ Benue ati Plateau.
"Ikọlu kan to waye ni ipinlẹ Benue losu kẹfa ọdun 2025 lo pa igba eeyan o kere tan nigba ti awọn ti wọn di alainilelori n gbe nile awọn ijọ Aguda."
Abọ iwadii ajọ USCIRF salaye siwaju si pe awọn agbẹnusọ fawọn ọmọlẹyin Kristi na ika aleebu sawọn ikọ agbofinro pe se ni wọn maa n yan awọn agbegbe tawọn Musulumi n gbe nipọsin lasiko iwadi ati isọwọsisẹ wọn.
Ẹ fura o, ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ Boko Haram àti ISWAP ń pète ìkọlù lásìkò ọdún Iléyá - Iléeṣẹ́ ológun ké gbàjarè

Oríṣun àwòrán, AFP
Awi funni ko too dani, agba ijakadi.
Ileeṣẹ ologun Naijiria ti ke gbajare, pe o ṣee ṣe ki awọn ikọ agbesunmọmi Boko Haram ati ISWAP, ṣe ikọlu sawọn eeyan lasiko odun Ileya to gbode yii.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin nileeṣẹ ologun apapọ lẹkun Ariwa -Ila-Oorun(Joint Task Force North-East), Operation Hadin Kai, Lt. Col. Sani Uba,fi sita ni ọrọ yii wa.
Atẹjade naa kede pe iwadii ati iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ tawọn ṣe fi han, pe o ṣee ṣe ki awọn to ṣẹku ninu Boko Haram ati ISWAP kọlu awọn ibi to ba da wa lasiko ọdun naa.
Wọn fi kun un pe awọn oniṣẹ ibi naa le lo ibi ti ero pọ si, ki wọn gbe ado oloro si ẹnikan ti yoo wọ aarin ero lọ lara.
Uba sọ pe gbogbo eyi ni awon ti mọ pe o le ṣẹlẹ, awọn si ti gbe igbesẹ lati dena de e.
"Ṣaaju ọjọ ọdun Ileya ni Ọjọru, a ti pin awon ikọ ologun sibi to yẹ gbogbo, a si ti ṣi awon oju opo itọpinpin to yẹ kiri bi a ṣe n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo to ku, lati dena ikọlu kankan"
Atẹjade ologun naa ṣo pe wọn ti ko awọn ologun sibi to yẹ gbogbo, paapaa awọn ibi ti ewu ti farahan ju.
"Ṣaaju ayẹyẹ Ọjọru, a ti pin awon ikọ sibi to yẹ gbogbo, a si ti ṣi awon oju opo itọpinpin to yẹ kiri bi a ṣe n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo to ku, lati dena ikọlu kankan."
Bakan naa ni Operation HADIN KAI rọ awọn oriade, olori ẹsin, alẹnulọrọ lawujọ ati bẹẹ bẹẹ lọ lati ran iṣẹ aabo to n lọ yii lọwọ.
Ileeṣẹ ologun ni oun ko ni i fun awon agbesunmọmi laye lati ṣe iṣẹ ọwọ wọn, kawọn eeyan le fi ifọkanbalẹ ṣe ọdun Ileya.
Àwọn agbébọn kọlù àgọ́ ọlọ́pàá, ààfin ọba ní Kwara lóru mọ́jú, jí èèyàn mẹ́jọ gbé, tó fi mọ́ ayaba méjì àti àwọn ọmọ ọba, dáná sun dúkìá

Se ni ibẹrubojo gbilẹ, tí onikaluku n sa asala fun ẹmi rẹ loru mọju ọjọ Aje, ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Karun-un, ọdun yii.
Eyi ko sẹyin bawọn agbebọn se ya wọ iluu Yashikira, ni ijọba Ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara, ti wọn si ji okere tan, eeyan mẹwaa gbe lọ.
Lara awọn ti wọn ji gbe lọ ni meji ninu awọn olori Ọba ilu naa, Alaaji Umaru Sariki Usman to fi mọ awọn ọmọ ọba ti a o ti fidi iye wọn mulẹ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.
Amọ iroyin kan ni gbogbo awọn eeyan ti wọn gbe lọ to mẹwaa niye.
Bẹẹ ba gbagbe, oru alẹ ọjọ Satide ijẹta ni awọn agbebọn yii naa tun kọlu sọọsi kan ti wọn ti n se isọ oru nijọba ibilẹ Ekiti nipinlẹ Kwara.
Wọn pa eeyan mẹta, ti wọn si ji eeyan mẹẹdogun gbe lọ

"Ẹmir naa moribọ sugbọn wọn dáná sun ọkọ̀, pa tòlótòló ọba méjì, ji awọn ayaba meji lọ, wọn si tun ko awọn ọmọ rẹ"
BBC Yoruba kan si asoju to n soju ẹkun Okuta Yashikira ni ile asofin Kwara, Họnọrebu Baba Saliu lori aago fun ẹkunrẹrẹ nipa iṣẹlẹ naa.
Baba Saliu sọ pe, nnkan bi aago kan si meji ni wọn ya wọ ilu, wọn si lọ taara si agọ ọlọpaa.
"Wọn ji awọn ohun ija kọọkan ni agọ ọlọpaa, ko to di pe wọn gba ile Emir lọ.
"Bi wọn ṣe de ile ọba ni wọn bẹrẹ si yinbọn soke ati si awọn ọkọ ti wọn ba nibẹ.
"Ẹmir naa moribọ sugbọn wọn ji awọn ayaba rẹ meji lọ, wọn si tun ko awọn ọmọ rẹ pẹluu ati awọn eeyan mii.
"A o le sọ iye eeyan ti wọn gbe lọ ni pato amọ yoo ma lọ bii mẹwaa.
Wọn dáná sun ọkọ̀, pa tòlótòló ọba méjì."
Baba Saliu fi kun un pe, awọn agbebọn naa ko gbẹmi eeyan kankan, amọ wọn dana si awọn ọkọ ayọkẹlẹ ọba, wọn si tun gbẹmi awọn tolotolo ọba meji.
Baba Saliu sọ pe, ijọba Kwara ti bẹrẹ igbesẹ ni kete ti iṣẹlẹ naa sẹ.
O ni koda, gomina ipinlẹ Kwara ti rọ Emir ilu naa lati fi ilu silẹ lasiko yii nitori aabo ara, titi ohun gbogbo yoo se pada bọ sipo.
"Ọlọpaa, ọdẹ asọgbo ati fijilante ti wọgbo lọ lati doola awọn araalu ti wọn jigbe"
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ejire-Adeyemi Adetoun, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, lọjọ Aje, ọṣẹ yii.
O ni iroyin de si eti igbọ awọn pe awọn agbebọn yabo iluu Yashikira, ni ijọba Ibilẹ Baruten, ni ipinlẹ Kwara, wọn ṣe akọlu si aafin ọba ati agọ ọlọpaa. ti wọn si ji eeyan mẹwaa gbe lọ.
O tẹsiwaju pe ni nnkan bi aago meji oru mọju ọjọ Aje, ni awọn ẹruku yabo ilu Yashikira, pẹlu ibọn ati awọn ohun ija oloro miran.
O ni wọn lọ agọ ọlọpaa to wa niluu ọhun sugbọn awọn ọlọpaa ti wọn wa lẹnu isẹ o jẹ ki wọn ri isẹ ṣe lori bi wọn ṣe koju wọn.
"Igba ti wọn kuro nibẹ ni wọn gba aafin ọba lọ nibi ti wọn ti dana sun apa kan aafin naa, ki wọn to ji iyawo ọba meji ati awọn ọmọ gbe lọ"
O fi kun un pe eeyan mẹwaa ni awọn agbebọn jigbe lọ sibi ti ẹnikéẹni ko mọ bayii.
O tẹ siwaju pe, Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Adekimi Ojo, ti ni ki iwadii bẹrẹ kiakia, ki gbogbo awọn ẹsọ alaabo wọgbo lọ lati lọ doola awọn araalu ti wọn jigbe lọ.
Kọmisanna, ni ati ọlọpaa ni, ọdẹ asọgbo, to fi mọ awọn fijilante ni wọn ti wọgbo lọ bayii, ki wọn le doola awọn araalu ti wọn jigbe.
O ni pe awọn agbesumọmi ti pe ogun bayii, wọn kede ogun lati maa da omi alaafia ilu ru ṣugbọn gbogbo wọn pata ni awọn yoo mu ti awọn yoo si fi wọn jofin.




























