Ṣé lóòótọ́ ni pé Olorì tẹ́lẹ̀, Naomi Silekunola fẹ́ padà sí ààfin Ooni Ifẹ bíi ìyàwó? Ohun tí Ààfin sọ rèé

Oríṣun àwòrán, Naomi Silekunola /Instagram
Latigba ti fidio to ṣafihan Ooni Ife; Ọba Adeyeye Ogunwusi ati olori rẹ tẹlẹ; Naomi Silekunola papọ nibi ayẹyẹ ikẹkọọ gboye obinrin naa niluu Ondo ti gun ori ayelujara ni awọn eeyan ti n sọ pe abi iyawo to ti kọ Ọọni silẹ naa tun fẹ pada si aafin ni.
Ọjọ Ẹti to kọja yii ni Naomi kẹkọọ gboye ni Yunifasiti Elizade, nipinlẹ Ondo, ti Ọọni si wa nibẹ pẹlu Tadenikawo ti I ṣe ọmọkunrin ti Naomi bi fun un.
Ninu fidio naa ni Ooni ati Iya Tadenikawo ti jọ n sọrọ pọ, ti wọn jọ n rẹrin-in, bẹẹ ni Ọọni tun fun ọmọ rẹ ni beeli owo pẹlu.
Eyi lo mu ọpọ eeyan to ri ifẹ to han ninu fidio naa maa sọ pe iba ti dun to bi Olori tẹlẹ naa ba le pada si aafin bii iyawo, awọn mi-in si n sọ pe boya ni ọrọ ifẹ ko ti bẹrẹ pada laaarin Kabiyesi Adeyeye ati Naomi Silekunola.
Ki ni aafin Ife sọ nipa ọrọ naa?

Oríṣun àwòrán, Screenshot from video
Nigba to n sọrọ lori iroyin to n lọ lori ayelujara naa, Agbẹnusọ Ọọni, Moses Olafare, sọ fun ẹka iroyin PREMIUM TIMES pe oun ko le sọ pe awọn tọkọ-taya tẹlẹ naa ti fẹ maa fẹra wọn pada niyẹn.
Olafare to sọ pe oun wa lorilẹede Liberia lọwọlọwọ, sọ pe Ooni ko ṣẹṣẹ maa lọ si ode ti Yunifasiti Elizade ba gbe kalẹ.
O ni kawọn eeyan ma fi ti ọjọ Ẹti to kọja yii fẹnuko pe ifẹ ti bẹrẹ pada laaarin Ooni ati olori to ti kuro laafin naa.
O ni amọ bi awọn tọkọtaya tẹlẹ naa ba fẹ, anfaani wa fun wọn lati maa fẹra wọn pada, nitori ipinya ko tumọ si pe wọn ko le fori ji ara wọn.
Ohun kan ti Olafare sọ pe o kan nilo lati ṣẹlẹ ni etutu, ki olori ana naa too le pada si aafin bii iyawo .
"Wọn le maa fẹ ara wọn pada gẹgẹ bawọn tọkọtaya ṣe maa n ṣe. Ṣugbọn yoo nilo awọn etutu kan fun obinrin naa.
"Iru etutu naa ki I ṣe ohun ti wọn yoo ṣe lode ita gbangba.
"Bi obinrin naa ba ti pinnnu lọkan rẹ lati pada si igbeyawo rẹ atijọ, aaye wa fun un, amọ etutu to leto lọna ibilẹ gbọdọ waye."
Bẹẹ ni Olafare ṣalaye.
O fi kun un pe Silekunola lo kuro laafin funra rẹ, amọ ki ẹnikẹni ma ṣe ro pe ipadabọ rẹ ko ṣee ṣe.
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
Oṣu Kẹwaa ọdun 2018 ni Olori Naomi Silekunola di aya Ooni Adeyeye Ogunwusi, niluu Ile Ife.
Oṣu Kọkanla ọdun 2020 lo bi Arẹmọ Tadenikawo fun Kabiyesi.
Oṣu Kejila ọdun 2021 lo kede pe oun ki I ṣe iyawo Ooni mọ to si kuro ni aafin naa pẹlu ọmọ rẹ.
Lẹyin ti Naomi kuro laafin ni Kabiyesi Ogunwusi fẹ awọn olori to wa laaafin rẹ bayii.
Lara awọn olori naa ni: Olori Maryam Anako, Olori Folasade Ashley, Olori Ronke Ademiluyi, Olori Tobi Ogunwusi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

























