Ààfin Ataoja Osogbo ló gbadé lórí àwọn ọba tó ń lọgun nítorí ìwà ajagungbalẹ̀ kìí ṣe Gómìnà Adeleke - Ìjọba Osun sọ̀rọ̀ sókè

Oríṣun àwòrán, Gov Ademola Adeleke/X
Ijọba ipinlẹ Osun ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu iroyin to n lọ kaakiri ori ayelujara wi pe Gomina Ademola Adeleke rọ awọn ọba kan loye, lori ẹsun ṣiṣe oṣelu, ati pe wọn n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.
Agbẹnusọ gomina, Olawale Rasheed sọ pe iro to jinna si otitọ ohun ti wọn n gbe kaakiri, ati pe gomina ko ni nnkan ṣe pẹlu awọn ti irọloye naa kan.
Rasheed jẹ ko di mimọ ninu atẹjade to fi sita lọsan ọjọ Aje, wi pe Ata-Oja tilu Osogbo lo rọ awọn eeyan naa loye, lori ẹsun iwa aṣemaṣe to nii ṣe oẹlu tita ilẹ lọna aitọ, ati aṣilo ipo.
Kí ló ṣẹlẹ̀?
Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti Alagunbelewo tilu Agunbelewo nilu Osogbo, Oloye Maruf Olayiwola sọ pe oun ati Olu tilu Irepodun ni wọn rọ loye lati ori ipo ọba keji si ipo oloye lasan.
Olayiwola sọ pe ẹsun ti wọn fi kan awọn ni wi pe awọn n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu APC dipo ẹgbẹ oṣelu Accord ti gomina n ṣe.
Ọkunrin naa ni wọn lo sọ pe wọn ka ẹsun ti wọn fi kan awọn si wọn leti ko to di pe wọn gbe igbesẹ lati rọ wọn loye ipo ọba.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe, "O ṣeni laanu wi pe titi di asiko yii, ko sẹni to sọ ẹṣẹ wa fun wa, ṣugbọn wọn sọ fun wa pe nitori ti a ko ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu Accord, ati pe a ko gba owo lọwọ ẹnikẹni.
"A ni awọn ọrẹ ninu ẹgbẹ APC, a ko si le sọ pe a ko ba wọn ṣe. Mo nigbagbọ wi pe iyẹn ko to lati gba ade lori wa," Olayiwola sọ bẹẹ.
O fi kun ọrọ rẹ pe ki "Gomina Adeleke ma ṣe gba awọn kan laaye lati wọ ipo rẹ gẹgẹ bii gomina nilẹ lati maa fi oṣelu ẹtanu ṣe."
Kí ni ìjọba sọ?
Ṣugbọn nigba to n tako ẹsun naa, Rasheed sọ pe "irọ to jinna si otitọ ni gbogbo ọrọa awawi ti Olayiwola sọ."
Rasheed sọ pe Gomina Adeleke ko le rọ ọba kereje kan nipo, nitori pe Ata-Oja tilu Osogbo ni olori wọn.
O ṣalaye siwaju pe igbimọ oluwadii ati ifiyajẹni ti Aafin Ata-Ọja ni wọn gbe igbesẹ naa, lẹyin iwadii pe awọn Baalẹ meji naa lọwọ ninu iwa ajagungbalẹ, aṣilo ipo ati awọn iwa miran to tako alaafia ilu Osogbo.
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o sọ pe oniruuru ẹsun ni wọn ti fi kan awọn Baalẹ meji naa laafin Ata-Oja, ti kabiyesi si ṣe ojuṣe nipa iṣẹ iwadii.
"O wa jẹ ẹdun ọkan lati maa yi ọrọ to nii ṣe pẹlu agbegbe wọn nipa iwa ajagungbalẹ mọ Gomina Adeleke. Gomina ko raaye lati maa da si ọrọ agboole niwọn igba ti ọba alaye to jẹ olori awọn ọba wa nilu," Rasheed fidi rẹ mulẹ.
O wa rọ awọn araalu lati ma ṣe gba ayederu iroyin gbọ, to si ṣapejuwe awọn to wa nidi iroyin ọhun gẹgẹ bi awọn ti ko fẹ abajade ijọba ibilẹ nipinlẹ Osun.
Gómìnà Adeleke gba ade lórí àwọn ọbalayé kan, sọ wọ́n di olóyé, àwọn ọba tọ̀rọ̀ kan ní àtílẹyìn àwọn fún APC ló kóbá àwọn

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/X
Awuyewuye si n lọ lori bii Gomina Ademola Adeleke ipinlẹ Osun ti rọ ọba meji loye ti o si sọ wọn di oloye lasan, lẹyin tawọn ori ade naa sọ pe igbesẹ ijọba naa lọwọ oṣelu ninu.
Awọn ọba naa ti sọ pe tori awọn n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu alatako APC lo jẹ ki ijọba Gomina Adeleke sọ awọn di oloye lati ipo ọba.
Lọsẹ to kọja ni ijọba ipinlẹ Osun kede pe kabiyesi Alagunbelewo of Agunbelewo, Oba Maruf Adewale Olayiwola Lawal, ati Olu of Irepodun, Adewale Adeniyi Sikiru, ti kuro nipo ọba ti wọn wa tẹlẹ.
Lati ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹwaa to kọja nijọba ti sọ pe awọn ọba alade tọrọ kan naa ti di oloye.
Ariwọ sọ nigba ti iroyin jade wi pe ijọba ti fi Agunbelewo mii jẹ lẹyin irọloye Ọba Maruf Lawal.
Ninu ọrọ rẹ, Ọba Lawal ṣalaye fawọn akọroyin wi pe ko si idi kan gboogi ti ijọba fi rọ awọn loye ju ọrọ oṣelu lọ.
O ni ohun tawọn gbọ ni pe ijọba ipinlẹ Osun rọ awọn loye tori pe ẹgbẹ APC lawọn n tẹle dipo ẹgbẹ oṣelu Accord to jẹ ẹgbẹ gomina.
''A wa n fi asiko yii kepe gbogbo eeyan wi pe ki wọn ran wa lọwọ lori ọrọ yii,'' Ọba Lawal lo sọ bẹẹ.
''Muritala Abiola Adejumobi di Alagunbelewo tuntun''
Ṣaaju ni ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ fi iwe ranṣẹ si Ọgbẹni Lawal eyi to ri i gẹgẹ ọba labẹ ofin Cap 25 ipinlẹ Osun ọdun 2002 lati ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ ọdun 2024.
Wale Aliyu lo buwọlu iwe naa lorukọ akọwe agba ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ ijọba ibilẹ ati ọrọ oye jijẹ.
Amọ, Ọgbẹni Aliyu naa lo tun fi iwe mii eyi to buwọlu lọjọ karun un oṣu Kọkanla ọdun 2026 yii eyi to fi sọ fun un wi pe ijọba ipinlẹ Osun ti buwọlu irọloye rẹ gẹgẹ lati ipo ọba lọ si ipo oloye bẹrẹ lati ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹwaa ọdun 2026.
Lẹta naa ṣalaye wi pe gbogbo ajẹmọna ti ọba ti Ọgbẹni Lawal lafaani si tẹlẹ ni ko ni lanfaani si mọ bayii lẹyin irọloye rẹ.
Iru iwe kan naa ni ijọba fi ranṣẹ si Olu ti Irepodun, Ọba Sikiru naa.
Ọrọ naa di ranto nigba ti Wasiu Bello to akọwe Ataoja ilu Osogbo, Ọba Jimoh Oyetunji Olanipekun (Larooye III).
O si sọ fun Lawal wi pe ki o ma pe ara rẹ ni aṣoju Ataoja mọ, bakan naa ni o tun paṣẹ fun un lati da gbogbo nnkan aafin to wa lọwọ rẹ laarin ọjọ meje.
A gbọ wi pe ijọba ipinlẹ Osun pada yan Ọmọba Muritala Abiola Adejumobi gẹgẹ bii Alagunbelewo ti Agunbelewo lọjọ kẹtala oṣu Kọkanla yii.
Ohun ti ofin sọ lori rirọ ọba loye
Labẹ ofin Cap 25 ipinlẹ Osun ti ọdun 2002, ijọba ipinlẹ Osun lagbara lati rọ ọba loye, tabi da a duro.
Bakan naa ni ijọba le sọ ọba alade di oloye labẹ ofin yii.
Ofin tun fun ijọba lagbara lati yọ ọba ni ipo pata pata.
Ẹwẹ, Victor Adefioye Ayoade gbe Gomina Rauf Aregbesola ipinlẹ Osun lọ si ile ẹjọ lọdun 2015 lẹyin ti ijọba sọ ipo Shoko ilu Ikire di ipo oloye lasan an.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun si dajẹ wi pe ijọba ti yi ofin ọdun 1958 to ṣagbekalẹ oye naa danu.





























