Gbas-gbos nílé Olúwa! Ìgbìmọ̀ ìjọ Fountain of Life Church yọ Pásítọ̀ Jimmy Odukoya, àmọ́ ó takú pé òun kò lọ

Aworan Pasitọ Jimmy Odukọya ninu ijọ rẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iroyin kan jade lowurọ ọjọ Iṣẹgun eyi to tọ̀ka si atẹjade kan ti awọn kan ti wọn pe ara wọn ni igbimọ majẹobajẹ ijọ Fountain of Life Church nilu Eko ninu eyi ti wọn ti n kede pe wọn ti yọ oluṣọ aguntan ijọ naa, Pasitọ̀ Jimmy Odukọya nipo.

Ohun ti igbimọ naa n sọ̀ ni pe ilana ti baba pasitọ naa, Pasitọ Taiwo Odukọya to da ijọ naa silẹ fi silẹ tako iyansipo rẹ gẹgẹbi iku rẹ.

Ki lawọn idi ti igbimọ naa la kalẹ fun yiyọ Pasitọ Jimmy Odukọya?

Aworan Pasitọ Jimmy Odukọya ninu ijọ rẹ

Awọn ọmọ igbimọ majẹobajẹ naa ṣalaye ninu atẹjade wọn ọhun pe awọn ti ri fidio kan ti baba oluṣọaguntan naa fi silẹ ki o to ku ninu eyi ti wọn ni awọn rii pe ọtọ ni ojuṣe ti baba oluṣọaguntan naa yan fun un lẹyin iku rẹ.

Gẹgẹbi igbimọ naa ṣe sọ, wọn ni ohun ti oludasilẹ ijọ naa sọ ninu fidio ọhun ni pe ẹlomiran ni ko jẹ oludari ati pasitọ agba ijọ naa lẹyin iku rẹ. Wọn ni, ninu fidio naa ti Pasitọ Taiwo Odukọya ka silẹ ni oṣu kejila ọdun 2021, ohun to sọ ni pe ipo amugbalẹgbẹ fun ẹni to yan gẹgẹbi oluṣọaguntan lẹyin ara rẹ ni Oloogbe Pasitọ Taiwo Odukọya ni ki ọmọ rẹ dimu, ki o si maa dari ẹka awọ̀n ọdọ ni ijọ naa.

Wọn ni iroyin to wa ni arọwọto awọn ọmọ igbimọ majẹobajẹ yii nigba ti baba rẹ ku lọdun 2023 ni wọn fi yan Pasitọ Jimmy Odukọya gẹgẹbi pasitọ agba ijọ naa nigba naa.

Idi miran ti wọn tọka si ni awọn abala kan ninu iwe ofin ile ijọsin naa.

Bakan naa ni wọn tun kọminu lori igbeyawo ti pasitọ naa ṣe laipẹ yii lẹyin to kọ iyawo rẹ akọkọ silẹ eleyi ti wọn ni o tako ẹkọ ati ohun ti awọn to da ijọ naa silẹ fi lelẹ. Wọn ni ko si tun ba ilana adari nipa ẹmi mu.

Awọn ọmọ igbimọ Majẹobajẹ naa ni igbesẹ yii ti n mu ẹrẹ ba ijọ naa.

"Nitori eyi, Pasitọ Jimmy Odukọya kii ṣe oluṣọaguntan agba ijọ Fountain of Life Church mọ."

'Jimmy odukọya ṣi ni oluṣọaguntan ijọ wa, awọn kọlọransi ọmọ igbimọ majẹobajẹ lo wa nidi ikede yíyọọ́ nipo'

Aworan PAsitọ Jimmy Odukọya ati baba rẹ, Pasitọ Taiwo Odukọya.

Wayii o ninu atẹjade mira to jade loju opo ayelujara ijọ naa ni ọsan ọjọ Iṣẹgun, ijọ naa sọ pe ko si otitọ ninu iroyin to n sọ pe wọn ti yọ Pasitọ Jimmy Odukọya nipo gẹgẹ bi oluṣọaguntan agba ijọ Fountain of Life Church.

Atẹjade ọhun sọ pe awọn kọlọransi kan ninu igbimọ majẹobajẹ inu ijọ naa ni wọn wa nidi ikede naa.

Atẹjade naa sọ pe lati oṣu kẹta ọdun 2026 ni wọn ti paṣẹ fun awọn ọmọ igbimọ majẹobajẹ yii lati kọwe fi ipo wn silẹ nitori ohun ti atẹjade naa pe ni 'ṣiṣe lodi si iwe ofin ijọ naa'.