Ọmọ̀ Nàìjíríà mẹ́jọ wà nínú afurasí méjìlà tọ́wọ́ ọlọ́pàá tẹ̀ ní Canada fún jíjí àwọn ọkọ̀ gbé

Aworan lara awọn ọkọ ayọkẹlẹ ti awọn ọlọpaa Canada ri gba pada lọwọ awọn afurasi naa.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọwọ awọnọlọpaa lorilẹede Canada ti tẹ awọn afurasi mejila kan, ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ adigunjale kan to jẹ wi pe ọkọ ayọkẹlẹ ni wọn maa n ji gbe.

Mẹjọ ninu awọn afurasi adigunjale yii ni wọn jẹ ọmọ orilẹede Naijiria.

Ẹsun ti wọn fi n kan wọn bayii ni pe wọn kii ri ọkọ ayọkẹlẹ olowo iyebiye soju, jiji ni wọn yoo ji i gbe. Bi wọn ba si ti rii ji gbe bayii, ẹkun iwọ oorun Africa ni wọn yoo ko wọn ta si.

Awọn ọlọpaa ni Peel ni ilu Ontario sọ pe ọkọ ayọkẹlẹ olowo iyebiye mẹrindinlọgọrun ni wọn ri gba pada ninu akoto ikẹrusi ti wọn ko si ori ọkọojuomi.

Awọn alaṣẹ sọ pe nigba ti wọn diye le awọn ọkọ naa ti wọn ta kaakiri awọn ibudokọ ojuomi lorilẹede Canada, owo rwọn to miliọnu mẹrin abọ dọla owo ilẹ Amẹrika ($4.5m)

Ẹsun mọkanlelọgbọn o le igba ni wọn fi kan awọn afurasi naa bayii, bi o tilẹ jẹ wi pe iwe aṣẹ ti jade lati mu awọn ti panpẹ ofin ko tii mu. Bakan naa lawọn ọlọpaa n sọ pe o ṣeeṣe ki wọ̀n le awọn afurasi naa pada si orilẹede koowa wọn lẹyin ti wọn ba pari eto igbẹjọ wọn.

Awọn ọmọ Naijiria to wa lara wọn niwọnyii: Stanley Udeh, Olawale Ibrahim, Tosin Oyebade, Oluyemi Sodade, Oluwaseyi Bameke, Gbolahan Babatunde, Olushola Oke ati Kenneth Okafor.

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Canada ni ọpọlọpọ oṣu ni wọn ti fi n tọpinpin awọn afurasi naa ati ẹgbẹ wọn.

Wọn ni eeyan marun lo n ṣe adari ẹgbẹ ajọkọgbeta naa, bi wọn ba ti ji ọkọ ayọkẹlẹ gbe tan, wọn a fi ọgbọn alumọkọrọyin yi awọn nọmba idanimọ ara ọkọ naa titi kan ti ẹnjini rẹ.