"Inú ebi la wà ní Igbokoda láti ìgbà tí bàálù ti já, omi ẹ̀rọ kò sí, à ń ra omi mu ni, a kò sì le pa ẹja"

Àkọlé fídíò, "Inú ebi la wà ní Igbokoda láti ìgbà tí bàálù ti já, omi ẹ̀rọ kò ṣe fà, à ń ra omi mu ni, a kò sì le pa ẹja"
"Inú ebi la wà ní Igbokoda láti ìgbà tí bàálù ti já, omi ẹ̀rọ kò sí, à ń ra omi mu ni, a kò sì le pa ẹja"
Published

Awọn eeyan ati ọba ilu Igbokoda, to jẹ olu ilu ijọba ibilẹ Ilaje, nipinlẹ Ondo ti ke si ijọba fun iranlọwọ lẹyin oorun to gba ilu naa kan latari baalu ọmọ ogun to ja lulẹ nibẹ loṣu to kọja.

Ọjọ karun un, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 yii ni baalu naa ja lulẹ lẹyin ọọfi ileeṣẹ ọmọ ogun, Forward Operating Base, to wa ninu ilu naa.

Amọ ibanujẹ lo jẹ pe lẹyin ti baalu naa ja tan, awọn eeyan ilu ọhun ti n dojukọ ipenija mii latari awọn to ku sinu omi ti ọkọ ofurufu naa ja si.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe oorun ti gba agbegbe ti baalu naa ja si kan, lawọn mii sọ pe iṣẹlẹ naa ti gba ounjẹ lẹnu awọn.

Eredi ree ti BBC Yoruba fi gbera lọ si ilu naa lati wo bi nnkan ṣe ri.