Mo máa yẹ ìdí Seyi Makinde wò tí mo bá di gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo – Bimbo Adekanmbi
Oludije sipo gomina ipinlẹ Oyo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM, Bimbo Adekanmbi, ti sọ pe oun yoo ṣe iwadii gomina Seyi Makinde lori awọn owo to ti ya ti oun ba gori alefa.
Adekanmbi lo sọrọ naa ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba.
O tun sọ pe oun gẹgẹ bii gomina yoo fun awọn ijọba ibilẹ nipinlẹ naa ni ominira bo tilẹ jẹ pe oniruru igbesẹ lo wa nidi rẹ ti awọn aṣofin gbọdọ gbe.
Adekanmbi sọ pe oun ati gomina Makinde ti ni adehun pe ipinlẹ Oyo ni yoo ṣaaju, kii ṣe ohun ti awọn n fẹ gẹgẹ bii ẹnikọọkan.
Ni ti ijọba ibilẹ, Adekanmbi sọ pe oun yoo tẹle ohun ti ofin sọ, oun yoo si gbiyanju lati fun wọn ni ominira.
Oludije naa tun sọ pe oun ko ni baba isalẹ kankan ninu oṣelu bikoṣe awọn eeyan ipinlẹ Oyo lapapọ.
Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti Adekanmbi sọ fun BBC Yoruba.






