Kí ẹni tí Ajimọbi fẹ́ fà sílẹ̀ fún gómìnà má bà tẹ̀síwájú pẹ̀lú ẹjọ́ tó sọ mí dèrò ẹ̀wọ̀n ni mo ṣe ṣiṣẹ́ fún Makinde kó di gómìnà Oyo - Oriyomi Hamzat
Oludije fun ipo gomina ipinlẹ Oyo lọdun 2027 ninu ẹgbẹ Accord, Oriyomi Hamzat, ti ṣalaye ero ọkan rẹ ati idi to fi fẹ di gomina fun BBC, bẹẹ lo ṣe adehun fun awọn eeyan ipinlẹ Oyo.
Oriyomi sọ pe oun ti won ti mọ tẹlẹ naa ni, oun ko ni i yipada si ai daa fun wọn bi won ba fibo yan oun sipo.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu Hamzat lo ti ṣalaye ajọṣepọ rẹ pẹlu gomina akọkọ to ni oun kọkọ ba ṣe nipinlẹ Oyo, iyẹn Rashidi Adewolu Ladoja, lẹyin ẹ lo ni oun ba Ajimobi ṣe, Alao Akala ni saa akọkọ rẹ ati Seyi Makinde.
"Ni saa akọkọ Seyi Makinde, mo lọ si ẹwọn"
"Ni saa akọkọ Seyi Makinde, ṣe ẹ mo pe mo lọ si ẹwọn, nigba aye Ajimobi, ẹjọ yẹn o ti i pari ti ijọba wọn fi lọ.
"Emi wa wo o pe ti ẹni ti Ajimobi fa kalẹ ba wọlẹ, ẹjọ yẹn ni yoo maa tẹsiwaju, mi o wa fẹ ki ẹni ti Ajimobi fa kalẹ wọle.
"Nigba naa, mo ri Seyi Makinde bii ẹni ti yoo ṣe daadaa ni mo ṣe ba wọn ṣiṣẹ, ni iṣẹ yẹn fi yatọ si eyi ti mo ti n ṣe bọ tẹlẹ.
" Mo ki gbogbo ara bọ ọ tẹmitẹmi ni saa akọkọ, bẹẹ naa ni saa keji, ko si si gbọnmi si i omi o to o kankan laaarin emi ati Gomina Seyi Makinde.
"Awọn to n kigbe pe emi ati Seyi Makinde n ja ni won tako Makinde ni igba akọkọ ati ikeji, ṣugbọn nisinyi, Seyi Makinde ti lo wọn. Emi ti Seyi Makinde lo nigba yẹn,emi yẹn ni ọta leni.
"Gomina n sanwo oṣu oṣiṣẹ ati tawọn oṣiṣẹfẹyinti, eewọ ni fẹni to ba wọle lẹyin rẹ lati fa a sẹyin, dandan ni ki ẹni naa tẹsiwaju ni ti daadaa, ohun ta a fẹ ṣe to yatọ niyẹn o.
"Mo n bọ fun araalu, ijọba araalu gangan ti yoo ko akoyawọ ni mo fẹ waa ṣe t'Ọlọun ba sọ mi di gomina Oyo.
"T'Ọlọun ba sọ mi di gomina Oyo, ma a da apa kan opopona olobiripo pada si marundinlọgọrin, apa keji, ma a da a pada si marundinlọgọrin.
"Leyi to jẹ pe atunto ti a ba fẹ ṣe nibẹ, ki ilu fi dun un ri, wọn a sọ fawọn to ba ni ilẹ yẹn pe ibi yii o, ile la fẹ nibẹ o, ibi yii o, ile epo ni o, ibi yii o, ọja ni o, amọ awọn naa ni wọn yoo maa ṣe nnkan wọn, ijọba o si maa ṣe amojuto ẹ ki ilu le dun un ri.
Ọrọ nipa Sheikh Gumi to wa s'Ibadan
Oriyomi sọ pe oriṣiriṣi nnkan leeyan maa n ri ninu oṣelu. O ni:
"Gumi wa s'Ibadan loootọ, mi o mọ ẹni to pe Gumi. Ileeṣẹ agbohunsafẹ to n sanwo oṣiṣẹ ni awa naa, wọn pe ileeṣẹ wa pe ka wa ba awọn ka ohun tawọn n ṣe silẹ, ka gbe e saye.Ninu iwe ti won fun wa, won o sọ pe Gumi n bọ, ki i ṣe ileeṣẹ redio wa nikan ni wọn pe.
"Bowale Akinbode lo lọ ṣoju wa nibẹ, emi gan-an o lọ. Ṣugbọn nigba ti Bowale wa fi akasilẹ yẹn han mi, mo wa ri i pe ọlọpaa wa nibẹ, ti wọn tẹle Gumi wa,idi niyẹn ti wọn fi n bu mi leni o.
"Tori pe mo ri i pe ọlọpaa tẹle Gumi wa, o wa jọ mi loju, mo wa bọta pe kijọba wa ṣalaye fun wa, pe o da bii pe ijọba gan-an ni Gumi n ṣiṣẹ fun o, ki lo de ti ọlọpaa n tẹle ẹni ta a ri to n ba awọn agbesunmọmi ṣe, awọn to n pa awọn eeyan wa, ọlọpaa ma tẹle Gumi.
"Ọrọ yẹn la n sọ ti a fi aworan yẹn han saye, ohun ni awọn ẹlẹmi eṣu ba lọ wa fọto kan, wọn ran ẹrọ igbalode AI, ni wọn ba ran an niṣẹ pe ko ṣe fọto yẹn bii Oriyomi, ni wọn ba n gbe e kaakiri.
"Lẹyin ta a wa pada mu fọto yẹn gangan jade ta a fi han aye, a o gbọ nnkan kan mọ lẹnu wọn. Ṣebi wọn o tiẹ jade pe Oriyomi ma binu o, a parọ mọ ọ ni o, wọn ran awọn ni o tabi aṣiṣe, wọn o sọ nnkan kan. Emi o ni nnkan kan pẹlu Gumi."
Bẹẹ ni Oriyomi Hamzat ṣalaye.
Ọrọ nipa Sharia ati sisọ ilu di ẹlẹsin Islam
Ninu alaye rẹ, Oriyomi Hamzat sọ pe lati 2015 loun ti n ṣa awọn ọmọ ti ẹnikẹni ko mọ ile wọn labẹ biriji toun si n ran wọn lọ sile ẹkọ.
Oludije naa sọ pe eyi to n ṣe lọya, eyi to n kọṣẹ iṣegun oyinbo ateyi to wa nile ẹkọ nipa wiwa baaluu wa ninu won, bẹẹ oun ko mọ ẹyẹ to ṣu wón toun n fi n ṣaanu wọn.
O ni aaye wa fun musulumu lati ṣe ẹsin rẹ nile awọn ọmọ alai ni iya toun kọ n'Ibadan, bẹẹ naa lo si ṣe wa fawọn ọmọ Kristẹni to wa nibẹ.
"Ti mi o ba lagbara lati sọ gbogbo ipinlẹ Oyo di ẹlẹsin Islam,mo ṣaa lagbara lori awọn ọmọ alailẹnikan to jẹ emi ni wọn ri bii ọlọrun kekere wọn ti mo n fun wọn lounjẹ.
"Bi mo ba ni ki won maa ṣe musulumi, ko sẹni ti yoo ṣe nnkan mi-in ju musulumi lọ ninu wọn. Amọ ṣe o wa ba laakaye mu, kẹni kan wa ni emi ti mi o le sọ awọn iyẹn di musulumi ni ma a sọ gbogbo ipinlẹ Oyo di ẹsin mi, ko ba a mu to.
Mo jade lati dije fun ipo gomina Oyo, ọwọ Ọlọrun ni gbogbo ẹ wa,mo fẹ iranlọwọ yin, ẹ fọwọsowọpọ pẹlu mi, mo ṣadehun fun yin, ma a ṣe daadaa. Oriyomi tẹ ẹ ti mọ ni, mi o ni i yipada."





























