Ẹ forijí mi pé mi ò wá wò yín lásìkò ìkọlu oṣù Kẹ́ta- Ààrẹ Tinubu bẹ àwọn èèyàn Jos

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/X
Lẹyin oṣu mẹjọ, Aarẹ Bola Tinubu ti tọrọ aforiji lọwọ awọn eeyan Anguwan Rukuba, nijọba ibilẹ Ariwa Jos, ipinlẹ Plateau, fun bi ko ṣe yọju si wọn lasiko ikọlu agbebọn to ṣẹlẹ si wọn loṣu Kẹta ọdun 2026 yii.
Ikọlu igba naa pa to ogun eeyan, ọpọ lo si farapa.
Aarẹ Tinubu tọrọ aforiji yii lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrinla oṣu Kọkanla yii niluu Jos, lasiko ipolongo ibo ipo aarẹ saa keji to n du ninu ẹgbẹ oṣelu APC.
"Nigba ti mo wa gbẹyin, papakọ ofurufu ni mo duro"
Ninu alaye Aarẹ Tinubu nipa aiyọju si wọn lapa Oke Ọya, o ni:
"Nigba ti mo wa gbẹyin, papakọ ofurufu ni mo ti duro.
"Ẹ foriji mi ti ẹ ko ba ri mi lapa Oke. Amọ mo ri ipayinkeke naa, mo gbọ iroyin ohun to ṣẹlẹ latọdọ gomina. Mo ri ibẹru loju awọn eeyan.
"Ṣugbọn latigba naa, iyẹn ti yi pada; a jọ n tẹsiwaju ni."
Bẹẹ ni Aarẹ Tinubu wi.
O fi awọn olugbe agbegbe ti ikọlu kan lọkan balẹ, o ni ile wọn yoo di kikọ pada laipẹ, ki awọn ti ko rile gbe mọ le pada silee wọn.
Aarẹ sọ pe ọpọ ẹmi lo ti sọnu ni Plateau lati 2001, bẹẹ lo ba awọn ẹbi to padanu awọn eeyan wọn sinu ikọlu kẹdun.
"Mo ti paṣẹ fawọn ẹṣọ alaabo gbogbo lati gbe igbesẹ ti yoo mu alaafia jọba ni Plateau.
"Oriire lo yẹ ka maa ri, ki I ṣe rogbodiyan. Wọn ko yan ijọba wa sipo lati maa ṣa awọn eeyan lọgbẹ tabi lati maa gbe wọn sin. A gbọdọ mu awọn eeyan kuro ninu oṣi lọ sinu ọrọ̀.
"Ọdẹ aṣogbo ẹgbẹrun kan lo n gba ẹ́kọ́ lọwọ bayii, ẹ maa riṣẹ wọn. Ọkan yin a balẹ labule ati ilu yin."
Tinubu to n dije fun saa keji nipo aarẹ lo sọ bẹẹ.
Bakan naa lo ni awọn ti pese awọn ẹrọ ayaworan agbegbe tijọba ṣeleri.
Ohun to ṣẹlẹ ṣaaju
Ikọlu awọn agbebọn kan lo waye ni Angunwan Rukuba, ni Jos lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2026 to si mu ọpọ ẹmi lọ.
Ọjọ Isinmi Ọpẹ ( Palm Sunday) ni ọjọ naa, lasiko ọdun Ajinde ni.
Awọn to farapa ko lonka, bẹẹ ni awọn eeyan kan di alai nile lori mọ nitori iṣẹlẹ yii.
Nigba to di ọjọ keji oṣu Kẹrin, Aarẹ Tinubu pade ẹbi awọn eeyan ti ijamba naa kan, amọ papakọ ofurufu Jos lo ti ba wọn kẹdun, ko de ibudo iṣẹlẹ gan-an.
O fi da wọn loju nigba naa pe ikọlu bẹẹ ko ni I ṣẹlẹ mọ.
Iwa yii mu ọpọ eeyan bu ẹnu atẹ lu Aarẹ, amọ agbẹnusọ rẹ; Bayo Onanuga, sọ pe ki i ṣe pe Tinubu ko fẹẹ de ibudo iṣẹlẹ.
O ni irinajo to ni lati lọ ni Chad, nibi ti yoo ti ṣepada kan lo fa a.


























