Ọkọ̀ ojú omi tó ń kó àwọn èèyàn lọ ètò ìsìnkú dànù ní Bayelsa, ọmọdé méjì àtàwọn míì kú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan, eeyan mẹrin lo jade laye – ti ọmọde meji wa ninu wọn – lẹyin ti ọkọ oju omi akero kan danu ni ijọba ibilẹ Ijaw, nipinlẹ Bayelsa.
Wọn ṣi n wa awọn kan ninu awọn ero ọkọ naa lasiko ti a n ko iroyin yii jọ amọ awọn adoola ti n wa awọn mii, ti awọn adoola ẹmi naa ṣi n ba iṣẹ lọ.
Ọkan ninu awọn ti ori ko yọ nibẹ sọ pe ọkọ oju omi naa ti wọn fi igi gbẹ ti ọpọ mọ si "love boat" ti wọn wa ninu rẹ ni ọpọ ero ati dukia wọn wa, ti ẹru naa si pọ ju fun ọkọ ọhun ko to danu.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, lasiko to n fidi iroyin naa mulẹ sọ pe ilu Ayama ni ọkọ naa ti n rinrinajo lọ si Ukubie fun eto isinku kan ko to danu loju ọna.
Ọlọpaa ni iwadii awọn fi han pe ṣe ni ọkọ ọhun ṣadede kọṣe lasiko to n ri lọ lori omi.
Awọn asiko ti ọkọ ti danu ni Naijiria ni 2026
Lọdun 2026 yii nikan ṣoṣo, ọpọ igba ni ọkọ oju omi ti danu to si gba ọpọ ẹmi, eyii to mu ki awọn onwoye maa kọminu lori aabo irinajo ori omi ni Naijiria.
Lọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2026, eeyan mẹrinlelogun lo ku ninu ijamba ọkọ to waye ni abule Adiyani to wa ni, Guri, nipinlẹ Jigawa.
Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, eeyan mẹrinla ku, ti wọn jẹ obinrin mẹtala ati ọmọde kan lẹyin ti ọkọ oju omi to ko eeyan to le ni ọgọrun danu nipinlẹ Kebbi lẹyin ayẹyẹ igbeyawo kan.
Nigba ti yoo di inu oṣu Kẹfa, eeyan mẹfa lo jade laye nigba ti wọn doola mẹẹdogun mii lẹyin ti ọkọ to ko ogoji eeyan danu ni Jigawa.
Ninu oṣu Kẹjọ, ọkọ mii tun danu ni Jigawa, nibi ti eeyan mẹrindinlaadọta ti ba omi lọ ti awọn mẹrindinlogun mii si di awati.


























