Gbas-gbos ìjọ Fountain of Life délé ẹjọ́, adájọ́ ní kí Jimmy Odukoya lọ simẹ́dọ̀, kó yé pe ara rẹ̀ ní alákóso ijọ náà, àmọ́ ṣé lóòótọ́ lọlọ́pàá tiléèjọ́sìn pa?

Oríṣun àwòrán, Getty Images/The Fountain of Life Church Hq/Facebook
Ile-ẹjọ giga ti pinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki wọn ti ṣọọṣi Fountain of Life pa titi digba ti idajọ yoo waye lori wahala to n lọ ninu ijọ naa.
Ọjọru, ọsẹ yii ni ile-ẹjọ gbe aṣẹ naa kalẹ, koda, to tun da Pasito Jimmy Odukoya lọwọ kọ gẹgẹ bi pasitọ agba ijọ naa.
Igbimọ iṣakoso ijọ naa lo gba ile-ẹjọ lọ, lati f'opin si gbogbo awuyewuye ati iṣoro ti ijọ naa n dojukọ, lori taani ojulowo alakoso.
Ṣọọṣi naa ni awọn agbofinro ti ju agadagodo sẹnu ọna abawọle rẹ bayii.
Lati bi ọjọ meloo kan sẹyin ni aawọ ti n waye laaarin igbimọ iṣakoso ile ijọsin naa, ati Jimmy Odukoya to jẹ ọmọ oludasilẹ.
Ọrọ ọhun lo ti di ohun ti awọn eeyan n sọrọ nipa rẹ kaakiri Naijiria, ati ni gbogbo agbaye.
Kí ni ilé-ẹjọ̀ sọ?

Oríṣun àwòrán, Others
Nigba to n gbe aṣẹ naa kalẹ lọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, Onidajọ O.O Adewunmi-Oshin sọ pe ki Jimmy Odukoya dẹkun lati maa pe ara rẹ ni pasitọ agba ijọ naa.
Ati pe, ki Odukoya dẹkun lati maa da si gbogbo ohun to n lọ ninu ijọ ọhun, to fi mọ igbesẹ awọn alakoso.
Awọn alakoso naa lọ sile ẹjọ lati fopin si gbogbo wahala to n ṣẹlẹ ninu ijọ ọhun lori ọrọ olori.
Igbesẹ yii lo waye lẹyin ọjọ diẹ ti awọn igbimọ alakoso kede pe Jimmy kii ṣe pasitọ agba ijọ naa mọ, ti wọn si tọka si fidio ti oludasilẹ tẹlẹ, Pasitọ Taiwo Odukoya ṣe.
Ninu fidio naa ni Pasito Taiwo Odukoya ti kede pe Pasitọ Kunle Areogun ni ko gba ipo oun, lẹyin toun ba ti ku tan.
Kete ti awọn alakoso kede eyi, ni wọn tun ti jẹ ko di mimọ pe Pasitọ Rotimi Okpaise ni yoo jẹ adele pasitọ agba ijọ naa, titi digba ti gbogbo eto yoo fi pari.
Jimmy Odukoya fárígá
Ṣugbọn, loju ẹsẹ ni Jimmy Odukoya ati awọn ọmọ ẹyin rẹ ti fariga, to si jẹ ko di mimọ pe bi wọn ṣe yan oun ninu oṣu Kẹsan, ọdun 2023 ba ilana ofin mu, ati pe wọn ko ni aṣẹ lati yọ oun nipo.
Fun idi eyi, gbogbo eto ijọ naa to ti wa nilẹ tẹlẹ ni wọn ti wọgile, lẹyin ti wahala ipo adari ti bẹ silẹ.
Bakan naa i ijọ ọhun tun ti sun isin idupẹ rẹ to yẹ ko waye lọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla siwaju.
Kí ní ìgbìmọ̀ ìṣàkóso sọ?
Ninu atẹjade ti igbimọ iṣakoso ijọ naa fi sita, wọn sọ pe awọn yoo kede ọjọ miran fun isin idupẹ to yẹ ko waye lọjọ Aiku to n bọ.
"Ẹ dakun, a fi n to yin leti pe Isin Idupẹ Ọdun 2026 to yẹ ko waye lọjọ Aiku, ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla la ti sun siwaju. A maa kede ọjọ miran ti a maa ṣe laipẹ," atẹjade naa fidi rẹ mulẹ.
Àwọn ìjọ tí gbas-gbos ti wáyé nítorí yíyan mọ̀lẹ́bí olùdásílẹ̀ gẹ́gẹ́bí adarí lẹ́yìn ikú wọn
Ile-ẹjọ giga ti pinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki wọn ti ṣọọṣi Fountain of Life pa titi digba ti idajọ yoo waye lori wahala to n lọ ninu ijọ naa.
Ọjọru, ọsẹ yii ni ile-ẹjọ gbe aṣẹ naa kalẹ, koda, to tun da Pasito Jimmy Odukoya lọwọ kọ gẹgẹ bi pasitọ agba ijọ naa.
Igbimọ iṣakoso ijọ naa lo gba ile-ẹjọ lọ, lati f'opin si gbogbo awuyewuye ati iṣoro ti ijọ naa n dojukọ, lori taani ojulowo alakoso.

Oríṣun àwòrán, Jimmy Oduko/Taiwo Odukoya/SCOAN
Lati ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2026 yii ni ẹnu ti bẹrẹ si n kun ijọ Fountain of Life Church, to wa niluu Eko lẹyin ti awọn alaṣẹ ijọ naa yọ adari rẹ, Jimmy Odukoya, bii jiga.
Awọn alaṣẹ to yọ pastiọ naa sọ pe awọn gbe igbesẹ ọhun lẹyin ti fidio kan lu sita, ninu eyii ti oludasilẹ ijọ naa Taiwo Odukoya ṣe ko to dagbere faye, nibi to ti darukọ ẹni ti yoo gba ọpa aṣẹ ijọ naa lẹyin oun, ti eni naa kii sii ṣe Jimmy.
Gẹgẹ bi wọn ṣe ọ, wọn ni iyansipo Jimmy gẹgẹ bii adari ijọ naa kii ṣe ohun ti oludasilẹ ijọ ọhun n fẹ ko ṣẹlẹ lẹyin iku rẹ.

Oríṣun àwòrán, JImmy Odukoya
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ọdun 2021 ni Taiwo Odukoya ka fidio naa silẹ ko to dagbere faye.
Ninu fido ọhun to tẹ BBC lọwọ ni oloogbe naa ti sọ pe igbakeji ati pasitọ ijọ awọn ọdọ ni ipo to tọ si Jimmy.
Awọn alaṣẹ ijọ ọhun sọ pe inu oṣu Kejila ọdun 2025 lawọn to mọ nipa fidio naa, eyii to jẹ ọdun meji lẹyin iku Taiwo to waye ninu oṣu Kẹjọ, ọdun 2023.
Wọn fẹsun kan Jimmy pe ko bun awọn gbọ nipa fidio ti baba rẹ ṣe ki wọn to fọntẹ lu iyansipo rẹ gẹgẹ bii adari ijọ ọhun.
Amọ ṣa, ko pẹ ti iroyin naa bẹrẹ si n mi igboro titi ti a tun ri atẹjade mii loju opo ijọ ọhun nibi ti wọn ti kọ iyọnipo Jimmy, ti wọn si fidi rẹ mulẹ pe Jimmy gan ni ojulowo adari ijọ naa.
Awọn gbas-gbos to ti waye lori jijogun ijọ ni Naijiria
Gbas-gbos to n waye lori ijọ Fountain of Life yii kii ṣe igba akọkọ ti ọrọ jijogun ijọ yoo da wahala silẹ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ni 2023 ti wọn kede Jimmy gẹgẹ bii olori ijọ naa ati ẹgbọn rẹ obinrin, Tolu Odukoya-Ijogun, gẹgẹ bii pasitọ agba lọpọ eeyan bẹrẹ si n bere boya iṣẹ Oluwa ti di oye didile.
Asiko mii ti awọn reyan bẹrẹ si n jẹ ọrọ ijọ lẹnu lẹyin ti mọlẹbi gba ọpa aṣẹ ijọ lẹyin iku oludasilẹ ni asiko ti ijọ Synagogue Church of All Nations (SCOAN) kede Evelyn Joshua gẹgẹ bii adari ijọ naa lẹyin iku ọkọ rẹ, T.B. Joshua.
A gbọ lasiko naa pe ọpọ awọn olori ninu ijọ ọhun lo tako iyansipo Evenlyn gẹgẹ bii oludari SCOAN.
Bo tilẹ jẹ pe awọn kan gbagbọ pe idile oludasilẹ ijọ lo yẹ ko maa tẹsiwaju gẹgẹ adari ijọ naa lẹyin iku oludasilẹ, ọpọ eeyan lo gbagọ pe Ọlọrun lo yẹ ko maa yan adari ijọ, ko yẹ ko di oye idile.
Awọn ijọ ti ọrọ adari fẹẹ tuka
Ijọ CAC
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo gbagbọ pe ko yẹ ki ọrọ ijọ maa da ija silẹ, kii ṣe ohun tuuntun mọ nitori oniruru ijọ ni ọrọ adari ti fẹẹ tuka.
Fun apẹrẹ, ijọ Christ Apostolic Church, CAC, wa lara awọn ijọ ti ọrọ ti adari ti fẹẹ tuka lati nnkan bi ọgbọn ọdun sẹyin.
Ijọ naa ṣi duro digbi titi di oni amọ ijọ naa ko wa ni iṣọkan to wa ni ibẹrẹ.
Lonii, adari meji ọtọtọ, to fi mọ logo ọtọtọ ni ijọ CAC ni bo tilẹ jẹ pe orukọ kan naa lo ṣi n jẹ.
Foursquare Gospel Church
Ijọ mii ti ọrọ adari daamu ni ijọ Foursquare Gospel Church lẹyin ti adari rẹ nigba kan ri, Wilson Badejo, kọ lati fi ipo silẹ lẹyin ti akoko rẹ to.
Iroyin ni o gbiyanju lati joko sori aga adari naa, koda, wọn ni o fun awọn kan ni riba lati ma fi ipo ọhun silẹ amọ pupọ awọn igbimọ ijọ tako o.
Lẹyinorẹyin, ọrọ adari di eyii ti wọn n gbe lọ silemẹjọ amọ o pada yanju.
Ijọ Celestial Church of Christ
Pasitọ Samuel Bilewu Joseph (SBJ) Oshoffa lo da ijọ CCC silẹ, ijọ naa si wa lara awọn ijọ to mi ati gbogbo agbaye Naijiria titi.
Iwe itan fidi rẹ mulẹ pe oluṣo agutan naa gbaawẹ ogoji ọjọ ninu igbo kan ni Dahomey, to jẹ Republic of Benin lonii ki ipe rẹ to fọhun.
Amọ nnkan gbọna mii yọ lẹyin iku rẹ lọdun 1985 latari bi ko ṣe kede ẹni ti yoo joko sori aga adari lẹyin rẹ.
Gbas-gbos to waye lasiko naa le koko to bẹẹ ti ọrọ naa di ọrọ ile ẹjọ.
Lonii, ijọ CCC jẹ ọkan lara awọn ijọ to gbajumọ julọ ni Naijiria bo tilẹ jẹ pe awọn kan lara awọn ọmọ ijọ naa maa n ṣe ohun ti awọn adari ijọ juwe bii pipa ilana da.




























