"Ìgbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo ti kó sọ́wọ́ ajínigbé, ohun tí ojú mí rí rèé"

Iṣẹ agbẹ ni Sunday Abogunrin Omobolade yan laayo ni ipinlẹ Kwara, to si gbajumọ daadaa ni agbegbe rẹ.
Fun Omobolade, ko le gbagbe iṣẹlẹ to ṣẹlẹ sii lọjọ karun-un, oṣu Karun-un, ọdun 2026, nigba to ko sọwọ awọn ajinigbe lasiko to wa ninu oko rẹ.
Latigba ti Sunday Omobolade ti ja ajabọ nigbekun awọn ajinigbe naa, ni ko ti pada de inu oko rẹ ọhun mọ, to si ti jọwọ gbogbo iṣẹ to faarọ ọjọ aye rẹ ṣe, nitori ibẹru awọn ajinigbe.
Nigba to n ba BBC sọrọ, Omobolade jẹ ko di mimọ pe inu oko loun wa lọjọ naa, toun gbọ pe awọn kan n yinbọn, to si loun gbiyanju lati sa asala fun ẹmi ara oun.
"Ni ilu Isanlusi lo ti ṣẹlẹ lọjọ karun-un, oṣu Karun-un, ọdun 2026. Bi mo ṣe de oko, mi o mọ pe wọn ti n ṣọ mi, ni mo kan ri pe ibọn de sori mi, bi mo yipada pe ki n maa salọ, bi wọn ṣe ju ada bii mẹta sori mi niyẹn," sọ fun BBC.
Ọkunrin naa ni ibi toun ti n salọ, ni wọn ti ja okun aṣọ toun wọ. Asiko naa lo loun mọ pe wọn ti ji eeyan mẹrin gbe.
"Mo ṣubu lulẹ, ki n too mọ, wọn ti ja okun aṣọ ti mo wọ. Nigba ti maa wo ẹgbẹ, mo rii pe wọn ti ji eeyan bii mẹrin kan naa gbe, ti wọn ko wọn wa ba mi ninu oko.
"A rin irin yẹn lati aarọ di alẹ. O to bii agogo meji aabọ loru, wọn lu mi pẹlu pẹtẹpẹtẹ ada. Ibi ti a jokoo si, bi wọn ṣe sọrọ tan wọn sọ ede kan sira wọn, awọn mẹrin kan dide ninu awọn meje, wọn wa rin siwaju.
"Bí mo ṣe sálọ nígbà àkọ́kọ́"
O ni ibi ti awọn wa, loun ti ṣe ipinnu lati sa asala fun ẹmi ara oun, to si loun sọ fun awọn ti wọn jọ ji wọn gbe.
"Mo wa n sọ fun awọn ti wọn jọ ko, wi pe a ko nii ba wọn de ibi yẹn, wi pe ẹnikan lo sọ pe ki awọn wa gbe mi. O tunmọ si pe ti mo ba tẹle wọn debẹ, ti a ko ba ta gbogbo dukia ile wa tan, wọn ko nii ju mi silẹ," Omobolade sọ bẹẹ.
O tẹsiwaju pe, "Mo sọ fun wọn pe niṣe ni mo maa salọ, ati pe ẹni ori yọ, o dile o. Mo fi ọgbọn tu okun ọwọ awọn eeyan, mo fi okuta ja okun ọwọ temi.
"Awọn boroboro yẹn ti n sun, bi mo ṣe dide niyẹn, ti mo fi gbera, awọn yooku naa sare tẹle mi ni, a ti sare lati oru, ni nnkan bi agogo meji oru, a n sare lọ titi di nnkan bi aggogo mẹfa aarọ."
"Bi wọn ṣe mu mi"
Ọkunrin to yan iṣẹ agbẹ naa ṣalaye pe, "Ibi ti a ti n salọ ni ọkada meji ti yọju, wọn ko ibọn AK-47 dani, mo si sare gba ọna ọtun, awọn yooku sare gba apa osi. Ere ti mo n sa, inu igbo ni mo tun n wọ lọ. Wọn n tẹle mi, wọn si tun n yinbọn.
"Mo wa ranti pe igi kan ti mo fo kọja lẹẹkan, igi kan wa lẹgbẹ rẹ to ṣubu, o ṣidi, iho si wa nibẹ. Mo wa wọnu ẹ lọ, mo si da koriko bo ara mi.
"Lati nnkan bi agogo meje aarọ, ibẹ ni mo wa titi di nnkan bi agogo mẹsan alẹ. Igba to ya ni mo n gbọ ohun ọkada, awọn bororo wa yọju, wọn ri mi, bi wọn ṣe mu mi niyẹn.
"Wọn n da ada bo mi, wọn n sare tẹle mi lẹyin, emi naa si n sare lọ niwaju. Mo wa rii pe ibi ti mo n sare lọ, ile koriko kan wa niwaju, awọn bororo si n jade nibẹ, ibẹ ni mo ti juwọ silẹ. Wọn wa mu mi lọ sinu ile yẹn."
Mo lo to oṣu kan lahaamọ wọn
"O to bi oṣu kan ti mo fi wa nibẹ. Awọn to wa ninu ile pẹlu mi, ti wọn n sọ pe wọn fẹẹ ko owo ori wọn wa. Ẹni to ba ko owo igbanisilẹ wa, wọn le mu ẹlomiran silẹ pẹlu owo.
"Ibẹ ni mo ti wo o pe awọn eeyan yii ko nii fi emi gan silẹ, bi mo ba ko owo silẹ, ibẹ ni mo ti ṣe ipinnu wi pe mo maa salọ.
"Mo kọkọ n fọ ogiri nibi kan, ni ẹnikan ba fẹẹ ṣofofo, awọn to ku lu ẹni naa. Oru ti a n fọ ogiri, ki a to fọ ogiri tan, wọn ti mọ. Itọ ti a ba wa tọ, niṣe ni mo n da a jọ soju ogiri yẹn, ko le rọ, nitori pe ile alamọ ni.
"Bi mo ṣe fo jade niyẹn, ti wọn si bẹrẹ sii yinbọn. Ibọn ba eeyan meji ninu wa loru ọjọ yẹn. Inu igbo yẹn ni mo wa fun ogoji ọjọ.
"Nigba ti mo tun pada sibi ti mo tun ro pe o le jẹ ọna, ibẹ ni wọn tun ti pada mu mi ni igba kẹta. Awọn meji lo mu mi, wọn lu mi, wọn fẹẹ pa mi.
"Wọn wa gbe mi pada sibi ti mo ti sa kuro. Wọn kii fun wa lounjẹ, ọjọ to ba wu wọn ni wọn yoo fun wa ni ṣibi irẹsi kekere bayii, o tun di ọjọ kẹta. Ori aṣọ ti a wọ ni wọn maa bu irẹsi naa si."
"Bí mo ṣe jáde"
O tẹsiwaju pe kii ṣe pe awọn ajinigbe naa deedee fi oun silẹ, bi ko ṣe pe lẹyin ti awọn araalu oun da owo, ni awọn agbebọn naa too fi oun silẹ lahaamọ wọn.
Omobolade sọ pe owo to to miliọnu mẹrinla naira ni wọn gba lọwọ awọn, koun too le ni ominira.
"Ilu mi lo ṣe e, ti mo fi jade. Wọn san owo to to miliọnu mẹrinla. Lati igba yẹn, mi o le pada soko mọ, oko kaṣu wa nibẹ. Mo ni ẹgẹ ati awọn nnkan miran. Mi o le wọ ilu mọ nitori pe awọn to n ṣofofo wa, ti wọn maa sọ pe mo tun ti de, ki wọn wa gbe mi."



























