"Ba ma yi! Ba ma yi!!" Kí ni ìtumọ̀ ariwo táwọn kan pa lé Tinubu lórí ní mọ́ṣáláṣí Abuja tí APC ń di ẹ̀bi rẹ̀ rú ẹgbẹ́ alátakò

Oríṣun àwòrán, @Bola Ahmed Tinubu
Aisi atilẹyin fun awọn oluwọde jẹ ọkan lara ohun to n ru wọn ninu, to si n da kun ibẹru wọn nigbakuugba ti wọn ba ri ipolongo ibo.
Laipẹ yii ni ori ayelujara kun fun fidio atawọn fọto awọn oloselu nilẹ Naijiria tawọn araalu n pariwo le lori lasiko ti wọn lọ sibi eto laarin ilu.
Ọkan lara awọn fidio naa lo se afihan awọn araalu lẹkun ariwa ilẹ yii ti wọn n pariwo 'A ko ni se e' eyi ti wọn n pe ni Bamaiyi ni ede Hausa.
Aarẹ Bola Tinubu lo lọ kirun jimọ ni Mosalasi kan nilu Abuja lọsẹ to kọja nigba ti isẹlẹ naa ti waye.
Nitori isẹlẹ naa, awọn osisẹ agbofinro mu awọn eeyan to le ni aadọrin fun ẹsun pe wọn n pariwo Bamaiyi lasiko ti aarẹ Tinubu n kuro ni Mọsalasi naa.
APC fẹsun kan ẹgbẹ oselu ADC ati NDC pe awọn lo n se onigbọwọ awọn eeyan to n pariwo Bamaiyi
Amọ aarẹ Tinubu ti wa kede ni ibẹrẹ ọsẹ yii pe kawọn agbofinro fi awọn eeyan to wa ni ahamọ wọn silẹ lori isẹlẹ naa.
Ni ọpọ igba, awọn oloselu maa n naka aleebu sira wọn pe awọn lo n se onigbọwọ ikọlu to ba waye lasiko ipolongo ibo koowa wọn.
Laipẹ yii, ẹgbẹ oselu APC to n sejọba lọwọ ni Naijiria, ti fi ẹsun kan awọn alatako rẹ, ADC ati NDC pe awọn lo wa nidi isẹlẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ikọ ipolongo ibo ẹgbẹ APC, Dele Alake, fisita, o fi ẹsun kan ẹgbẹ oselu alatako pe awọn lo n se onigbọwọ awọn eeyan naa lati maa pariwo Bamaiyi lati fi tako ẹgbẹ oselu APC lasiko ipolongo ibo rẹ.
Alake tun wa ke sawọn asaaju ẹgbẹ oselu alatako lati dẹkun awọn iwa to le fi ẹmi awọn ọdọ sinu ewu.
Ki ni itumọ Bamaiyi?

Oríṣun àwòrán, @OfficialAPCNg
'A ko se ni itumọ Bamaiyi, o si jẹ ọrọ to n safihan aisi ifẹ tabi atilẹyin fun ẹni ti wọn ba sọ ọrọ naa si.
Ọjọgbọn Kamilu Sani Fagge, tii se olukọ kan ni ẹka imọ nipa ọrọ oselu ni fasiti Bayero to wa nilu Kano ati onwoye nipa ọrọ oselu Naijiria, lasiko to n ba BBC sọrọ salaye nipa ọrọ naa.
Fagge ni ọrọ Hausa ni Bamaiyi, eyi to tumọ si pe "a ko se atilẹyin fun ọ nidi ọrọ oselu."
O fikun pe " A ko se mọ tumọ si igbesẹ oselu ti eeyan kan tabi ikọ oloselu kan le lo lati se afihan pe awọn ko ni se atilẹyin fun ẹni ti wọn ba sọ ọrọ naa si."
"Tawọn eeyan ba n pariwo "Rara, Rara" fun oloselu kan lasiko ipolongo ibo, o jẹ ami pe awọn eeyan n tako oloselu bẹẹ atawọn ilana iselu rẹ." Onimọ nipa eto oselu naa lo sọ bẹẹ.
Ọjọgbọn Kamilu Fagge ni nilana sayẹnsi nipa oselu, a le se afiwe isẹlẹ naa bii atako oludibo kan.
"O jẹ ami pe awọn oludibo ko si lẹyin ẹni naa ti wọn dibo fun tẹlẹ."
O fikun pe irufẹ ifẹhonuhan naa ni wọn ko tii lo ri nilẹ Naijiria.
"Wọn se oselu lasiko isejọba alagbada akọkọ ati ikeji, nitori naa, irufẹ ilana bayii ko jẹ tuntun."

























