"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi ló ti di grandma kí n to bí ìbẹrin nípa IVF"

Àkọlé fídíò, Iya Ibẹrin
"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi ló ti di grandma kí n to bí ìbẹrin nípa IVF"
Published

Obinrin kan to ṣẹṣẹ bi ibẹrin lẹẹkanṣosọ nipasẹ ilana IVF ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri ki awọn ọmọ naa to de.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Olushola Olonade sọ pe oun fi ọpọ ọdun wa ọmọ ti gbogbo igbiyanju oun si ja si pabo.

Nigba to di akoko igba kan, o ni oun gbadura pe bo tilẹ jẹ ẹyọkan ṣoṣo loun bi inu oun yoo dun, nitori ọlọmọ kan kuro ni ki lo nbi.

Amọ nigba ti Eledua yo gbe iṣe rẹ de, ilana IVF ti tọkọtaya naa ṣe so eso rere, wọn si bi ibẹrin lantilanti.

Ọkọ obinrin ọhun, Segun Olonade, sọ fun BBC pe oun ti bi ọmọ mẹrin tẹlẹ, amọ oun gbadura fun ọmọ mii lati ọdọ iyawo oun ki ayọ obinrin naa le kun.

Gẹgẹ bo ṣe, ẹru ko ba oun pe iyawo oun bi ibẹrin, koda, to ba bi marun un gan apa oun ka.

Iyaafin Olushola Olonade sọ fun BBC pe oriṣiriṣi ipenija loun la kọja ki awọn ọmọ naa to de, koda, o ni oun tilẹ ri ẹjẹ lakoko kan ti oun si ro pe oyun naa ti bajẹ.

Ṣugbọn lẹyinorẹyin, ayẹwo fi han pe ọmọ mẹrin ọtọtọ lo wa ninu oun, to si bi awọn ọmọ naa pẹlu ayọ ati alaafia.

O ni lọpọ igba lawọn eeyan n ṣe igbeyawo loju oun ti wọn a si bi ọmọ ti oun ko si bimọ.

Iya ibẹrin naa fi kun pe ọpọ awọn ọrẹ oun ni ọmọ wọn wọn ti n ṣe abiyamọ ki Eledua to pada da oun naa lohun.