'Ọdún mẹ́rin gbọdọ̀ pé kó tó lè fi kún owó ilé' - Àwọn kókó tó yẹ kí o mọ̀ nípa àbádòfin tuntun tíjọba ṣe tako àjẹjù lárìnlọọ̀dù àti 'agent'

Oríṣun àwòrán, Ayodele Johnson/Getty Images
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Enugu ti ṣagbekalẹ abadofin ti yoo maa tọpinpin owo ile tawọn ayalegbe n san ati iye ti awọn onile le fi kun owo ile.
Ile fẹnuko wi pe awọn onile ko gbọdọ ṣe afikun owo ile ju ida 2% lọ.
Abadofin ọhun ni wọn pe akori rẹ ni "A Bill for a Law to Amend the Landlord and Tenant Second Amendment Bill, Cap. 101, Revised Laws of Enugu State 2024 (House Bill No. 3, 2025)."
Ile buwọlu abadofin yii lẹyin ti họnarebu Iloabuchi Abugu to n ṣoju ẹkun Nkanu West da aba naa, eyi ti igbakeji adari ile, Họnarebu Jane Eneh naa fọwọ si.
Nigba ti o n jabọ fun ile, alaga igbimọ to n ṣiṣẹ lori ilegbee ati okowo, Okey Mbah, to n ṣoju ẹkun Nkanu East, ṣalaye pe igbimọ naa ti jiroro pẹlu awọn tọrọ kan.
Mbah sọ pe abadofin yii yoo dẹkun bawọn onile ṣe maa n gbowo le ile loorekoore ati bawọn aṣoju awọn onile ṣe maa n gbowo rọgun rọgun.
Họnarebu Mbah ni abadofin yii yoo mu adinku ba iye owo ile ti araalu n san pẹlu ida 60%.
Ninu ọrọ rẹ, adari ile igbimọ aṣofin Enugu, Họnarebu Uche Ugwu, sọ pe abadofin yii jẹ ọkan pataki ninu awọn eto ti ijọba n ṣe nipinlẹ Enugu eyi ti yoo ṣanfaani fun araalu.
Họnarebu Ugwu ni abadofin yii ni yoo tun wa ojutuu si inira ti araalu maa n ni lasiko ti wọn ba fẹ sanwo ile.
''Ofin yii yoo nira lati tẹle fawọn onile pẹlu bi gbogbo nnkan ṣe gbowo lori bayii''
Abadofin yii tawọn araalu lanfaani lati jiroro lori rẹ lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2026 yii yoo di ofin ti Gomina Peter Mbah ba ti buwọlu u.
Ile aṣofin ṣagbeyẹwo abadofin naa lẹyin tawọn eeyan Enugu ke gbajare lori owo rọgun rọgun tawọn onile atawọn aṣoju wọn n gba lọwọ araalu to ba fẹ gba ile.
Ẹwẹ, onile kan nipinlẹ Enugu ti orukọ rẹ n jẹ Onyekwere Johnson sọ fun iwe iroyin Punch pe abadofin ti ile aṣofin ipinlẹ Enugu ṣe wi pe yoo nira pẹlu bawọn aṣofin ṣe sọ afikun owo ile ko gbọdọ ju ida 2% lọ.
Ọgbẹni Johnson sọ pe ofin yii yoo nira lati tẹle fawọn onile pẹlu bi gbogbo nnkan ṣe gbowo lori bayii
Koko mẹrin to yẹ ki o mọ nipa abadofin ile aṣofin Enugu lori owo ile sisan
1. Onile ko le maa fowo kowo ile lọdọọdun
Lara nnkan to yẹ ki o mọ ni pe awọn onile ko ni i le maa ṣe afikun owo ile bo ba ṣe wu wọn mọ.
Abadofin naa la a kalẹ wi pe onile ni lati duro fun ọdun mẹrin ki wọn to le ṣe afikun owo ile.
Afikun owo ile ti onile le san ko gbọdọ ju ida 2% owo ti ayalegbe n san lọ.
Fun apẹẹrẹ, ti ayalegbe ba n san N500,000 lọdun, onile ko gbọdọ fi le owo ile ju N10,000 lọ to ba fẹ ṣe afikun owo ile eyi to jẹ afikun ida 2%.
2. Owo ile ti onile ba ṣatunṣe le lori le lọ soke
Abadofin ti ile igbimọ aṣofin Enugu gbe kalẹ fun onile laṣẹ lati ṣe afikun owo ile pẹlu ida 10%.
Eyi tumọ si pe onile to ba ṣatunṣe lori ile rẹ le ṣe afikun owo ile ju ida 2% lọ.
Fun apẹẹrẹ, ti ayalegbe ba n san ₦500,000 lọdun, onile le ṣafikun owo ile pẹlu ₦50,000 eyi to tumọ si pe ₦550,000 ni owo ile tuntun ti ayalegbe naa yoo maa san.
3. Adinku yoo ba owo ti ayalegbe n san fawọn aṣoju onile
Yatọ si pe onile ko le ṣafikun owo ile bo ba ṣe wu wọn, adikun yoo tun ba owo tawọn aṣoju onile naa maa n gba lọwọ ayalegbe.
Iru owo yii lo maa n jẹ ki owo tawọn onile n gba lọwọ ayalegbe maa n pọ.
Alaga igbimọ ile to ṣiṣẹ lori abadofin naa sọ pe owo tawọn aṣoju onile maa n gba lọwọ ayalegbe wa lara nnkan ti ijọba fẹ dẹkun pẹlu ofin tuntun ọhun.
4. Ijiya onile labẹ ofin yoo pọ si i lori lile ayalegbe kuro nile
Abadofin yii tun sọ pe onile ko le ṣadeede le ayalegbe kuro nile bi o ṣe wu u.
Ofin tuntun yii ṣe alakalẹ wi pe onile gbọdọ fun ayalegbe ni iwe lati sọ fun un nipa akoko ti yoo fi ile rẹ silẹ ki o to ṣe bẹẹ.
Fun apẹẹrẹ, onile gbọdọ fun ayalegbe ni iwe ilẹ ẹjọ ki o to gbe iru ayalegbe bẹẹ lọ sile ẹjọ.
Ati wi pe onile gbọdọ tẹle ofin ki o to le sọ pe ki ayalegbe kuro nile.


























