Ta ló lọ yí orúkọ pápá ìṣeré ìlú Oṣogbo padà sí tí Ademola Adeleke tí gómìnà ìpínlẹ̀ Osun fi ńfọnmú, pàṣẹ kí wọ́n yọ pátákó orúkọ náà dànù ní kíá?

Oríṣun àwòrán, Adeleke ademola/osun defender
Bi ipalẹmọ ṣe ti bẹrẹ fun iburawọle fun saa keji nipo gomina ipinlẹ Osun fun Ọmọọba Ademola Adeleke ni awọn eeyan kan naa n palẹmọ lapa ibi kan, eyi to mu wọn lọ ri patako ajuwe to kede ayipada orukọ papa iṣẹre ilu Osogbo pada si Ademola Adeleke Imole Stadium, Osogbo.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Ọjọruu, ọjọ kejidinlogun oṣu Kọkanla yii ni wọn ri patako ajuwe naa si ẹnu ọna abawọle papa iṣere naa, lọwọ owurọ kutu.
Ṣugbọn nigba ti yoo fi di nnkan bii aago marun-un irọlẹ, aṣẹ wa lati ọfiisi Gomina Ademola Adeleke pe ki wọn fa patako ajuwe naa yọ kia, bẹẹ ni wọn si ṣe fa a yọ lẹyẹ o sọka.
Ki lo ṣẹlẹ gan-an?
Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kọkanla yii ni wọn yoo bura wọle sipo gomina lẹẹkeji fun Ademola Adeleke.
Bi ọjọ naa ṣe n sunmọ etile ni awọn kan lọ ṣeto ayipada orukọ stediọmu naa lọwọ ara wọn bi a ṣe gbọ.
Bo tilẹ jẹ pe atunṣe n lọ lọwọ lara papa iṣere naa, ti ọpọ nnkan si ti bajẹ nibẹ, sibẹ, awọn to gbe patako ajuwe naa wa ko wo eyi,wọn ri I si apa ibi ti gbogbo oju yoo ti ri i.
Oṣiṣẹ ibẹ kan ti ko darukọ rẹ tilẹ fidi ẹ mulẹ, pe Gomina Adeleke n bọ waa ṣe abẹwo si papa iṣere yii, bi wọn ko tilẹ ti I fi atẹjade sita nipa rẹ.
Ki lo wa de tijọba paṣẹ ki wọn yọ patako naa kuro?
Kọmiṣanna fun eto iroyin ati ilaniloye awujọ nipinlẹ Osun, Kolapo Alimi, fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni ijọba paṣẹ ki wọn hu patako naa kuro nibẹ kia.
Kọmiṣanna naa sọ pe awọn to ri patako to n kede ayipada orukọ naa ko gba aṣẹ ijọba Osun ki wọn too ri I mọbẹ.
Kolapo sọ pe:
"Awọm to lọ gbe patako naa sibẹ ko gba aṣẹ ki wọn too ṣe bẹẹ.
"Ohun ti wọn ṣe ni pe wọn sọ fun ẹnikan pe ko sọ fun gomina pe awọn fẹẹ ṣe e, gomina si ni oun yoo fi lọ, oun yoo si fun wọn labọ bo ba ṣe jẹ.
"Amọ wọn ko duro de aṣẹ latọdọ gomina. Gomina ti ni ki wọn yọ patako naa kiakia."
Bẹẹ ni Kọmiṣanna fun iroyin ati ilanilọye l'Osun ṣalaye lẹyin ti wọn fa patako naa yọ nirọlẹ Ọjọru ti wọn ri I mọlẹ.
Bi eto iburawọle fun saa keji Gomina Ademola Adeleke yoo ṣe lọ
Gẹgẹ bi wọn ṣe kede alakalẹ eto ọlọsẹ kan naa, ọjọ Ẹti ni eti yoo bẹrẹ pẹlu irun Jimọ ti wọn yoo ki ni mọṣalaṣi nla ilu Osogbo, eyi to wa ni Oja Oba, Osogbo.
Eto adura ọlọkan-o-jọkan nilana ẹsin mi-in yoo tẹle e.
Aṣekagba idije bọọlu afẹsẹgba ti wọn pe ni "Ademola Adeleke Victory Soccer Tournament" yoo waye pẹlu.
Ọrọ ikinikaabọ lati ẹnu Senator Shehu Sani, ti yoo da lori awọn akori bii "Federalism Dilemma: Navigating Institutional Friction, Local Government Allocations, and Executive Overreach."
Eto isin idupẹ ni All Souls' Anglican Church Cathedral, Osogbo ati bẹẹ bẹẹ lọ.


























