Ìjọba ra ọkọ̀ bàálù $60m fún Ààrẹ wọn, àwọn aráàlú figbe ta

Oríṣun àwòrán, Ghana Air Force/Facebook
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ọrọ naa ṣi n ja rainrain kaakiri orileede Ghana, lori bi ijọba ṣe kede rira ọkọ baalu fun Aarẹ wọn.
Owo ti ko din ni ọgọta miliọnu owo dọla ni ijọba sọ pe awọn fi ra baalu naa fun ileeṣẹ Aarẹ, lati maa gbe kaakiri agbaye.
Pẹlu awọn araalu ṣe n fọnmu lori igbesẹ tuntun ti ijọba gbe yii, sibẹ ijọba ti wa sọ pe ko si ohun to buru ninu rira baalu fun Aarẹ.
Ko si nnkan to n bi awọn araalu ninu lori igbesẹ tuntun yii, bi ko ṣe pe asiko ti awọn eeyan n tiraka lori bi eto ọrọ aje wọn ṣe ri, ni ijọba kede rira baalu olowo iyebiye fun Aarẹ.
Bakan naa ni awọn olori ẹgbẹ alatako n fẹsun kan Aarẹ John Mahama pe aṣilo ipo lo n lo, pẹlu awọn igbesẹ to n gbe.
Sibẹ, ijọba sọ pe o pọn dandan fun ijọba lati ra baalu tuntun, lati fi rọpo baalu atijọ ti Aarẹ n gun kaakiri, eyi ti wọn sọ pe ọjọ ti lọ lori rẹ.
Oniruuru awuyewuye lo ti dide bayii, pẹlu bi Mahama ṣe n gbiyanju lati wa nnkan ṣe si ayipada lẹka eto ọrọ aje, nipa iranlọwọ lati ọdọ IMF.

Oríṣun àwòrán, Ghana Air Force/Facebook
Níbo ni wọ́n ti ṣe bàálù náà?
Ileeṣẹ Dassault Aviation to n ṣe awọn baalu nilẹ Faranse lo ṣe baalu naa, awọn si ni wọn gbe e wa fun ileeṣẹ ologun oju ofurufu lọjọ Aje, pẹlu owo ti ko din ni mọkanlelọgọta dọla.
Ninu oṣu Kejila, ọdun to kọja ni ile igbimọ aṣofin buwọ lu igbesẹ lati ra baalu naa, lati mu ki iṣẹ awọn ọmọ ogun oju ofurufu lọ soke.
Yatọ si eyi, wọn yoo tun ra ọkọ baalu ẹlicọputa mẹrin fun ileeṣẹ ologun oju ofurufu.
Gbara ti wọn gbe baalu ọhun de, ni wọn ti n fi omi wẹ ẹ lọjọ Aje.
Ṣugbọn bi baalu naa ṣe balẹ pẹlu ikede, ni awọn araalu ti bẹrẹ sii sọrọ si ijọba, paapaa awọn alatako ti wọn n sọ pe kii ṣe iru asiko yii lo yẹ ki ijọba ra baalu naa.
Kí ló dé tí àwọn aráàlú ń sọ̀rọ̀?
Ko si nnkan meji to tubọ jẹ ki awuyewuye naa pọ, bi ko ṣe pe nigba ti Mahama wa ninu ẹgbẹ alatako, ko too di Aarẹ, oun naa ti tako rira baalu tuntun fun ileeṣẹ Aarẹ.
Ohun t'awọn eeyan wa n sọ bayii ni pe, ki lo de ti Mahama to n tako rira baalu fun ileeṣẹ Aarẹ, wa n ra baalu tuntun bayii?
Samuel Abu Jinapor lati inu ẹgbẹ alatako sọ pe kii ṣe asiko ti awọn araalu n tiraka lati rijẹ pẹlu bi nnkan ṣe gbowo lori yii, lo yẹ ki aarẹ pinnu lati ra baalu tuntun.
O ni ọpọ awọn ọdọ ni wọn ko ri iṣẹ ṣe, ti wọn ko si niṣẹ lọwọ lati maa wa ounjẹ funra wọn, ṣugbọn to ni ijọba ko ri awọn nnkan naa ro.
"Nnkan ti ko jẹ itẹwọgba nigba ti o wa ninu ẹgbẹ alatako, ko yẹ ko jẹ itẹwọgba nigba ti o de ijọba, ṣugbọn nitori pe awọn to di agbara mu ti yi pada," o sọ bẹẹ.
O fẹsun iwa agabagebe kan ẹgbẹ oṣelu NDC to n ṣe akoso ijọba lọwọ, pẹlu bi awọn olori wọn ṣe tako rira baalu tuntun fun aarẹ nigba ti wọn ko tii de ipo naa.
"Aráàlú ní láti mọ iye tí owó bàálù náà jẹ́"
Jinapor tun sọ pe ijọba ni lati ṣalaye lẹkunrẹrẹ lori ọna ti wọn gba ra baalu mọ, to fi mọ gbogbo owo ti wọn na lori rẹ, fun araalu lati mọ.
Bakan naa lawọn araalu tun n sọ pe niṣe lo yẹ ki ijọba na owo naa sori awọn ohun ti araalu nilo.
"Owo yii le gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan nọọsi si iṣẹ, to fi mọ olukọ ẹgbẹrun lọna igba," ẹnikan sọ bẹẹ lori ikanni 'X'
Ṣugbọn ijọba ti wa sọ pe pupọ awọn to n bu ẹnu atẹ lu ijọba ni wọn ko mọ ohun ti wọn n sọ, nitori pe eto ọrọ aje Ghana ti ni ilọsiwaju latigba ti NDC ti gba iṣakoso.
NDC kò fìgbà kankan tako ríra ọkọ̀ bàálù
Peter Lanchene Toobu, alaga igbimọ to n ri sọrọ ileeṣẹ ologun nile igbimọ aṣofin Ghana sọ pe ko sigba kan ti ẹgbẹ naa tako rira ọkọ baalu fun aarẹ.
O lohun ti wọn tako nigba naa ni asiko ti ijọba gbọdọ ra ọkọ baalu naa, eyi ti kii ṣe asiko ti wọn n koju iṣoro eto ọrọ aje.
"A fẹnuko pẹlu ilana lati ra ọkọ baalu tuntun," o sọ bẹẹ.
O jẹ ko di mimọ pe Ghana ko le ra baalu lasiko ti wọn n wa iranlọwọ biliọnu mẹta dọla lati ọdọ ajọ IMF.
"Eto okoowo ọrọ aje wa ti duro ṣinṣin lorileede yii, pẹlu bi owo ohun ti wọn n ko wọle ṣe ti walẹ, ati pe asiko to dara ree," o fidi rẹ mulẹ.
Toobu fi kun ọrọ rẹ pe ijọba ra baalu naa lai jẹ pe wọn lọ ya owo nita, pẹlu bo ṣe jẹ ko di mimọ pe eto ọrọ aje wọn ti lagbara si i.
Báwo ni bàálù ọ̀hún ṣe rí?
Agbẹnusọ ileeṣẹ Aarẹ, Kwayke Ofosu sọ pe baalu naa ko ni ọpọ awọn ohun tawọn eeyan pariwo rẹ ninu.
Ofosu sọ pe Aarẹ ko ni ipinnu lati "wẹ loju ofurufu".
"Ko si baluwẹ ninu baalu naa. Aarẹ Mahama ko ni erongba lati wẹ loju ofurufu," o sọ bẹẹ.
Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe baalu naa ni aga ijokoo to ṣe e sọ di bẹẹdi, nigba teeyan ba fẹẹ sun, ṣugbọn ko ni yara adani.
Ijọba sọ pe baalu tuntun yii ni yoo rọpo Falcon 900EX ti wọn ti n lọ lati ọdun mẹrindinlogun sẹyin, eyi to jẹ gbogbo igba ni wọn n na owo lee lori fun atunṣe.
Baalu tẹle naa ni wọn ti gba silẹ fun ọpọlọpọ oṣu lorileede France, iyẹn lọdun 2025, ti wọn si ti gbe e lọ fun atunṣe.
Inu oṣu Kọkanla, ọdun 2023 ni wọ ṣe ọkọ baalu Dassault Falcon 6X to tobi fun okoowo.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ Dassault Aviation to ṣe baalu naa ṣe ṣalaye, baalu Falcon 6X tuntun naa jẹ ti igbalode fun igbe aye ọtun, to si tobi daadaa.
Wọn ni o gba to eeyan mejila si mẹrindinlogun, to si le rin irin ajo ọlọdun pipẹ, pẹlu awọn ẹnjiini to lagbara fun irin ofurufu.




























