Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Eloo ni lita bẹntiroolu kan bayii lẹyin tijọba apapaọ ti kede adinku owo epo fun oṣu kan?
Ka tiẹ to maa sọrọ nipa iye ti wọn n ta epo bayii, ṣe ijọba ti da sọbsidi ori epo pada ni?
Ibeere yii gan an lọpọ ọmọ Naijiria naa n beere, amọ, ijọba ti sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ
A ti pe ki ni yoo ṣẹlẹ lẹyin oṣu kan taraalu ba ti ra epo lẹdinwo tan?
Kan soju opo wa fun idahun si gbogbo ibeere rẹ
'''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''
Eemọ ree o!
Nibo?
Ọmọ wòlíì kan maa ni wọn lo f'orúkọ wòlíì míràn lu jìbìtì
Bawo lo ṣe jẹ?
Adewale Ogoemi ni wọn fẹsun kan pe o lu àwọn tó ń wá ojútùú sí ìṣòro ayè wọn lórí ayélujára ni jibiti miliọnu mejidinlogun naira
Lọrọ kan, afurasi ọhun ti ko si gbaga ọlọpaa bayii
ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa lori ikanni BBC News Yoruba
'''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''
Iwọ́de ìwà ipá sáwọn àjèjì tun ṣẹyọ lorilẹede South Africa
ṣe bo ti lọọlẹ tẹlẹ ni?
Lanaa Ọjọbọ lawọn oluwọde naa tun dana sun ọ̀pọ̀ ọkọ̀ ti wọn si tun ja àìmọye ilé ìtajà lólè


