Iléeṣẹ́ ológun kéde ìsìn ìkẹyìn fáwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nílùú Igbokoda

Agbegbe ti ọkọ baalu ẹlicọputa jabọ si niluu Igbokoda, ipinlẹ Ondo
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ologun oju ofurufu ti sọ pe awọn yoo ṣe eto isin idagbere fun gbogbo awọn to ku ninu ijamba ọkọ ofurufu ẹlicoputa to jaboọ niluu Igbokoda, ipinlẹ Ondo.

Ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa ni ọkọ baalu tii ṣe ẹlicọputa jabọ sinu odo kan niluu Igbokoda, to si pa gbogob awọn to wa ninu rẹ.

Ileeṣẹ ologun NAF sọ pe o di dandan lati ṣẹyẹ ikẹyin fun gbogbo awọn to padanu wọn ninu ọkọ baalu NAF 931, ati pe ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla ni eto naa yoo waye.

Atẹjade ti Ehimen Ejodame to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ ologun oju ofurufu fi sita jẹ ko di mimọ pe itẹku awọn ologun apapọ to wa niluu Abuja ni eto isin idagbere naa yoo ti waye.

NAF sọ pe gbogbo mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn, awọn ọrẹ, alabaṣiṣẹpọ, to fi mọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ologun ni wọn yoo pe papọ lati wa nibi bibu ọla ati ẹyẹ ikẹyin fun iṣẹ isin ilu ti wọn ṣe.

NAF ṣàwárí àwọn ẹ̀ya ara bàálù tí wọ́n ń wá

Ileeṣẹ ologun NAF sọ pe awọn ti ri ẹya ara baalu naa to ṣe pataki, eyi ti wọn pe ni Cockpit Voice Recorder (CVR), pẹlu awọn nnkan miran to jẹ gẹgẹ bi ẹri lati mọ ohun to ṣokunfa ijamba ọjọ karun, oṣu Kẹwaa.

Ejodame je ko di mimọ pe awọn nnkan ti wọn ṣawari rẹ yii, yoo ran iṣẹ iwadii wọn to n lọ lọwọ, lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ.

O ni awọn alakoso eto iṣẹ iwadii ti ri ọpọlọpọ ẹya ara eeyan ati awọn ẹya ara baalu to ja naa, nigba ti idanimọ awọn ẹya ara ti wọn ri ṣi n lọ lọwọ.

Agbẹnusọ naa sọrọ lori iṣoro ati ipenija ti wọn koju lasiko iṣẹ lati wa ibi ti baalu naa wọlẹ si ninu odo ira niluu Igbokoda.

Ìdàgbàsókè dé bá iṣẹ́ ìwádìí

O fi kun ọrọ rẹ pe itẹsiwaju n de ba iṣẹ iwadii awọn, nipa ajọṣepọ to dan mọnran pẹlu ileeṣẹ Nigerian Safety Investigation Bureau (NSIB) ati Nigerian Civil Aviation Authority (NCAA).

Ejodame tun sọ siwaju pe awọn ṣi n ba awọn ileeṣẹ tọrọ naa kan sọrọ lori ohun to nii ṣe pẹlu ọrọ agbegbe, nipa awọn ohun to n jẹyọ lasiko iṣẹ awari ti wọn n ṣe.

O ni awọn ni lati rii daju pe ohun gbogbo ni wọn ṣe, lati rii pe iṣẹlẹ naa ko ṣe akọba fun awọn eeyan, lẹyin iṣẹ iwadii awọn.

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni Ọba ilu Igbokoda pariwo sita nipa oorun buruku to n jade lati inu omi wọn, to sig ba inu afẹfẹ kan, lẹyin ijamba naa.

Ọba naa sọ pe oorun yii le ṣe akoba fun ilera agbegbe ijamba naa, ati gbogbo ilu to wa nitosi rẹ, to si tun le ko iṣoro ba eto ọrọ aje wọn.