"Ìṣọ́ òru ní ṣọ́ọ́sì àti mọ́ṣáláṣí dópin, ìsìn kò gbọdọ̀ ju wákàtí méjì lọ, káwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ní ìgbéríkò sì kó wá sáàrin ìlú torí ìkọlù agbébọn"

Akọle sọọsi ti agbebọn kọlu ati awọn ọlọpaa to wa nibẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Alaga ìjọba ibilẹ Ekiti ni ipinlẹ Kwara Honourable Awẹlẹwa Gabriel ti kede fifofin de isin isọ oru ni ijọba ibilẹ naa.

Bakan náà lo tun kede pe, ki wọn ko gbogbo ile ijọsin ati Ori Oke to ba wa lẹyin ilu wọ inu ilu.

Alaga ìjọba ibilẹ Ekiti pasẹ naa lanaa ọjọ Aiku ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu yii lasiko to sabẹwo si ilu Ikẹrin Ọpin ni ibi ti akọlu ti waye.

Bẹẹ ba gbagbe, saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe eeyan mẹta ni awọn agbebọn naa pa, ti wọn si ji eeyan mẹẹdogun gbe salọ lasiko ti wọn ya wọ sọọsi kan ti wọn ti n se isọ oru.

Ori Oke Ijọ Ajaye ati Igbala, l'Abule Ẹkẹrin, nijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ Kwara, ni isẹlẹ naa ti waye lọjọ Satide, ọjọ kẹtalelogun oṣu Karun-un ọdun 2026.

Awọn ọlọpaa wa nibi ti ikọlu agbebọn ti waye

"Adari ile ijọsin ti ko ba tẹle aṣẹ yii, awọn ni yoo ni ẹbi eyikeyi ikọlu agbebọn to ba waye"

Ninu ọrọ rẹ sawọn eeyan agbegbe yii, Alaga ijọba ibilẹ Ekiti ni ki gbogbo ile ijọsin ni eto aabo to duro re, pẹlu alaye pe ki ijọsin awọn ile ijọsin mase ju wakati meji lọ.

Awelewa ni ijọba ibilẹ naa ti fofinde isọ oru ati eyikeyi apejọ ẹṣin lalẹ yala ti ọmọlẹyìn Kristi tabi ti Musulumi.

O rọ awọn adari ijọ ẹlẹsin ni ijọba ibilẹ naa lati tẹle aṣẹ ti ijọba pa yii.

Lasiko to n ba ikọroyin BBC News Yorùbá sọrọ nipa iṣẹlẹ naa, Awelewa ni awọn ọlọdẹ ati awọn osisẹ aabo to ku, ti wọ inu igbo lọ lati doola awọn ti wọn ji gbe.

Alaga naa ni awọn adari ile ijọsin ti ko ba tẹle aṣẹ yii , awọn ni yio ni ẹbi eyikeyi ikọlu agbebọn to ba waye.

Alaga ni ijọba ibilẹ naa yoo fọwọsowọpọ pẹlu ijọba ipinlẹ Kwara ati awọn ajọ eleto aabo lati dola awọn ti wọn ji gbe.

Awelewa wa bawọn mọlẹbi ti wọn padanu eeyan wọn ninu ikọlu agbebọn naa kẹdun.

Inu ile ijọsin ti agbebọn kọlu kun fun ẹjẹ, ti awọn ẹni ti wọn tẹ silẹ si wa kaakiri

"Inu ibẹrubojo lawọn eeyan agbegbe naa wa, awọn ọdẹ ati awọn ẹṣọ alaabo ti wa ninu Igbo lati doola awọn eeyan ti wọn ji gbe naa"

Ọkan lara awọn olujọsin ti ọrọ naa soju ẹ, Abiodun Sunday to ba aṣoju ikọroyin wa sọrọ lori iṣẹlẹ naa sọ pe, isẹlẹ ọhun ba ni lọkàn jẹ pupọ.

O fikun pe, inu isọ oru lawọn wa ni Ori Oke Ajaye ni ilu Ikẹrin Ọpin lasiko tawọn agbebọn kọlu awọn.

O salaye pe, lojiji ni wọn da ibọn bolẹ ti isọ oru si daru, lọrọ ba di boo lọ, ko yago fun mi.

Pẹlu alaye pe, eeyan mẹta ni wọn pa loju ẹsẹ ti wọn si ji eeyan mẹẹdogun gbe lọ.

O fikunpe pe Inu ibẹrubojo lawọn eyan agbegbe naa wa.

Abiọdun sọ pe awọn ọdẹ ati awọn ẹṣọ alaabo ti wa ninu Igbo lati ana lati doola awọn eeyan ti wọn ji gbe naa.

Ọgba ile ijọsin ti agbebọn kọlu ati ami itọka si ile ijọsin naa

Ki ni ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ naa?

Ninu ọrọ rẹ, Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Kwara Adekimi Ojo sọ pe, awọn ti fi awọn ikọ eleto abo to n gbogun ti iṣẹlẹ ijinigbe sọwọ si ilu naa.

O salaye pe, alẹ ọjọ Satide ni iṣẹlẹ naa waye ni nnkan bi ago mẹwa alẹ, Oníwàásù ijọ naa Pastor Adebayọ Abiọdun lo fi iṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti.

Pẹlu alaye pe, loju ẹsẹ ti wọn fi iṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti ni awọn agbofinro ti lọ si agbegbe naa.

Pẹlu afikun pe ibi ti Ori Oke naa wa jina si inu ilu tosi fa idiwọ fawọn ikọ eleto aabo lati ṣiṣẹ idọla.

Lọjọ Satide to kọja yii lawọn agbesunmọmi yawọ Ori Oke Ajaye ni ilu Ikẹrin Ọpin, Ijọba ibilẹ Ekiti ipinlẹ Kwara ni ibi ti wọn ti pa eeyan mẹta ti wọn si ji eyan mẹdogun gbe lasiko ti wọn nṣe isọ oru.

Agbébọn tún yabo Orí Òkè ìṣọ́ òru ní Kwara, jí èèyàn 15 gbé, pa mẹ́ta

Agbebon kan gbe ibon dani, o bo oju rẹ, ikeji naa wa lẹgbẹẹ rẹ pẹlu oju ati ori re to wé

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe bi iroyin ijinigbe to sọ awọn olukọ ati ọpọ akẹkọọ di ẹni igbekun niluu Ogbomoso, nipinlẹ Oyo ṣe n lọ lọwọ, awọn agbebọn tun ti yabo ibudo isọji nipinlẹ Kwara.

Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, SP Adetoun Ejire-Adeyemi to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣe wi, eeyan mẹẹẹdogun ni wọn ji gbe lọ, wọn si yinbọn pa eeyan mẹta.

Nibo ati nigba wo leyi ṣẹlẹ?

Ninu atẹjade ti Alukoro ọlọpaa Kwara fi ṣalaye ohun to ṣẹlẹ, eyi yo fi lede lọjọ Aiku oni lo ti ni :

"Ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Pasitọ Adebayo Abiodun, lo mu ifisun wa lọjọ kẹrinlelogun oṣu Karun-un ọdun 2026, pe awọn ajinigbe yabo ori Oke Ijo Ajaye ati Igbala, l'Abule Ẹkẹrin, nijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ Kwara, lọjọ Satide, ọjọ kẹtalelogun oṣu Karun-un ọdun 2026.

"Pasitọ Adebayo ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ, lasiko ti eto iṣọ oru naa n bẹrẹ ni awọn janduku kan yade ti wọn si ṣina ibọn bolẹ.

"Lasiko ti wọn n yinbọn naa ni wọn pa eeyan mẹta ti wọn si gbe mẹẹẹgogun lọ."

DSP Adetoun sọ pe bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe gbọ nipa ifisun naa ni ikọ ọlọpaa ti gbera lọ sibẹ, ti kọmiṣanna ọlọpaa Kwara, Adekimi Ojo, si ran ikọ ọtẹlẹmuyẹ lọ pẹlu.

Alukoro ọlọpaa ṣapejuwe ikọlu yii bii ohun to buru jai ti ko si ṣe e gba mọra rara.

O fi da ẹbi awọn eeyan ti wọn gbe lọ atawọn ti eeyan wọn di oloogbe loju, pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo mu awọn to wa nidii iṣẹ ibi naa.

Bakan naa lo rọ araalu lati ṣe suuru, ki wọn si foju ṣọri.

O ni ki wọn maa ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo kia bi wọn ba ri nnkan ifura.

SP Adetoun fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa Kwara yoo maa fi to araalu leti bi ohun gbogbo ba ṣe n lọ.