Olubadan rọ Mọ́gàjí mọ́kànlá lóyè n'Ibadan, ó ní kùdìẹ̀-kudiẹ wà nínú ìyànsípò wọn

Oríṣun àwòrán, Olubadan Palace
Olubadan ilẹ Ibadan, Oba Rashidi Ladoja, ti rọ awọn mọgaji mọkanla loye, titi kan Amofin Niyi Ajani Aborisade to jẹ Mogaji ile Ajagba, Oke-Offa, lagbegbe Babasale, Ibadan.
Igbimọ Oludamọran fun Olubadan lo sọ eyi di mimọ ninu lẹta kan ti wọn fi ṣọwọ si Aarẹ ẹgbẹ awọn Mogaji ilẹ Ibadan, ti Akọwe wọn, Balogun A.K, buwọlu.
Ki ni lẹta naa wi?
Gẹgẹ bi lẹta naa ṣe wi, Mọgaji mọkanla ni rirọloye naa kan.
Bi won ṣe yọ wọn nipo naa si waye lẹyin iwadii ti wọn lo fi han pe kudiẹ-kudiẹ wa ninu bi wọn ṣe fi wọn jẹ mọgaji.
Igbimọ naa sọ pe bi awọn mọgaji naa ṣe depo n'Ibadan ko tọna.
Wọn fi kun un pe awon panupọ lati gba iwadii yii wọle lẹyin ipade awọn igbimọ ẹka mi-in to waye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹwaa ọdun 2026.
"Awọn ti ọrọ yii kan ko gbọdọ pe ara wọn ni mọgaji mọ"
Aṣẹ to tẹle ikede yii ni pe awọn mọgaji mọkanla ti ọrọ yii kan gbọdọ dẹkun ati maa pe ara wọn ni mọgaji.
Wọn ni ki wọn ko gbogbo ilẹkẹ ati ohun gbogbo to ba n tọka won bii oloye kalẹ.
Wọn ko gbọdọ pe ara wọn ni aṣoju ile ti wọn ti fi wọn jẹ mọgaji mọ lode eto iṣẹmbaye, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ pe ara wọn ni mọgaji mọ nita gbangba.
Igbimọ naa fi kun ikilọ rẹ, pe ẹnikẹni to ba tapa sofin yii lara awọn mọgaji ti Olubadan rọ loye yoo foju wina ofin.
Amọ o, wọn ni ipo awọn meji ninu awọn mọgaji yii wa lọwọ idajọ kootu, lati sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ nipa iyọnipo wọn.
Awọn wo ni mọgaji ti wọn rọ loye naa?
Diẹ lara awọn eeyan naa ti iroyin fi orukọ wọn lede ni:
Amofin Niyi Ajani Aborisade
Ishola Ganiyu Olagoke
Ismaila Kunle Shodeinde
Funmilayo Adekunle Oluseyi
Muritala Suara Adeagbo
Yekini Musiliu Olaoye
Akinyemi Samuel Olusegun ati bẹẹ bẹẹ lọ























