Láti igba ti Omo Agege ti pàdánù tikẹẹti lo ti n fa wàhálà káàkiri- Jaro, alaga Ariwa Ughelli

Oríṣun àwòrán, Others
Ninu fọnran fidio to gba ori ayelujara kan ni ọrọ miran tun ti n ba ọrọ bọ lori ikọlu laarin Ọmọ Agege ati awọn miran ni Ughelli nipinlẹ Delta.
Alaga ijọba ibile Ariwa Ughelli nipinle Delta, Egbo Jaro lo sọrọ ninu fọnran fidio naa to gba igboro kan bayii eyi ti BBC gbọ lati oju opo 'X' ti Ossai Success Ovie to jẹ agbenusọ Gomina Sheriff Oborevwori to n tukọ ipinlẹ Dleta.
Ninu fidio naa ni Jaro ti fẹsun kan Omo Agege pe niṣe lo n fa wahala kiri to si n gbẹmi awọn eeyan lati igba to ti padanu tikẹẹti APC.
O ni pe Omo Agege lo paṣẹ fawọn ọmọleyin rẹ bii Efemena Umukoro atawọn imii lati ṣina ibọn bolẹ.
Jaro tun ṣalaye ninu fidio naa pe awọn alatileyin Omo Agege lo yinbọn si Aarẹ agbegbe naa, Cosmos Ejoke ni eyi to pada da wahala silẹ ni agbegbe naa.
Egbo tun ṣalaye pe lẹyin naa ni gbogbo nkan daru pẹlu Umukoro.
O tun sọ pe awọn mẹta miran doloogbe lagbegbe Uduere ko to di pe Umukoro pada jẹ Olorun nipe loru moju naa.

Oríṣun àwòrán, OSSAI OVIE SUCCESS @ossaiovie
Kini Egbo fẹ ki Ileeṣẹ Ọlọpaa Naijiria ṣe?
Egbo Jaro sọ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria bẹrẹ iwadii to yẹ lori iṣẹlẹ naa.
Ati pe O ya oun lẹnu pe Omo Agege ṣi n sọrọ lori amohunwaworan lori ọrọ: 'Rigg and Die' ẹ yi ibo ki ẹ doku.
O ni pe wọn ti pa Aarẹ oun ati awọn mẹta miran.

Oríṣun àwòrán, Others
Èèyàn mẹ́fà kú, ọ̀pọ̀ farapa níbi ìpolongo ìbò Omo-Agege
Ijọba ipinlẹ Delta ti kede isede kaakiri ijọba ibilẹ Ughelli, lẹyin ti rogbodiyan oṣelu mu ẹmi eeyan mẹfa lọ lọjọ Aje.
Aago mẹfa irọlẹ si mẹfa idaji ni isede naa yoo fi maa waye.
Nibi ipolongo ibo fun Sẹnetọ Ovie Omo-Agege n'ilu Uduere, ni ija oṣelu ti bẹ silẹ. Omo-Agege ni Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo aarin gbungbun ipinlẹ Delta.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe iwadii ti awọn kọkọ ṣe, fihan pe eeyan mẹfa lo ku, ti ọpọlọpọ si farapa.
Omo-Agege n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC) for di fun idibo ọdun 2027.
Kini Omo Agege sọ?
Ninu ọrọ to ba ileeṣẹ iroyin Channels sọ, Omo-Agege sọ pe ọpẹlọpẹ awọn oṣiṣẹ alaabo DSS to wa pẹlu oun, ni ori fi ko oun yọ ninu ikọlu naa.
"Orukọ mi la gbọ ti awọn janduku naa n pariwo bi wọn ṣe de, ti wọn si n sọ pe, Omo-Agege la fẹ ẹ pa. A gbọdọ pa Omo-Agege."
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii nipa iṣẹlẹ naa, ati lori bi ọwọ yoo ṣe tẹ àwọn to wa nidii rẹ.
Bo ti lẹ jẹ pe àwọn ọlọpaa ko ti i sọ nkankan nipa awọn to wa nidi ikọlu naa, ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC), fi ẹsun kan pe, ẹgbẹ alatako, APC, lo wa nidi ikọlu ọhun.
Akọwe ikede fun ẹgbẹ oṣelu NDC, Osa Director, sọ ninu atẹjade to fi sita lori iṣẹlẹ naa sọ pe, "ọna lati pa ẹgbẹ oṣelu alatako lẹnu mọ, ati lati dẹru ba awọn ọmọ ẹgbẹ naa ki wọn le jawọ ninu eto idibo, ni."
























