Wọ́n pe pásítọ̀ kó wá ṣe ìṣọ́ òru ní ṣọ́ọ̀ṣì ni káwọn agbébọ̀n tó yìnbọn paá – Aráàlú sọ̀rọ̀ lórí ìkọlú àwọn agbébọn sí ṣọ́ọ̀ṣì kan l'Ekiti

Àkọlé fídíò, Wọ́n pe pásítọ̀ kó wá ṣe ìṣọ́ òru ní ṣọ́ọ̀ṣì ni káwọn agbébọ̀n tó yìnbọn paá – Aráàlú sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù sí ṣọ́ọ̀ṣì kan l’Ekiti
Wọ́n pe pásítọ̀ kó wá ṣe ìṣọ́ òru ní ṣọ́ọ̀ṣì ni káwọn agbébọ̀n tó yìnbọn paá – Aráàlú sọ̀rọ̀ lórí ìkọlú àwọn agbébọn sí ṣọ́ọ̀ṣì kan l'Ekiti

Ọrọ di boolọ yago fun mi nilu Ẹda Oniyọ ni ipinlẹ Ekiti ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹrin nigba ti awọn agbebọn kan ya wọ ijọ kan nibẹ lasiko ti wọn n ṣe iṣọ oru.

Iroyin sọ wi pe awọn agbebọn naa pa pasitọ ijọ naa wọn si tun ko ọpọ awọn olujọsin lọ sinu igbekun.

"Ṣadede la gburo ibọn lai mọ ibi to ti n dun wa...wọn yinbọn fun pasitọ to wa ṣe iṣọ oru naa, igba ti wọn du u titi ni pasitọ naa ṣa gbẹmi mi ki wọn to de ile iwosan."

Awọn olugbe ilu Ẹda Oniyọ bii arabinrin Musa Modupẹ, to tun ba BBC News Yoruba sọrọ tun rawọ ẹbẹ si ijọba lati gbe igbesẹ to loorin nipa eto abo lagbegbe naa.

O ṣalaye siwaju sii pe 'Lana a o le lọ si ibi kankan, inu igbo la sun, wahala ti pọ, ki Ọlọrun ṣaanu wa".

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Awọn agbebọn kan ya wọ ile ijọsin CAC Eda Oniyo Ekiti lasiko ti wọn n ṣe iṣọ oru lọwọ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe ṣadeede lawọn agbebọn naa ṣina ibọn bolẹ, ti wọn si ṣekupa pasitọ ijọ naa, ki wọn to ji awọn ọmọ ijọ kan gbe lọ.

awọn agbebọn kan ya wọ ile ijọsin CAC Eda Oniyo Ekiti lasiko ti wọn n ṣe iṣọ oru lọwọ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe ṣadeede lawọn agbebọn naa ṣina ibọn bolẹ, ti wọn si ṣekupa pasitọ ijọ naa, ki wọn to ji awọn ọmọ ijọ kan gbe lọ.

CP Micahael sọ pe ajọ ọlọpaa gbọdọ fọwọ ofin mawọn janduku agbebọn to ṣiṣẹ laabi naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni nnkan bii ago mẹwaa abọ alẹ ana ọjọ Iṣẹgun tii ṣe ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹrin yii ni awọn agbebọn marun un ṣadeede ya wọ ṣọọṣi naa.

O ni isẹlẹ naa waye lasiko ti wọn n ṣe iṣọ oru lọwọ, ti wọn si yinbọn pa alufaa ijọ naa.