Ìjọba Plateau gbé gbogbo ilé ẹ̀kọ́ tì pa nítorí àrùn Diphtheria tó búrẹ́kẹ níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Plateau ti paṣẹ ki wọn gbe awọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama ti pa fun akoko diẹ lọna ti dena arun diphtheria to burẹkẹ kaakiri ipinlẹ naa.
Gomina Caleb Mutfwang lo paṣẹ bẹẹ ninu atẹjade kan nibi to ti kede pe awọn agbegbe bii ariwa Jos, Wase, guusu Jos ati Bassa ni arun naa ti milẹ titi julọ.
Igbesẹ titi awọn ile ẹkọ yii yoo gberasọ bẹrẹ lati ọjọ Aje, ọjọ Keje, oṣu Kẹsan an, ọdun 2026 ti a wa yii, aṣẹ naa si kan gbogbo awọn ile ẹkọ ti wọn ti pada wọle fun saa ẹkọ tuntun atawọn ti ko tii bẹrẹ.
Ninu atẹjade naa ti Joyce Ramnap, to jẹ kọmiṣọna fun ọrọ to n lọ buwọlu, o ni titi pa fun akoko diẹ yii wa fun idaabobo awọn akẹkọọ atawọn olukọ, to fi mọ awọn oṣiṣẹ mii lawọn ile ẹkọ ọhun.
O wa rọ gbogbo awọn adari ile ẹkọ, to fi mọ awọn oludasilẹ ile ẹkọ lati tẹlẹ aṣẹ naa lai yẹsẹ.
Gomina tun bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ awọn obi atawọn eeyan mii ti ọrọ eto kan nipinlẹ ọhun.
O ni ijọba yoo maa kede asiko ti awọn ile ẹkọ naa yo pada di ṣiṣi laipẹ.
Kí ni Diphtheria?
Aarun ti oloyinbo n pe ni Diphtheria jẹ aarun kan to maa n tete ràn gidi.
Kokoro aifojuri ti a mọ si Bacteria lo maa n fa a. O si maa n kọlu imu ati ọna ọfun, yoo gba ibẹ wọnu itọ ẹnu, ikọ ti eeyan ba n hu ati bi eeyan ba n sín.
Bakan naa lo tun le kọlu eeyan ti ẹni naa ba fọwọ kan nnkan ti kokoro to n bi Diphtheria ba ti wa lara rẹ, paapaa nibi ti ero ba ti pọju, tabi ti atẹgun gidi ko ti fẹ wọle.
Ni 2023, aarun Diphtheria bẹ silẹ ni Naijiria, eeyan to ku lati ara ikọlu naa si le ni ẹgbẹta (600), ọmọde lo pọ ju ninu awọn to di oloogbe naa.
Ipinlẹ mọkandinlogun ni ikọlu naa ba ninu mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria, apa Ariwa ni pupọ ninu wọn si wa.
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post
Nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Diphtheria
Aarun Diphtheria jẹ oriṣi kokoro aifojuri 'bacteria' to ma n kọlu eroja (mucous membranes) to n daabo bo imú ati ọ̀fun.
Lootọ ni oogun oyinbo maa n wo diphtheria, ṣugbọn to ba ti pọ ju ninu ara, o le ba ọkàn, kindinrin ati ọpọlọ jẹ.
Koda pẹlu itọju, aarun naa ṣi le pa eeyan, paapaa awọn ọmọde.
Awọn ami ti Diphtheria maa n fi han ninu ara:
- Laarin ọjọ meji si marun-un ni aarun Diphtheria maa n farahan to ba ti wọ ara.
- Lara awọn ami naa si ni:
- Egbo ni ọna ọfun
- Ọrun yoo wú
- Idiwọ si eemi tabi ki eeyan o maa mi lakọ-lakọ
- Ikun imu yoo ma jade lai dawọ duro
- Ara gbigbona ati otutu
- Aarẹ yoo mu ara
- Kẹlẹbẹ to ni awọ eeru yoo bo ọfun
Bakan naa lo ṣee ṣe ki ẹni to ni Diphtheria ma ri ami kankan – iru awọn eeyan bayii lo maa n ṣaba pin aarun naa kiri, lai ṣe pe awọn funra wọn dubulẹ aisan.
Ki lo n fa Diphtheria?
Oriṣi kokoro aifojuri 'Corynebacterium Diphtheria' lo n fa a . Kokoro aifojuri naa yoo maa pọ si ni ọna ọfun tabi ni awọ ara.
Ti ẹni to ni aarun Diphtheria ba sín tabi hu ikọ sinu afẹfẹ, ẹni to ba sunmọ ọn tabi kọja lasiko naa le fa Diphtheria si imu.
Ọna kan pataki ti Diphtheria fi maa n di ajakalẹ ree, paapaa ni ayika ti ero ba pọ si.
Eeyan tun le ko aarun yii to ba fi ọwọ kan awọn ohun elo bi aṣọ inuwọ ati awọn nnkan mi-in ti ẹni to ni aarun Diphtheria ti lo, nitori pe o ṣee ṣe ki aarun naa ti sa pamọ si wọn lara.
Yatọ si ọna ọfun, Diphtheria tun le farahan ni awọ ara.
Iru eyi ma n fa irora ninu ara, ara wiwu ati ara pipọn.
Bo tilẹ jẹ pe ko wọpọ niru agbegbe bii Naijiria, o le ṣẹlẹ laarin awọn eeyan ti imọtoto wọn ko ba dara to, tabi awọn to n gbe ni ibi ti ero ti pọ ju bo ṣe yẹ lọ.
























