Ṣé òótọ́ ni pé INEC ti mọ ẹni tí yóò jáwé olúborí kí ètò ìdìbò tó wáyé?
Ọpọ eeyan lo maa n sọ pe ajọ eleto idibo ni Naijiria, INEC, lo maa n ṣe makaruru lasiko eto idibo.
Koda, awọn mii tun maa n sọ pe ajọ naa ti maa n mọ ẹni ti yoo jawe olubori lọjọ ibo ki eto idibo naa to waye, atawọn nnkan mii to jọ bẹẹ, amọ ṣe ootọ ni?
Eniola Oladapo, to ṣoju ajọ INEC sọ fun BBC Yoruba niluu Abuja pe irọ gbu ni gbogbo awọn ọrọ naa ati pe ahesọ ọrọ lasan ni.
O ni INEC kii yii esi ibo paa bẹe ni ajọ naa kii mọ ẹni ti yoo jawe olubori ṣaaju ọjọ idibo.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn to maa n sọ irufẹ ọrọ bẹẹ n mọọmọ sọ ki awọn eeyan ma ba a jade lati dibo ni, ati pe awọn araalu gan funra ni yoo sọ ẹni ti yoo wọle nipa ibo wọn.
Ọgbẹni Oladapo tun mẹnuba awọn nnkan ti INEC ko lagbara labẹ ofin lati ṣe lọjọ ibo.
Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti aṣoju INEC ba wa sọ.






