Ṣé òótọ́ ni pé àwọn Kristẹni nìkan làwọn jàndùkú agbébọn ń kọlù ní Naijiria?

Àkọlé fídíò, Ṣé òótọ́ ni pé àwọn Kristẹni nìkan làwọn jàndùkú agbébọn ń kọlù ní Naijiria?
Ṣé òótọ́ ni pé àwọn Kristẹni nìkan làwọn jàndùkú agbébọn ń kọlù ní Naijiria?
Published

Lọdun 2010, ọpọ awọn Kristẹni lo ku ninu ikọlu awọn agbebọn si abule Dogo Nahawa nipinlẹ Plateau.

Ọpọlọpọ ọdun lẹyin ikọlu naa, ogunlọgọ ẹmi ọmọ Naijiria lo ti sọnu sinu oniruru ikọlu bẹẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba Naijiria n gbiyanju lati koju irufẹ ikọlu ọhun, ikọlu awọn agbebọn ti di lemọlemọ ni Naijria.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe ọrọ ala ilẹ lo n fa awọn ikọlu naa, lawọn mii n sọ pe ede aiyede laarin awọn agbẹ atawọn Fulani darandaran lasan ni.

Bẹẹ lawọn mii tun n sọ pe ija ẹsin ni, eyii ti awọn Fulani darandaran fi n kọlu awọn Kritẹni ti wọn jẹ agbẹ.

Eredi ree ti ikọ Africa Eye ileeṣẹ iroyin BBC ṣe kan si awọn Fulani darandaran naa ti pupọ wọn jẹ Musulumi.

Awọn eeyan ti wọn gbọ iwaasu ninu ṣọọṣi

Awọn Fulani ọhun sọ pe awọn kii ṣe ọdaran, amọ niṣẹ lawọn eeyan n mọọmọ n so awọn mọ awọn ọdaran naa lati ba orukọ ẹya awọn jẹ.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, kii ṣe awọn Kristẹni nikan lawọn agbebọn n kọlu, wọn ni bi wọn ṣe n kọlu awọn Kristẹni ni wọn n kọlu awọn naa pẹlu.

Wayi o, bo tilẹ jẹ pe awọn aṣofin ilẹ Amẹrika ti fẹsun kan awọn Fulani kan pe wọn n gbogun ti awọn Kristẹni ni Naijiria, ijọba apapọ ti ni ko si ohun to jọ bẹẹ.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ iwadii BBC Africa Eye.