Ìfẹ́ tí Ajá mi fi hàn sí mi, ló gba ẹ̀mí mi là lásìkò tí mo fẹ́ pa ara mi - Oreoluwa Osoba

Àkọlé fídíò, Ìfẹ́ tí Ajá mi fi hàn sí mi, ló gba ẹ̀mí mi là lásìkò tí mo fẹ́ pa ara mi - Oreoluwa Osoba
Ìfẹ́ tí Ajá mi fi hàn sí mi, ló gba ẹ̀mí mi là lásìkò tí mo fẹ́ pa ara mi - Oreoluwa Osoba
Published

Yoruba ni ẹni to ba ku ni ku, ni eeyan maa n ba jaye, wọn a tun ni ise eniyan ni ise ẹranko.

Bakan naa ni Yoruba maa n ni aja kii gbagbe oloore ẹkọ.

Eyi si lo n safihan igbe aye irẹpọ to maa n wa laarin awọn eeyan ati ẹranko, paapaa aja to jẹ ẹran ọsin ninu ile.

Lọpọ igba si lawọn ẹranko naa maa n daabo bo olowo wọn, paapaa aja.

Irufẹ isẹlẹ lo waye ninu igbe aye ọkunrin kan, Oreoluwa Osoba, to fẹ ronu pa ara rẹ, amọ aja to n sin, Duke, lasan lo doola ẹmi rẹ.

Ileesẹ BBC kan si ọkunrin naa lati mọ ipa ti aja yii ko, to fi gba a lọwọ iku ojiji.

Oreoluwa Osoba jokoo, o wọ asọ tshirt funfun, o kọ oju fila oloyinbo to de si ẹyin, o gbe aja kekere kan lọwọ

"Mo bẹrẹ ironu, ti a mọ si Depression, nigba ti aburo baba mi ku, inu mi ko dun, n ko le jẹun, o kan n se mi bakan-bakan ni"

Nigba to n ba BBC sọrọ Oreoluwa Osoba, to wa lati ipinlẹ Ogun, to si se aseye ninu imọ ẹrọ ayarabiasa kọmputa pẹlu isọri kinni, First class ni ifẹ aja oun lo gba oun silẹ lasiko ti oun fẹ pa ara oun.

"Ni orilẹede Naijiria, wọn maa n sọ pe ọkunrin ko le sunkun sita, tori akọ igi kii se oje, o le saroye, to si ni lati gbe nnkan to ba n se ẹ si ara.

Mo bẹrẹ ironu, ti a mọ si Depression, nigba ti aburo baba mi ku, inu mi ko dun, n ko le jẹun, o kan n se mi bakan-bakan ni.

Nkan ti aja mi se fun mi, n ko tiẹ le sọ tan, o jẹ ki n mọ pe ifẹ orisirisi lo wa, ati pe ifẹ otitọ ni Duke fi han mi.

Ko fẹ nkankan lati ọdọ mi, o kan nifẹ mi lasan ni.

Ọjọ tiẹ wa, ti gbogbo rẹ ti su mi, mo fẹ pa ara mi, ijọ yẹn, Duke lo gba mi la.

O jẹ ko ye mi pe Duke ni oye nipa mi ati pe aja maa n mọ ohun to fẹ sẹlẹ.

Wọn le maa wo eeyan, wọn a mọ pe nnkan fẹ sẹlẹ, lati ọjọ yẹn ni ifẹ emi ati aja mi ti pọ si."

Oreoluwa Osoba ati aja rẹ joko sori ibusun kan, wọn n fi ẹnu ko ara wọn lẹnu

Oreoluwa Osoba wa salaye bo se pade aja rẹ naa, ti wọn si di ọrẹ korikosun lati igba naa lọ.

"Ni ọjọ kan, mo wa ninu yara mi, mo wa ranti pe aburo baba mi to ku nifẹ aja gan ni.

Mo wa ro pe ti emi naa ba ni aja, maa fi sunmọ aburo baba mi to ku ni.

Nigba ti aburo baba mi naa ku, n ko ri , ẹri ọkan si n da mi lẹbi, mo wa ro pe ti mo ba ra aja, yoo jẹ ki n sunmọ si ni.

Iru ifẹ yẹnti Duke fi han mi, o jẹ ki n mọ pe mo le bori isoro ironu, nnkan ti Duke se fun mi ree.

Ifẹ ti Duke fi han mi, lo fun mi ni agbara lati bori ironu yẹn."

Aja to wọ asọ funfun, sokoto penpe Jeans naro, Oreoluwa Osoba, ti oun naa wọ sokoto jeans alawọ buluu ati tshirt alawọ buluu, fi ọwọ mejeeji mu aja naa, wọn dijọ n woju ara wọn