Àṣírí Gbọ́mọgbọ́mọ méjì tó ń wọ Hijab láì ṣe Mùsùlùmí tú lásìkò tí wọn tún fẹ́ jí ọmọ míì gbé

Agbẹnusọ ọlọpaa Abuja, Josephine Adeh wọ igo oju o n wo ọọkan, o wọ aṣọ ọlọpaa Naijiria, obinrin to wọn hijaabu to kẹyin si ẹrọ ayaworan wa ni ẹgbẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, FCT POLICE/FACEBOOK

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa tẹka olu ilu Naijiria, Abuja ti fi pampẹ ofin mu awọn obinrin meji kan fẹsun pe wọn n ji awọn ọmọde gbe, wọn si n ta wọn.

Eyi lo n waye lẹyin ọjọ diẹ tawọn ẹṣọ aabo n kọminu lori bi ijinigbe awọn ọmọde ṣe n waye lemọlemọ lẹnu ọjọ mẹta yii ni ilu Abuja atawọn agbegbe mii ni Naijiria.

Ni ọdun 2025 ni wọn ti kọkọ nawọ gan awọn obinrin naa fun ẹsun pe wọn ji awọn ọmọde mẹrin gbe, iyẹn awon ọmọkunrin meji ati obinrin meji ṣugbọn ti wọn gba itusilẹ lẹyin oṣu mẹrin.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Abuja, Josephine Adeh ba BBC sọrọ lori iṣẹlẹ naa ati bi ọwọ ṣe tẹ awọn obinrin naa.

'Wọn maa n wọ hijaabu amọ wọn kii ṣe musulumi'

Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọwọ tẹ awọn obinrin meji kan ni ijọba ibilẹ Gwagwa ni ilu Abuja.

"Lasiko ti awọn obinrin naa n gbiyanju lati ji ọmọdebinrin kan, ọmọ ọdun mẹrin ti orukọ rẹ n jẹ Ummi gbe sabẹ hijaabu ni ọwọ tẹ wọn," Josephine sọ fun BBC.

Josephine ṣalaye pe niṣe ni awọn obinrin ti kii ṣe musulumi maa wọ hijaabu lati fi ji awọn ọmọde gbe ni ilu Abuja.

O ni ti awọn eeyan naa ba ti ri awọn ọmọde tawọn obi wọn ba ti ran niṣẹ ni wọn maa gbe wọn ti wọn si maa fi awọn ọmọ naa si abẹ hijaabu wọn ki awọn eeyan ma fi le dawọn mọ.

Awọn afurasi ti ọwọ ọlọpaa ṣẹṣẹ ban aa ni wọn pe ni Blessing John, to jẹ bibi ipinlẹ Benue ati Rose Daniel to jẹ ọmọ ipinlẹ Enugu.

"Kristẹni ni awọn mejeeji ṣugbọn gbogbo igba ni wọn maa n wọ hijaabu.

"Wọn maa n wọ hijaabu to tobi gidi gan ki wọn ba a le gba ọmọde lai si ẹni to maa mọ pe ọmọde wa labẹ hijaabu naa," Josephine fi kun.

'A ti fi wọn si ahamọ tẹlẹ ki a to tun ri wọn nita'

Agbẹnusọ ọlọpaa naa tun ṣalaye pe igba akọkọ kọ niyi ti awọn maa fi pampẹ ofin gbe awọn ọmọbinrin fun ẹsun jiji ọmọ gbe.

O ni ọdun 2025 ni ọwọ ofin ti kọkọ tẹ wọn fun ẹsun jiji ọmọ mẹrin gbe, ti awọn sig be wọn lọ sile ẹjọ nigba naa.

O fi kun lasiko ti wọn n gbiyanju lati ji ọmọ meji mii gbe lọwọ tẹ wọn nigba naa.

Josephine ni ilu Port Harcourt ni wọn ta awọn ti wọn kọkọ gbe si ni miliọnu kan abọ naira.

O tẹsiwaju pe lẹyin ti awọn gbe wọn lọ sile ejọ nigba naa, Adajọ to da ẹjọ naa sọ awọn ọmọbinrin mejeeji si ẹwọn ti wọn si ko wọn lọ si ọgba ẹwọn Kuje.

O ni iyalẹnu lo jẹ fun awọn pe awọn tun ri awọn ọmọbinrin naa nita, ti wọn si n tẹsiwaju pẹlu iṣẹ ibi wọn.

"Nigba ti a mu wọn yii, a beere pe ṣebi awọn ni ile ẹjọ ran lọ si ọgba ẹwọn kuje ti wọn si ni bẹẹ ni.

"Wọn oṣu mẹrin ni awọn lo ni ọgba ẹwọn naa ki wọn to tu awọn silẹ."