Ilé aṣojú-ṣòfin rí àpò àṣùwọ̀n owó 58 tó so mọ́ Adeniyi Adeyemi, bó ṣe wẹ Gbajabiamila mọ́ pé kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa ayédèru iléeṣẹ́ PFIPC

Oríṣun àwòrán, Collage
Igbimọ oluwadii ti ile igbimọ aṣofin-ṣofin nilu Abuja gbe kalẹ lori iwadii nipa ayederu ileeṣẹ Presidential Foreign Intervention Promotion Council (PFIPC) ti awọn kan da silẹ sọ pe awọn ti pari iṣẹ iwadii awọn.
Igbimọ naa sọ pe olori awọn oṣiṣẹ aarẹ, Femi Gbajabiamila ko mọ ohunkohun nipa idasilẹ awọn ayederu ileeṣẹ naa, eyi ti wọn ti fi ẹsun rẹ kan an.
Bakan naa ni wọn fidi rẹ mulẹ pe Gbajabiamila lo n ṣiṣẹ tako idasilẹ awọn ayederu ileeṣẹ yii, ti aṣiri rẹ fi tu sita fun gbogbo araye.
Wọn ni awọn ko ri ẹri aridaju kan wi pe olori awọn oṣiṣẹ aarẹ mọ nipa, buwọlu, tabi kopa ninu idasilẹ ayederu awọn ayederu ileeṣẹ naa.
Dipo bẹẹ, igbimọ naa sọ pe awọn ẹri ti wọn ri ninu iwadii wọn safihan wi pe Gbajabiamila lo gbe igbesẹ lati pariwo ayederu ileeṣẹ naa sita, fun iwadii lati bẹrẹ.
Igbimọ yii lo fidi awọn ẹri wọnyi mulẹ lasiko ti wọn n jabọ fun alaga wọn, Yusuf Gagdi, nibi ipade awọn akọroyin lori ohun ti wọn ba bọ lẹyin iwadii wọn.
Gẹgẹ bi wọn ṣe ṣalaye, wọn ni ileeṣẹ NIPC lo mu tọka si ileeṣẹ kan ti wọn fura si pe wọn fi n lu jibiti, fun olori awọn oṣiṣẹ aarẹ, to si paṣẹ pe ki wọn bẹrẹ iwadii nipa awọn to wa nidi rẹ loju ẹsẹ.
Wọn ni laaarin ọjọ kan ọṣo pere ni Gbajabiamila fi tete ta awọn ileeṣẹ eleto aabo ati ajọ oniṣẹ iwadii, to fi mọ ileeṣẹ ọlọpaa, NSA, DSS ati ECC lolobo.
Gbajabiamila tun gbe igbeṣẹ iwadii nipa awọn ileeṣẹ tọrọ naa kan lati ri aridaju, gẹgẹ bi awọn igbimọ naa ṣe ṣalaye.
"Awọn iwe ẹri ti a fidi rẹ mulẹ ko fidi mulẹ pe olori awọn oṣiṣẹ aarẹ paṣẹ, buwọ lu, ṣagbekalẹ tabi kopa ninu idasilẹ ayederu ileeṣẹ yii," igbimọ naa sọ.
"Awọn ẹri ṣafihan oniruuru igbesẹ lati fidi otitọ mulẹ, nipa ṣiṣẹ afihan awọn to lọwọ ninu iwa ibajẹ naa, ati igbesẹ to yẹ."
Igbimọ naa wa sọ pe awọn gbe oriyin fun Gbajabiamila lori bo ṣe tete gbe igbesẹ to yẹ lati pariwo ileeṣẹ naa sita, ni kete to ti gbọ.
Ayédèrú ìwé ìgbanisíṣẹ́
Igbimọ naa sọ siwaju pe iwadii awọn ṣakiyesi pe igbe igbanisiṣẹ ti Ọmọọba Adeniyi Adeyemi n lo gẹgẹ bii alakoso agba fun ayederu ileeṣẹ naa lo jẹ agbelẹrọ, to si fi lọ ileeṣẹ aarẹ lẹsẹ.
Ayederu iwe naa lo ni agbara ati ontẹ Gbajabiamila ninu.
Ju gbogbo rẹ lọ, igbimọ naa sọ pe awọn ẹri ti wọn ri gba lati ileeṣẹ aarẹ fidi mulẹ pe ko si ẹnikẹni lati ileeṣẹ aarẹ tabi olori awọn oṣiṣẹ aarẹ to lọwọ ninu bibu ọwọ lu iwe naa.
Igbimọ yii fi kun un pe iwe aṣẹ ti wọn lo, kii ṣe ojulowo ti ileeṣẹ aarẹ n lo, ati pe awọn ẹrọ ibanisọrọ to wa ninu rẹ ni ko ba ti eyi ti wọn n lo nileeṣẹ aarẹ mu.
W|on jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn iwe naa lo jẹ eyi ti wọn ṣe agbelẹrọ wọn, ti wọn si n purọ rẹ mọ ileeṣẹ aarẹ.
Wọn kò dá PFIPC sílẹ̀ lábẹ́ òfin
Igibmọ naa tun sọ siwaju pe awọn ko ri aṣẹ tabi agbara ofin ti ile igibmọ aṣofin agba, tabi agba aarẹ, tabi eyikeyi agbara ijọba to lọwọ ninu idasilẹ ayederu ileeṣẹ PFIPC naa ninu iwadii awọn.
Wọn ni ko si ojulowo ileeṣẹ ijọba apapọ to fi ẹri silẹ wi pe akọsilẹ wa ninu idasilẹ ayederu ileeṣẹ naa.
Wọn ni ọna ẹburu ni wọn n gba ṣe gbogbo iṣẹ ti wọn n ṣe kaakiri.
Irinwó mílíọ̀nù náírà
Igbimọ oluwadii yii sọ ọ di mimọ pe awọn gba esi lati ọdọ ileeṣẹ kan, nibi ti wọn ti sọ pe Adeyemi n beere fun miliọnu lọna irinwo naira, eyi ti wọn yoo san ni igba mẹrin ọtọọtọ.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, wọn ni ileeṣẹ naa san owo yii, lẹyin adehun wi pe wọn yoo gba iṣẹ akanṣe lọwọ ijọba, eyi to nii ṣe pẹlu atunṣe ile ti ijọba apapọ fun un gẹgẹ bii alakoso agba ileeṣẹ naa.
Igbimọ naa sọ pe awọn ti bẹrẹ itọpinpin lati mọ apo aṣuwọn ti owo naa wọle si, bo tilẹ jẹ pe awọn ti mọ orukọ ati ẹni to ni apo aṣuwọn naa, to fi mọ awọn to ni dukia yii.
Wọn wa jẹ mo di mimọ pe ẹsun naa lo n tọka si igbesẹ iwadii tuntun ti awọn n ṣe, ati pe ile-ẹjọ nikan lo le fidi rẹ mulẹ wi pe iwa ọdaran ni.
Àpò àṣùwọ̀n méjìdínlọ́gọ́ta
Nigba ti wọn n tẹsiwaju ninu abajade wọn, igbimọ yii sọ pe awọn ti ṣawari apo aṣuwọn ti ko din ni mejidinlọgọta ni wọn ti tọpinpin rẹ de ọdọ Adeyemi, leyi ti ọgbọn ninu rẹ ni wọn n lo lorukọ ileeṣẹ, ati ajọ mẹsan.
Wọn fẹsun kan Adeyemi wi pe yoo mọ nipa rẹ, pẹlu awọn mejila miran, bo tilẹ jẹ pe wọn ko tii le fidi rẹ mulẹ wi pe awọn owo ti wọn fi n ranṣẹ ba ofin mu.
Igbimọ naa sọ siwaju pe iwadii awọn ṣawari awọn kudiẹkudiẹ to wa lawọn ileeṣẹ ijọba nipa ninu ojulowo idanimọ nipa awọn aṣoju ijọba, ile ijọba, nọmba ọkọ ati fifi idanimọ pamọ.
Wọn jẹ ko di mimọ pe iwadii igbẹyin ni yoo ṣafihan gbogbo awọn to n fi orukọ ijọba lu jibiti , ti awọn yoo si sọ oniruuru ijiya to ba tọ si iru wọn.



























