'A ti ń ṣàwàrí ohun tó ń fa òórùn tó ń ṣàkóbá fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, a ma jẹ́ kí ará ìlú mọ́ láìpẹ́'

Oríṣun àwòrán, @ola Oresanya facebook
Ni ọsẹ to kọja ni oorun kan gbalẹ ni awọn agbegbe kan ni ipinlẹ Ogun paapaa ni ilu Ijebu Ode ati Ijebu Igbo eyi to mu kawọn akẹkọọ ni awọn ile ẹkọ kan.
Lara awọn ile ẹkọ ti oorun naa ti ṣakoba fawọn akẹkọọ ni Anglican girls Grammar School Ijebu Ode, Comprehensive High school, Ita merin, Ago Iwoye, ati Abusi Edumare girls grammar school, Ijebu Igbo.
Niṣe ni ọpọ awọn akẹkọọ lawọn ile ẹkọ yii n daku bi wọn ṣe n gbọ oorun naa, ti wọn si n dero ile iwosan.
Nigba ti BBC News Yoruba ṣabẹwo si agbegbe naa lati fidi ohun to n fa oorun naa mulẹ awọn araalu naa fidi rẹ mulẹ pe igba akọkọ kọ niyi ti oorun abaadi yii n waye lawọn agbegbe naa.
Ọgbẹni Adegbenro Adetayo, ẹni to jẹ ọkan lara awọn obi akẹkọọ ti oorun naa ṣakoba fun ọmọ rẹ ni ilu Ijebu Ode sọ fun BBC pe iwadii awọn fidi rẹ mule pe lati inu ilẹ ni oorun naa ti n wa.
Arabinrin Joseph Alice, ti oun naa jẹ obi ọmọ ile ẹkọ sọ pe igba keji re e lẹnu igba tawọn akẹkọọ wọle fun saa ẹkọ ti wọn wa yii ti oorun naa n ṣakoba fawọn ọmọ wọn.
O fi kun pe kii ṣe ile ẹkọ nikan ni oorun naa ti n waye, bo ṣe ni gbogbo agbegbe ilu naa ni wọn n gbọ oorun naa ati pe eyi to waye lọsẹ to kọja yii lo fẹ ẹ buru julọ lati igba ti oorun naa ti n waye.
O ṣalaye pe oorun naa gbalẹ lasiko isinmi awọn akẹkọọ to kọja lọ ti gbogbo eeyan to wa niluu naa si mọ nipa rẹ.
"Waya la kọkọ ro pe o n run, a o le sọ pe bayii ni oorun naa ni pato"
Nigba to n sọrọ, igbakeji giwa ile ẹkọ Our lady of Apostle Senior Ijebu Ode, Roseline-Kehinde Onasanya sọ pe inu oṣu Kẹrin ni oorun naa ti kọkọ fẹ tawọn oṣiṣẹ eto ayika ipinlẹ Ogun si ṣe abẹwo sibẹ.
O ni wọn ti ile ẹkọ naa fun ọsẹ mẹta gbako ki wọn to ṣi pada lasiko lẹyin tawọn alẹnulọrọ ṣepade, ti wọn si fenuko lati ṣi ile ẹkọ naa pada.
Roseline-Kehinde Onasanya fi kun pe awọn ko le sọ pe oorun naa n run bii nnkankan ni pato nitori waya to kan ara ni awọn kọkọ pe e.
O woye pe nnkan to n mu ki oorun naa maa gbodi lara awọn akẹkọọ ni pe wọn ṣi kere, to si jẹ pe awọn ẹya ara wọn ko i tii gbo lati gba oorun bẹẹ mọra.
"Lati inu ilẹ to jin tabi eyi ti ko jin ni oorun naa n gba wa latari awọn nnkan to n dapọ mọ ayika latara awọn kẹmika ti wọn fi n pese nnkan"
Alabojuto eto ayika ni ipinlẹ Ogun, Ola Oresanya sọ pe awọn eeyan ko nilo lati bẹru nipa oorun ti wọn n gbọ.
Oresanya sọ pe oorun naa kii ṣe ohun to le pa eeyan tabi ṣe ipalara fun agọ ara.
"Ti ẹ ba ti n gbọ oorun naa, ẹ fi aṣọ pelebe sinu omi ki e fi bo imu u yin, ko ni si wahala.
"Ẹ ma si jẹ kawọn ọmọ to ba ni aisan kan tabi omiran lọ sile ẹkọ lasiko ti oorun yii ba n waye."
Nigba to n ṣalaye ọna ti oorun naa n gba jade, o sọ pe o jẹ lati inu ilẹ to jin tabi eyi ti ko jin ni oorun naa n gba wa latari awọn nnkan to n dapọ mọ ayika latara awọn kẹmika ti wọn fi n pese nnkan.
O ni iwadii n lọ lati mọ ohun to n fa oorun to n waye lemọlemọ yii ki eyi to waye lọsẹ to kọja yii to jade.
"Mo fi n da awọn eeyan wa loju pe a ti n ri okodoro nnkan to n ṣẹlẹ, a ma le jẹki wọn mọ laipẹ."




























