Afẹ́fẹ́ gáàsì burúkú fẹ́ lù àwọn ìlú kan l'Ogun, ọ̀pọ̀ akẹ̀kọ̀ọ́ dèrò iléèwòsàn, aráàlù sọ ohun tó ṣeéṣe kó fàá

Aworan inu ileẹkọ naa ati iwaju rẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Niṣe lọrọ tun di bi o ko le lọ, ki o yago lọna nigba ti wọn sọ pe oorun buruku kan tun suyọ lawọn agbegbe kan niluu Ijebu-Igbo ati Ijebu-Ode, to si ṣe akoba fun ọpọ akẹkọọ.

Awọn akẹkọọ ile-ẹkọ girama ti ko din ni mẹta la gbọ pe oorun buruku naa ti ṣọṣẹ, to si sọ pe ọpọ akẹkọọ ati olukọ di eru ile iwosan.

Iṣẹlẹ yii ni yoo jẹ igba kẹrin iru rẹ to ṣẹlẹ laaarin ọdun 2026, ti ijọba ipinlẹ naa si ti n wa iyanju si i.

Asiko ti wọn ni awọn akẹkọọ naa wa ni yara ikẹkọọ, ni afẹfẹ oorun buruku naa fẹ lu wọn, to si mu ki ọpọ wọn ṣubu lulẹ.

Ijebu-Igbo Girls Grammar School; Anglican Girls Grammar School, to wa ni Ijebu-Ode, Itamerin Comprehensive High School, to wa niluu Ago-Iwoye; Abusi Edumare Girls Grammar School to wa ni Ijebu-Igbo, ati awọn ile-ẹkọ miran ni oorun buruku naa ti ṣọṣẹ.

Kete ti iroyin ti tẹ ijọba ipinlẹ Ogun lọwọ la gbọ pe wọn ti ju agaadagodo sẹnu ọna awọn ile-ẹkọ naa, lati da eto-ẹkọ duro nibẹ.

Kí làwọn aráàlú sọ?

Aworan ile ẹkọ naa.

Lara awọn araalu to ba BBC sọrọ nibi iṣẹlẹ naa sọ pe, kii ṣe igba akọkọ ree ti oorun buruku naa yoo ṣọṣẹ fun awọn eeyan, ti wọn si ni ko tii sẹni to le fidi ibi to ti n wa mulẹ.

Ọgbẹni Paul Onogwu, ọkan lara awọn araalu ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ sọ fun BBC pe nnkan bi agogo mẹwaa owurọ Ọjọru, ọsẹ yii ni afẹfẹ oorun buruku naa jade.

Onogwu sọ pe kete ti awọn eeyan, paapaa awọn akẹkọọ naa ti bẹrẹ sii fa oorun naa simu, ni wọn ti bẹrẹ sii ṣubu lulẹ, ti wọn si n pokaka iku.

Ọkunrin naa fi kun ọrọ rẹ pe oorun buruku ọhun lo sọ pupọ awọn akẹkọọ to le ni ọgọrun kan di ero ile iwosan fun itọju.

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe ile iwosan ijọba to wa niluu Ijebu-Ode ni wọn gbe ọpọ awọn akẹkọọ naa lọ fun itọju.

"Kọ̀ǹga tí wọ́n ń gbẹ́ ló ń fa òórùn burúkú yìí"

Aworan iloro ileẹkọ naa pẹlu arabinrin kan niwaju rẹ.

Lara awọn araalu miran tun sọ fun BBC pe nnkan ti awọn ṣakiyesi ni pe awọn kọnga ti awọn eeyan n gbẹ lawọn agbegbe naa lo n fa oorun buruku naa jade, to si n ṣe akọba fun awọn eeyan, paapaa awọn akẹkọọ.

Ẹni naa to kọ lati darukọ ara rẹ sọ pe awọn ọpa afẹfẹ gaasi kan ti wọn ti ri mọlẹ tipẹ, ṣugbọn ti wọn ti pa ti, lo n gbe oorun buruku ọhun jade, nigba ti wọn ba gbẹ kọnga de ibi to wa.

O sọ siwaju pe ọpọ ile ni wọn ti kọ sori awọn ọpa afẹfẹ gaasi alopati naa, to si ṣoro lati ṣe awari wọn.

Bakan naa, Ọgbẹni Michael Abiodun, ọkan lara awọn obi akẹkọọ ti oorun buruku naa sọ di ero ile iwosan sọ fun BBC pe, oun ti wa pade ọmọ oun nile iwosan ijọba ti Ijebu-Ode.

Ṣe abo to peye wa fun awọn akẹkọọ lagbegbe naa?

Nigba ti BBC News Yoruba kan si ileẹkọ naa lọjọbọ, awọn akẹkọọ ti tun n ba eto ẹkọ wọn lọ nibẹ.

Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn iroyin kan ti jade tẹlẹ pe ijọba ti ti awọn ileẹkọ to wa nibẹ pa, abẹwo BBC sibẹ fihan pe ẹkọ n tẹsiwaju nibẹ. koda a gbọ wi pe awọn akẹkọọ to fara kaasa afẹfẹ gaasi naa, ti wọn ti ko lọ si ileewosan ni wọn ti tu wọn silẹ nileewosan lati pada sile, wọn ko si wa si ileẹkọọ naa lọjọbọ.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileẹkọ naa fi to BBC leti pe awọn n tẹsiwaju pẹlu ẹkọ awọn nitoripe ko si aṣẹ kankan to wa latọdọ ijọba pe ki wọn ti ilẹkun ileẹkọ naa. o ni lootọ awọn akẹkọọ ti wọn ko lọ sileewosan ko wa si ileẹkọọ nitori ilera ara wọn

Ìwádìí bẹ̀rẹ̀

Ni bayii, ijọba ipinlẹ Ogun ti wa sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lori iwadii kikun lati mọ ohun ganan to n fa afẹfẹ oorun buruku naa, ati ibi to ti n wa.

Akọwe agba nileeṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ ati imọ sayẹnsi nipinlẹ naa, Arabinrin Oluwatosin Oloko sọ fun BBC pe otitọ ni iṣẹlẹ naa, ati pe awọn ti wa lori rẹ.

Oloko fidi rẹ mulẹ pe nigba ti ijọba ba pari iṣẹ iwadii, wọn yoo fi to gbogbo araalu leti nipa abajade iwadii ti wọn ba ṣe.