Wo ìdí pàtàkí mẹ́rin tí Ààrẹ Tinubu kò ṣe fẹ́ kí ilẹ̀ Amẹ́ríkà fí àkọsílẹ̀ rẹ̀ nípà egbòogi olóró síta

Aarẹ Tinubu lo wọ aṣọ alawọ eeru pẹlu fila alawọ eeru to de sori, o n rẹrin bo ṣe fi igo soju, to si jokoo lori aga Aarẹ, bẹẹ ni iwe ati ẹrọ gbohungbohun wa lori tabili to kawọ le lori niwaju rẹ

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti ṣalaye idi mẹrin pataki ti ile-ẹjọ ilẹ Amẹrika eyi to wa ni ẹkun Columbia ko ṣe gbọdọ fi akọsilẹ ajọ FBI ati DEA ṣe nipa rẹ sita fun gbogbo araye.

Tinubu lo sọ bẹẹ ninu iwe ipẹjọ ti awọn agbẹjọro rẹ fi sita lọjọ Abamẹta.

Ninu iwe naa ni wọn ti sọ pe ofin anfaani si iroyin ati idaabo bo ẹtọ ọmọniyan yẹ ko jọba lori ṣiṣe afihan awọn akọsilẹ wọn, ati pe ko sẹnikẹni to fẹẹ mọ nipa rẹ.

Aarẹ Tinubu sọ pe ko si nnkan to kan araalu ninu ọrọ naa, ati pe awọn to pe ẹjọ naa ṣee nitori ifẹ ọkan ara wọn, ati pe wọn n fẹ mọ akọsilẹ to ni orukọ oun ninu.

Àwọn wo ni agbẹjọrò náà?

Christopher Carmichael, Victor Henderson ati Oluwole Afolabi ni awọn agbẹjọro to n ṣiṣẹ fun aarẹ lori ẹjọ yii.

Igbesẹ awọn agbẹjọro yii ko ṣai waye, bi ko ṣe ti ajafẹtọọ ọmọniyan kan nilẹ Amẹrika, Aaron Greenspan ṣe n beere fun awọn akọsilẹ Tinubu labẹ agbekalẹ ofin ilẹ Amẹrika nipa ominira iroyin.

Ṣugbọn ni bayii, gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ni wọn ti dide lodi si igbesẹ yii, ti wọn si n sọ pe awọn ọmọ Naijiria lẹtọọ lati mọ nipa awọn irin ajo aarẹ lati ẹyin wa.

Kí ló fa àríyànjiyàn yìí?

Kii ṣe igba akọkọ ree ti ọrọ awọn iwe ẹri ati akọsilẹ aarẹ nilẹ Amẹrika, paapaa awọn igbe aye to ti gbe sẹyin yoo maa jẹyọ sita gbangba.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọdun 2022 ni ọrọ ọhun ti jade, lasiko ti eto idibo apapọ to waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹji, ọdun 2023 n bọ lọna.

Awọn iwe kan lo jade sori ayelujara nipa bi ilẹ Amẹrika ṣe gbẹsẹ le awọn dukia kan.

Ile-ẹjọ kan nilẹ Amẹrika, eyi to wa niluu Illinois lo paṣẹ pe ki wọn gbẹsẹ le owo kan to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta dọla ($460,000) to wa lapo aṣuwọn Tinubu.

Eyi lo waye nipa ẹsun gbigbe egboogi oloro ti wọn fi kan an, ati awọn iṣuna kan to ṣe lọna ti ko ba ofin mu.

Ṣugbọn nigba naa, ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Aarẹ nigba naa kii ṣe ẹsun iwa ọdaran, bi ko ṣe eyi ti ijọba fi gba dukia pada labẹ ofin.

Ẹgbẹ oṣelu Labour ati oludije sipo aarẹ nigba naa, Peter Obi sọ pe niṣe lo yẹ ki wọn yọwọ Tinubu kuro ninu eto idibo labẹ ofin.

Ile-ẹjọ to gbọ ẹjọ idibo aarẹ gbe idajọ kalẹ ninu oṣu Kẹsan, ọdun 2023 wi pe awọn to pe ẹjọ ko fidi rẹ mulẹ nipa wi pe wọn fọwọ ofin mu Tinubu, wọn foju rẹ ba ile-ẹjọ, tabi pe wọn ju sẹwọn lori ẹsun ọdaran nilẹ Amerika.

Latigba naa ni awọn ẹgbẹ alatako ati awọn miran to n fẹ mọ okodoro ti wa lori ọrọ ọhun, ti wọn si n beere fun ẹkunrẹrẹ iroyin nipa Tinubu lati ilẹ Amẹrika.

Àwọn ìdí pàtàkí náà

Ààrẹ Tinubu sọ pé kò sí ọmọ Nàíjíríà tó fẹ́ẹ́ mọ̀ nípa ìrìn-àjò rẹ̀ láti ẹ̀yìn wá, àti pé àwọn tó n bèèrè fún àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ kàn n ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìfẹ́ ọkàn ara wọn lásán ni

Greenspan sọ pe ohun ti wọn n beere fun nipa "Aarẹ Naijiria to wa lori akoso lọwọ..." ati "orileede to ni eeyan to le ni miliọnu lọna igba, eyi ti igbe aye wọn nii ṣe labẹ akoso ipinnu Aarẹ Tinubu"

Ninu atako rẹ nipa ohun ti FOIA n beere fun, lo ti rọ ilẹ-ẹjọ ilẹ Amẹrika lati ma ṣe dahun awọn ibeere naa, nitori pe yoo tapa si ofin lati gba awọn iroyin nipa eeyna nitori ọrọ oṣelu nilẹ Naijiria.

Awọn agbẹjọro naa sọ pe awọn akọsilẹ naa ni wọn ṣe lati fi iroyin nipa iṣẹ ijọba sita.

Wọn ni ko si otitọ kankan ninu wi pe awọn araalu n fẹ lati mọ awọn ohun ti aarẹ ti ṣe sẹyin, paapaa leyi to nii ṣe pẹlu ilẹ Amẹrika, to si ni ofin ilẹ Amẹrika naa tọka si i aabo ẹtọ ọmọniyan.

Bakan naa ni igbimọ agbẹjọro ọhun tun sọ pe aarẹ wa ni ilera pipe fun ipo aarẹ to wa, ati pe ko si nnkan to kan FOIA nipa boya ẹnikan wa ni ilera pipe tabi bẹẹ kọ.

Kí ni àjọ FBI sọ?

Ajọ FBI nilẹ Amẹrika ti sọ pe awọn ko nii fi iroyin kankan nipa Aarẹ Bola Tinubu tilẹ Naijiria sita, lati le daabo bo awọn oṣiṣẹ ati awọn olofintoto wọn.

FBI sọ pe o ṣee ṣe ki wọn pa awọn oṣiṣẹ ati awọn to n fimu finlẹ fun wọn, bi awọn ba ṣee ṣi fi iroyin ati akọsilẹ wọn nipa Tinubu sita fun gbogbo eeyan lati mọ.

Ajọ naa lo sọrọ yii ninu ikilọ ti wọn gbe lọ siwaju ile-ẹjọ, lasiko ti wọn n dahun si ofin fifi iroyin nipa eeyan sita, eyi ti wọn pe ni 'Freedom of Information Act, FOIA', eyi to wa niwaju Onidajọ Beryl Howell ti ile-ẹjọ US District to wa ni District of Columbia niluu Washington, DC.

FBI sọ pe bi awọn ba fi iroyin ti wọn ni nipa eeyan sita, le ṣe akoba fun awọn eeyan kan.

Wọn ni awọn yoo ṣiṣẹ lori abala keje, iyẹn 'FOIA Exemption 7(F)', nipa didaabo bo eeyan.

Wọn sọ siwaju pe bi awọn ba fi iroyin tabi orukọ awọn eeyan kan sita lori akọsilẹ wọn, yoo fi ẹmi wọn sinu ewu.