Wo àlàyé bí o ṣe lè fi èsì ìdánwò O'level rẹ ṣọwọ́ sí JAMB láì kúrò nínú ilé rẹ

Oríṣun àwòrán, Jamb Help center
Awọn akẹkọọjade ile ẹkọ girama ni Naijiria ti le fi esi idanwo O'level wọn ṣọwọ si oju opo JAMB bayii lai kuro ninu ile wọn.
Alaga fidihẹ JAMB, Fabian Benjamin lo fi ikede naa lede loju opo X ajọ ọhun lọjọ Aje.
Benjamin sọ pe ajọ naa ti ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ajọ to n ri si idanwo WAEC ati WASCE lori esi idanwọ awọn akẹkọọ naa.
O ni awọn akẹkọọ le fi esi idanwo ipari ile ẹkọ girama wọn ṣọwọ si JAMB bayii ti JAMB yoo si fi ontẹ lu esi naa pẹlu awọn ajọ idanwo girama to ku.
Gẹge bo ṣe sọ, igbesẹ naa waye lọna ati mu ki nnkan rọrun fum awọn akẹkọọ.
Bi o ṣe le fi ontẹ lu esi idanwo O'Level rẹ lati ile

Oríṣun àwòrán, JAMB
Iwọyi lawọn igbesẹ ti o gbọdọ gbe lati fi esi idanwo rẹ ṣọwọ si JAMB lai kuro ninu ile rẹ.
- Lọ soju opo buyresultsverificationcode.ng.
- Tẹ nọmba NIN rẹ si aye ti wọn fi sibẹ ki o tẹ "Verify NIN"
- Kọ iye igba ti o joko lati kọ idanwo naa ati ajọ to bojuto idanwo bii WAEC tabi NECO
- Tẹ "Continue" lati tẹsiwaju
- Kọ ajiṣẹ email ati nọmba ẹrọ ilewọ rẹ ki o si tẹ "Pay Now" lati san owo
- Eyii yoo gbe ọ lọ si ibi ti o ti maa san owo
- San owo ti wọn bere pẹlu kaadi ATM rẹ tabi nipa ọna mii
- Lẹyin ti owo naa ba ti lọ tan, tẹ nọmba idanimọ idanwo rẹ, irufẹ idanwo to jẹ ati ọdun ti o kọ idanwo naa
- Bi o ṣe le fi esi idanwo O'Level rẹ si oju opo naa
- Lọ sori ẹrọ ilewọ rẹ ki o si fi "VERIFY" ṣọwọ si 55019 tabi 66019
- Esi idanwo naa yoo lọ, ajọ naa yoo si kan si ọ
- Awọn ti wọn kọ idanwo naa ju ẹẹkan lọ yoo gba ipe lati lọ soju JAMB e-Facility
- Loju opo JAMB e-Facility, tẹ "2026 UTME O'Level Upload"
- Kọ Verification Code rẹ sibẹ, yoo si gbe esi idanwo ti o ṣe lẹẹmeji naa jade
- Tẹ awọn ẹka idanwo ti o ṣe ki o si tẹ "Apply the O'Level Results" lẹyin naa
Ti esi idanwo ọhun ba ti lọ, JAMB yoo jẹ ki o mọ.
Ninu ọrọ Benjamin, o ni ajọ JAMB yoo tẹsiwaju lati maa lo imọ ẹrọ fun idanwo, yoo si tẹsiwaju lati maa ba awọn ajọ idanwo mii ṣiṣẹ papọ fun anfani awọn akẹkọọ.




























