Ṣé lóòótọ́ ni OPay fẹ́ kógbá wọlé ní Naijiria lónìí ọjọ́ kíní oṣù Kẹ́sàn án? Ohun tí a mọ̀ rèé

Ileesẹ banki Opay to jẹ onipako ti wọn kun ni awọ funfun ati eweko, awọn onibara ati osisẹ n takurọsọ

Oríṣun àwòrán, OPay NG/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iroyin kan lo n ja rain nilẹ pe banki ori ayelujara, Opay, ti ọpọ ọmọ Naijiria maa n lo fun isẹ ati okoowo wọn yoo kogba wọle.

Oni ọjọ kinni osu kẹsan ọdun 2026 si ni wọn n sọ kiri pe Opay yoo poora pẹlu owo ọpọlọpọ ọmọ Naijiria.

Iroyin naa tun sọ pe ileeṣẹ OPay ti rọ àwọn oníbàárà rẹ lati gba owo wọn ni OPay ṣaaju igba ti won yoo kogba wọle.

Amọ se bẹẹ ni ọrọ yii ri bi, ootọ wo si lo wa ninu iroyin naa?

Ni bayii, awọn aláṣẹ banki ori ayelujara, OPay, ti sọ pe irọ to jinna si otitọ ni iroyin kan to ti gba ori ayelujara kan pe OPay yóò kogba wọle láti ọjọ kinni oṣù Kẹsán an ọla yìí.

Nínu atẹjade kan ti OPay fi sita loju opo ayelujara rẹ, ileeṣẹ OPay fi ọkàn awọn onibaara rẹ balẹ wi pe ki wọn ma fòyà torí ileeṣẹ naa ko lọ ibikan.

OPay sọ nínú àtẹ̀jáde to fi sita pe "irọ nla ni iroyin naa, OPay ko ni sẹwele bo se n ṣiṣẹ, digbi ni a wà."

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ OPay rọ àwọn oníbàárà rẹ ati gbogbo eeyan wí pé ki wọn kọ eti ikun sí iroyin ofege t'awọn eeyan kan n gbe kiri.

Wọn ní ọrọ ti OPay ba fi sita nìkan ni kawon onibaara awon maa tẹle.

"Awọn onibaara OPay mọ bi a se maa n b'awọn sọrọ.

A fẹ ki ẹ maa ṣ'ayẹwo irufẹ iroyin t'awọn eeyan n pin nípa OPay loju ayelujara ki ẹ to gba a wolẹ.

Ẹ maa lọ soju opo OPay lori ayelujara fún iroyin lori OPay."

"Ẹyin onibaara wa, ẹ ma gba owo yín kuro ní OPay, ẹ ma jẹ kí ẹnikẹni ṣi yin lọna"

Ẹwẹ, igbakeji ààrẹ igbimọ to n ri si ọrọ ori ayelujara to ni ṣe pẹlu OPay, Ọmọwe Maxwell Loko sọ pe iroyin t'awọn eeyan kan n gbe kiri naa le ṣi ọpọ eeyan lọna.

Ọmọwe Loko ni OPay ko kogba sile, o si rọ àwọn oníbàárà wọn lati kọ eti ikun sí iru iroyin to n lọ kaakiri.

"Ẹyin onibaara wa, ẹ ma gba owo yín kuro ní OPay, ẹ ma jẹ kí ẹnikẹni ṣi yin lọna," Loko lo sọ bẹẹ.

Ọgbẹni Loko fikun ọrọ rẹ pe bi awọn eeyan kan ṣe n gbe iroyin ofege kiri nipa OPay le da ibẹrubojo silẹ.

O ni o si le jẹ k'awọn onibaara ma ni igboya ninu OPay mọ.

Ọmọwe Loko tun kọminu lori b'awọn eeyan kan ṣe n ṣe oríṣìíríṣìí fídíò lati ba orúkọ OPay jẹ.

Loko ni ko si ẹri to daju to le fidi iroyin ofege ti wọn n gbe kiri múlẹ.

OPay wa rọ àwọn oníbàárà rẹ pe kí wọn ṣe pẹlẹ ki won si maa ṣ'ayẹwo iroyin ti wọn ba ti ri nipa OPay dáadáa.

Àtẹ̀jade ti OPay fi sita ti tan imọlẹ si ìròyìn tó ti gbalẹ kan wi pe OPay yóò kogba wọle lọjọ kínní oṣù Kẹsan an.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post