NRC àti NSCDC dá ìgbìyànjú fífọ́ àti jíjí ohun èlò ojú irin dúró l'Osun

Reluwee ilẹ Naijiria ree to duro, awọn eeyan wa ni ayika rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ to n ri sọrọ irin-ajo oju irin, iyẹn reluwee nilẹ Naijiria, NRC, ti sọ pe awọn tun ti ṣe aṣeyọri tuntun nipa dida awọn amookunṣeka kan ti wọn fẹẹ ji awọn ohun elo ileeṣẹ naa gbe nipinlẹ Osun.

Atejade ti awọn alakoso ajọ NRC fi sita lọjọ Aiku to kọja yii, fidi rẹ mulẹ, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe asiko ti awọn afurasi ọdaran naa n gbiyanju lati ṣiṣẹ ibi ni aṣiri wọn tu.

NRC sọ pe aṣeyọri yii lo waye nipa ajọṣepọ pẹlu ileeṣẹ NSCDC ẹka tipinlẹ naa.

Ninu atẹjade naa ti agbẹnusọ ileeṣẹ NRC, Callistus Unyimadu fi sita f'awọn akọroyin, lo ti fidi rẹ mulẹ pe ọjọ Ẹti ni iṣẹlẹ ọhun waye.

Callistus Unyimadu sọ pe apa kan ti ileeṣẹ Dangote Steel Rolling Mills n lo, ni awọn afurasi ọhun fẹẹ ge irin rẹ lọ, ko to di pe akara wọn tu sepo.

Agbẹnusọ naa jẹ ko di mimọ pe kete ti awọn oniṣẹ ibi yii kofiri awọn oṣiṣẹ wọn, ni wọn tin a papa bora, ki ọwọ ma ba a tẹ wọn.

O sọ pe awọn irinṣẹ ti wọn fi n ge irin reluwee lọna aitọ bii agba afẹfẹ gaasi mẹsan ni awọn afurasi naa fi sita, lasiko ti wọn na papa bora.

"Lọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni wọn ta awọn ọga agba lẹka NRC niluu Oṣogbo, ipinlẹ Osun lolobo, nipa awọn kan ti wọn n ge irin reluwee," Unyimadu sọ bẹẹ.

"Loju ẹsẹ ni wọn ti gbera lọ sibẹ lati mọ ohun to n ṣẹlẹ, ati awọn to wa nidi iwa ibajẹ naa. Kete ti awọn afurasi yii ti kofiri awọn oṣiṣẹ aabo, ni wọn ti juba ehoro."

Àwọn irinṣẹ́ wọn ti wà ní ìkáwọ́ wa

Agbẹnusọ ọhun fi kun ọrọ rẹ pe; "Iwadii ti wọn ṣe, lo pada jẹ ki wọn ri agba afẹfẹ gaasi mẹsan ti wọn gbe wa lati fi ṣiṣẹ aitọ naa."

O wa sọ pe awọn pẹlu ajọṣepọ NSCDC ti ko gbogbo awọn irinṣẹ naa, ati awọn irin reluwee ti wọn tig e, lọ pamọ, pẹlu bi igbesẹ ṣe ti n lọ lati ṣe atunṣe lori awọn nnkan ti wọn bajẹ.

Ó ṣe pàtàkì láti dáàbò bò ohun ìní rélùweè

Nigba toun naa n sọrọ, alako agba fun ileeṣẹ NRC, Kayode Opeifa, ṣapejuwe ohun to ṣẹlẹ yii, gẹgẹ bi aṣeyọri tuntun ninu igbiyanju lati daabo bo awọn ohun ini ijọba, paapaa awọn ti ileeṣẹ wọn lọwọ awọn oniṣẹ ibi.

"Aṣeyọri tuntun miran ree, ninu igbiyanju lati daabo bo awọn ohun ini ileeṣẹ reluwee lọwọ awọn oniṣẹ ibi ti wọn n gbiyanju lati ba a jẹ, pẹlu eto ọrọ aje," Opeifa fidi rẹ mulẹ.

O wa gbe oṣuba kare fun awọn ẹṣọ aabo ileeṣẹ naa, lori bi wọn ṣe tete dide si iṣẹlẹ naa, to si rọ gbogbo awọn oṣiṣẹ aabo patapata lati maa tọpinpin loore-koore nipa awọn to n ge irin reluwee lọna aitọ, ati ji awọn irinṣẹ wọn gbe.

"Ohun ini ileeṣẹ reluwee jẹ ohun pataki ti a ni lati daabo bo fun iṣẹ lati lọ deedee, fun idagbasoke eto ọrọ aje orileede yii."

Ojúṣe gbogbo èèyàn ni

Ọga agba naa wa a rọ gbogbo awọn eeyan to n gbe lagbegbe ati ayika ibi ti ọkọ reluwee gba kaakiri Naijiria lati maa ta awọn oṣiṣẹ wọn lolobo, nigba ti wọn ba kofiri awọn oniṣẹ ibi ti wọn fẹ ba a jẹ.

Bẹẹ lo tun rọ awọn araalu lati gbaruku ti ipolongo lo n tako bi awọn ọbayejẹ ṣe n ba awọn irin reluwee jẹ, ti wọn si n ṣakoba fun awọn ohun ini ileeṣẹ wọn.

Bakan naa lo paṣẹ fun awọn ẹṣọ aabo lati bẹrẹ igbesẹ iwadii nipa rirọwọ to gbogbo awọn afurasi to ba lọwọ ninu igbiyanju lati ba irinṣẹ reluwee, ẹka ti 'Dangote Steel Rolling Mills siding' jẹ.