Ọmọ mẹ́fà kú s'ígbèkùn gbọ́mọ-gbọ́mọ tó ń ta àwọn ọmọdé l'Oyo, ọlọ́pàá dóòlà èèyàn 17, ọwọ́ tẹ afurasí alfa, babaláwo àtàwọn míì

Awọn afurasi gbọmọ-gbọmọ to n fọmọde ṣe kata-kara

Oríṣun àwòrán, Oyo Police Command/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kede pe ọmọde mẹfa lo ti ku si igbekun awọn afurasí gbọmọ-gbọmọ at'awọn to n fi eeyan ṣe kata kara nipinlẹ Oyo.

Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo tun kede pe ọmọ metadinlogun lawọn doola nigba ti ọwọ tẹ afurasi meje lẹyin iṣẹ ìwádìí t'awọn ọlọpaa ṣe lori awọn gbọmọ-gbọmọ at'awọn to n fi eeyan ṣe kata kara kaakiri ipinlẹ Oyo.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ipinlẹ Oyo, CP Abimbola Olugbenga lo fidi ọrọ yìí múlẹ fawọn akọroyin ni olú ileeṣẹ ọlọpaa to wa lagbegbe Eleyele niluu Ibadan lọjọ Aje ọjọ keje oṣù Kẹsán an yìí.

CP Olugbenga ṣàlàyé pe ọlọpaa bẹrẹ ìwádìí lẹyìn tí Adegoke Popoola t'awọn eeyan mọ si Orente Alagbo lagbegbe Sogade Ariyo ni Ibadan mu iwe ẹsun lọ sọdọ awọn ọlọpaa wi pe awon eeyan n gbimọ pọ láti ba oun lorukọ jẹ ati wi pe wọn n dunkooko lati gba ẹmi oun.

Ọga ọlọpaa sọ pé nígbà tí ikọ ọlọpaa otelemuye n ṣiṣẹ lori ọrọ naa ni wọn ṣakiyesi wi pe ọmọ ọdun mẹta kan, Ifakunle Ifagbenro ṣadeedee dawati lasiko ọdún eegun niluu Oyo lọjọ kọkandinlọgbọn oṣù Kẹfa ọdun yii.

Ọga ọlọpaa ni ọmọ kekere naa tẹle baba rẹ lọ sí agbo ile ana rẹ ti wọn ti n ṣọdun ni.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ni Popoola toun naa wa níbí ọdun eegun yii gbe ọmọ naa, loun ati ọmọ kékeré yii ba di awati níbẹ.

Bayii ni wọn f'ọrọ naa to agọ ọlọpaa Atiba leti niluu Oyo.

Ìwádìí ọlọpaa fìdí rẹ múlẹ wi pe Popoola gbe ọmọ naa lóòótọ́.

Bayii ni Popoola dero agọ ọlọpaa lọjọ kerin osu Kẹjọ, o si jẹwọ pe oun loun gbe ọmọ naa nibi ọdun eegun lóòótọ́.

''A maa n ta ọmọ kan to ₦500,000 sí ₦600,000''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ni ijẹwọ Popoola ni aseyori akọkọ awọn ọlọpaa lori awọn afurasi gbọmọ-gbọmọ to n ṣọṣẹ nipinlẹ Oyo.

Bayii ni afurasi naa jẹwọ wi pe oun ti kopa ninu ijinigbe ọmọ to le ni meedogun.

O ni lati ṣọọṣi ati ibi ayẹyẹ lawọn ti maa n gbe awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn ko ju ọdún meji si meje lọ laarin ipinlẹ Oyo ati ni ibomiran.

O darukọ enikan to n jẹ Adekanbi Janet ti won n pe ni Hosanna gẹgẹ bii ọkan lára ẹni t'awọn jọ maa n ṣiṣẹ pọ.

Ọlọpaa wa Adekanbi dé Mowe nipinlẹ Ogun nibi ti won ti doola ọmọ mẹrin ti wọn kò ju ọdún meji si merin lọ.

Koda, awọn ọlọpaa tun sawari oloyun meji níbẹ.

Adekanbi jẹwọ pe oun ti n ṣiṣẹ pọ pẹlú Popoola fun bi ọdun mẹwaa, amọ, o sọ pe kii ṣe ọdọ oun ni Ifakunle ti won n wa wa.

Adekanbi tun jewo fawọn olopaa wi pe awọn ọmọ tàwọn ba ji gbe maa n wa ni igbekun awọn titi tawon yoo fi ta won.

Bakan naa lo tun jẹwọ pe awọn maa n tọju awọn to loyun titi ti wọn yoo fi bímọ.

Awọn ọrọ ti wọn ri gba lẹnu rẹ láwọn ọlọpaa fi ṣawari Ifakunle lagbegbe Gbagi niluu Ibadan.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá fikun ọrọ rẹ pe lojo keji osu Kesan an ni igbimo oluwadii ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo tun sawari ọmọ merin ti won ji gbe nipinle Oyo niluu Agbor nipinlẹ Delta nibi ti won ti gb'awọn ọmọ naa lọwọ awọn ti wọn ra wọn.

Afurasi meji, Christopher Joy ati Rosemary Jesse lọwọ ọlọpaa tun tẹ níbẹ.

Ọga ọlọpaa tun sọ pe ọkan lára àwọn afurasi naa jẹwọ pe awọn maa n ta ọmọ to ba ti ku si igbekun awọn fawọn oloogun owo ni.

Bayii ni ọwọ tun ṣe tẹ Muritala Fasasi, alfa ati Yakubu Azeez toun jẹ babalawo tawọn mejeeji naa jẹwọ pe lóòótọ́ làwọn maa n lo oku ọmọde fun ogun owo.

Afurasi Orente sọ fawọn olopaa pe awon maa n ta ọmọ kan to ₦500,000 sí ₦600,000.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá wa rọ gbogbo obi ati alagbatọ ti wọn n wa ọmọ wọn lati kan sí olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleyele niluu Ibadan lati wa wo o bo ya ọmọ wọn wà lara awọn ti ọlọpaa doola.

Ọga ọlọpaa wa ṣeleri wi pe awọn agbofinro ko ni kaarẹ nípa pipese ààbò fawọn ọmọde ati fun gbogbo araalu lapapọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post