'Ibi alálàájì tó gẹṣin lọ Jumat lọmọ mi lọ tí wọ́n fi jíi gbé, bí mo ṣe ríi lẹ́yìn ọdún kan àti oṣù méjì rèé'
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kede pe ọmọde mẹfa lo ti ku si igbekun awọn afurasí gbọmọ-gbọmọ at'awọn to n fi eeyan ṣe kata kara nipinlẹ Oyo.
Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo tun kede pe ọmọ metadinlogun lawọn doola nigba ti ọwọ tẹ afurasi meje lẹyin iṣẹ ìwádìí t'awọn ọlọpaa ṣe lori awọn gbọmọ-gbọmọ at'awọn to n fi eeyan ṣe kata kara kaakiri ipinlẹ Oyo.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ni ijẹwọ ọkan lara awọn afurasi naa ni aseyori akọkọ awọn ọlọpaa lori awọn afurasi gbọmọ-gbọmọ to n ṣọṣẹ nipinlẹ Oyo.
Bayii ni afurasi naa jẹwọ wi pe oun ti kopa ninu ijinigbe ọmọ to le ni meedogun.
O ni lati ṣọọṣi ati ibi ayẹyẹ lawọn ti maa n gbe awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn ko ju ọdún meji si meje lọ laarin ipinlẹ Oyo ati ni ibomiran.
O darukọ enikan to n jẹ Adekanbi Janet ti won n pe ni Hosanna gẹgẹ bii ọkan lára ẹni t'awọn jọ maa n ṣiṣẹ pọ.





