APC àti PDP pe ẹjọ́ tako èsì ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun tó gbé Adeleke wọlé fún sáà kejì

Najeem Salaam, Bola Oyebamiji, ati Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Najeem Salaam/Bola Oyebamiji/Ademola Adeleke

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lẹyin nnkan bii ọjọ mẹtalelogun ti eto idibo gomina ipinlẹ Osun waye ni awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ṣẹṣẹ lọ sile ẹjọ lati pe esi ibo naa nija.

Ti ẹ ko ba gbage, ọjọ mọkanlelogun lẹyin eto idibo ni awọn ẹgbẹ oṣelu ti esi ibo naa ko ba tẹ lọrun ni lati gba ile ẹjọ lọ lati pe esi ibo naa nija.

Gomina Ademola Adeleke ti ẹgbẹ oṣelu Accord lo jawe olubori ninu eto idibo naa pẹlu ibo 511,067,nigba ti Bola Oyebamiji ti ẹgbẹ APC lulẹ pẹlu ibo 444,815.

Ẹgbẹ oṣelu mẹrinla mii lo kopa ninu eto idibo ọhun yatọ si ADC ti Adeleke.

Lẹyin ti ajo INEC kede esi ibo naa tan ni igbimọ to maa n gbọ ẹjọ esi ibo ṣilẹkun ninu ọgba ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun to wa ni Oke Fia, niluu Osogbo.

APC ati PDP pe ẹjọ lati tako esi ibo naa

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹta lẹyin eto idibo naa ni Oyebamiji to dije ninu ẹgbẹ oṣelu APC sọ pe awọn yoo ṣagbeyẹwo esi ibo naa daadaa ki awọn to mọ igbesẹ ti awọn yo gbe.

Eyii waye lẹyin to ti kọkọ kọ lati ki Adeleke to jawe olubori ku oriire fun yiyan sipo rẹ fun saa keji.

Lẹyin naa ni ẹgbẹ oṣelu ọhun sọ fun awọn aṣoju rẹ pe oun fẹ ri awọn fọọmu kan bi 'form' EC8A, EC8B ati EC8C fun iwadii.

Adari ipolongo ibo naa, Oluwole Oke sọ pe awọn fẹ ṣayẹwo naa lati mọ boya awọn yoo lọ sile ẹjọ tabi bẹẹ kọ.

Ọsẹ meji lẹyin eto idibo naa ni Oyebamiji ki Adeleke ku oriire fun aṣeyọri rẹ ninu eto idibo ọhun.

Nigba to n ba awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu naa sọrọ niluu Osogbo, Oyebamiji sọ pe oun ki Adeleke ku oriire fun ilọsiwaju ijọba awarawa, lẹyin naa lo rọ Adeleke ko daabo bo dukia awọn araalu ko si dẹkun ikọlu si awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Wayi o, lẹyin nnkan bii ọsẹ mẹta ti eto idibo naa waye ni ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP pe ẹjọ tako esi idibo ọhun.

Akọwe igbimọ kotẹmilọrun naa, Pefe Belemore, sọ fun awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan pe àwọn ẹgb ẹ oṣelu naa ti pe ẹjọ tako esi ibo naa.

Pefe Belemore sọ pe awọn yoo lẹ iwe ipẹjọ naa siwa ile ẹjọ fun anfani gbogbo araalu laipẹ.

Nọmba ipẹjọ ẹgbẹ oṣelu APC ni EPT/OS/GOV/01/2026, nigba ti nọmba ipẹjọ PDP jẹ EPT/OS/GOV/02/2026.

Ẹgbẹ oṣelu ADC ko fi akoko ṣofo lati gba esi idibo naa

Ni ti Najeem Salaam to dije ninu ẹgbẹ oṣelu ADC, ko fi akoko ṣofo lati jẹ ki aye mọ ibi to duro si.

Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹjọ, to jẹ ọjọ keji ọjọ idibo lo ki Adeleke ku oriire, o si sọ lọọ naa pe "Ifẹ awọn araalu lo gbọdọ ṣe."

O sọ siwaju si pe ọrọ oṣelu ko gbọdọ di ohun ti araalu yoo maa gbẹmi ara wọn si, o tun rọ Adeleke ko fi saa rẹ keji lori oye ṣe atunṣẹ awọn aṣiṣẹ rẹ ni saa akọkọ.

Apapọ ibo 17,180 ni Najeem Salaam ni eto idibo ọhun.

Esi ibo ti ko ni atako nile ẹjọ

Lọdun 2016, gomina Rotimi Akedolu sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin Punch pe awọn ọmọ ẹgbẹ alatako ko lọ ile ẹjọ lati tako iyansipo oun gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ondo.

O sọ lọdun naa pe awọn igbimọ to yẹ ko gbọ ẹjọ naa ni wọn pada siluu Abja nitori awọn to n ba oun du ipo naa lọdun ọhun, Eyitayo Jegede ati Olusola Oke ko pe ẹjọ.

Amọ ṣa, nigba to wọle fun saa keji lọdun 2020, Eyitayo Jegede pe ẹjọ tako esi ibo ọhun, ẹjọ naa de ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Abuja ki wọn to pada da a nu, amọ Akeredolu jade laye ko to pari saa keji ọhun.