Mo fẹ lọ fún ìsinmi díẹ̀ kí ara lè tù mí láti lé sin àwọn èèyàn Osun dáadáa - Gómìnà Adeleke

Oríṣun àwòrán, News In Naija
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke ti tẹkọ leti roke okun fun isinmi lẹnu iṣẹ lẹyin to jawe olubori ninu ib sipo gomina fun saa keji eyi to waye lọjọ karundinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2026.
Atẹjade ti agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọṣun, Ọlawale Rasheed fi sita ṣalaye pe Gomina Adeleke ti gbera lati ilu Eko lọ si ilẹ yuroopu fun isinmi.
Bakan naa ni atẹjade ọhun tun sọ pe Adeleke yoo tun lọ fun ayẹwo ilera ara rẹ ni ilẹ Gẹẹsi lasiko isinmi naa.
Adeleke sọ pe "Mo fẹ lọ fun isinmi diẹ ki ara le tu mi lati le sin awọn eeyan ipinlẹ Osun daadaa."
Adeleke dá sí ọ̀rọ̀ ìlú Koka tó ní ọba méjì kó tó lọ sinmi lókè okun
Atẹjade ti Rasheed fi lede sọ pe gomina Adeleke ti "paṣẹ fun ileeṣẹ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ lati ṣewadii iroyin to ni wọn ti yan ọba mii fun Koka Ilase, eyii to mu ki ilu naa ni ọba meji.
"Aṣẹ ti jade si ileeṣẹ ijọba naa ko ṣe agbeyẹwo ọrọ ọhun ko si ri daju pe wọn tẹle ofin to rọ mọ igbesẹ yiyan ọba ati alakalẹ aṣa."
Nigba to n sọrọ lori yiyan ọba mii fun ilu Koka, atẹjade naa ni gomina sọ pe "Mo gbọ pe wọn ti yan ọba mii lẹyin ẹni to wa lori oye. Mo ti pasẹ fun ileeṣẹ ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ ki wọn bojuto ariyanjiyan naa ki wọn si fi atẹjade sita lati tan imọlẹ si ọrọ ọhun.
"Mo fi akoko yii rọ gbogbo awọn ti ọrọ naa kan ki wọn gba alaafia laaye bi ileeṣẹ naa ṣe n ṣiṣẹ lori ọrọ ọhun.
"Ọrọ ọba ni ilana ati ofin to rọ mọ, ijọba yoo si gbe lẹyin ilana ati ofin to rọ mọ igbesẹ naa."
Atẹjade naa wa ke si ileeṣẹ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ ki wọn ṣewadii bi wọn ṣe yan ọba tuntun niluu Koka nigba ti ọba kan ti wa nibẹ tẹlẹ, eyii to mu ki ilu naa ni ọba meji.
O ni ki ileeṣẹ ọhun ṣayẹwo bi wọn ṣe yan ọba tuntun naa ki wọn si ṣe ohun to yẹ ni ilana ofin to rọ mọ oye ọba jijẹ nipinlẹ naa.


























