Wo àwọn alága EFCC tẹ́lẹ̀rí tí wọ́n ti fẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ kàn

Abdulrasheed Bawa, Ibrahim Lamorde ati Ibrahim Magu

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọpọ eeyan lo ti n kọminu lori ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria lẹyin ti alaga ajọ naa, Ola Olukoyede, sọ pe o le ni ogoji oṣiṣẹ ajọ naa to ti gba idaduro lẹnu iṣẹ nitori iwa ibajẹ.

Lẹyin ti Olukoyede sọrọ yii nibi eto to fi n ṣami ọdun mẹta to de ipo alaga EFCC lawọn eeyan bẹrẹ sii sọ ero wọn lori ajọ naa.

Ọpọ eeyan lo n sọ pe ti ọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria ko ba mọ, bawo ni wọn ṣe fẹ gbogun ti iwa ibajẹ lawujọ.

Idi niyii ti bi BBC Yoruba fi ṣe akojọpọ awọn alaga EFCC tẹlẹri ti wọn ti fẹsun iwa ibajẹ kan nigba ti wọn wa ni ọfiisi.

Abdulrasheed Bawa

Alaga ajọ EFCC tẹlẹri, Abdulrasheed Bawa, dero atimọle ajọ ọtẹmulẹyẹ DSS lọdun 2023 lori ẹsun ṣiṣe owo ilu kumọ kumọ, ṣiṣi ipo lo ati didari owo dukia ijọba ti EFCC gba si ibomiran.

Bawa ti ẹ kọ lati gba agbẹjọro funra rẹ nigba naa bo tilẹ jẹ wi pe o wa ni atimọle ajọ DSS.

Yatọ si pe o kọ lati gba agbẹjọro ti yoo ṣoju rẹ nile ẹjọ, alaga EFCC tẹlẹri naa tun kọ lati dahun ibeere tawọn ẹṣọ eleto aabo bi i nigba naa.

A gbọ pe ajọ DSS lọ sile Bawa niluu Abuja loju iyawo atawọn ọmọ rẹ fun iṣẹ iwadii wọn.

Bakan naa tun ni DSS tun lọ si ọfiisi Bawa niluu Abuja lati tẹsiwaju iwadii wọn lori Ọgbẹni Bawa.

Ajọ DSS tun sẹ ifọrọwanilẹwo fawọn alabaṣiṣẹpọ Bawa ti wọn ba ni ọfiisi rẹ niluu Abuja lori gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an.

Lẹyin naa ni DSS gba aṣẹ lọwọ ile ẹjọ lati le jẹ ki Bawa si wa ni atimọle bi iṣẹ iwadii wọn ti n tẹsiwaju.

Lara nnkan ti wọn bi Bawa leere ni bi EFCC ṣe ta ọkọ akẹru 244 ti ajọ naa ri gba niluu Port Harcourt.

Wọn fẹsun kan an wi pe o ta awọn ọkọ akẹru naa ti wọn to N20m si N30m ni N100,000 fawọn eeyan rẹ.

Eyi lo jẹ ki Olukoyede to jẹ akọwe EFCC nigba naa koju Bawa lọdun 2023, amọ, Bawa ni nnkan ti alaga EFCC tẹlẹ Ibrahim Magu sọ loun n tẹle.

Bakan naa tun ni gomina ipinlẹ Zamfara tẹlẹ, Bello Matawalle fẹsun kan Bawa wi pe o beere riba $2m lọwọ oun.

Ibrahim Magu

Alaga ajọ EFCC tẹlẹri, Ibrahim Magu, wọ gau lọdun 2020 lẹyin tawọn agbofinro gbe e ti o si dero atimọle.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan Magu ni iwa aigbọran ati kudiẹ-kudiẹ ninu akọsilẹ EFCC lori awọn dukia ijọba ti ajọ naa gba.

Bayii ni wọn da Magu duro lẹnu iṣẹ ti ijọba si gbe igbimọ oluwadii kan dide eyi ti Adajọ fẹyinti Ayo Salami jẹ alaga rẹ.

Ọfiisi agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ tẹlẹri, Abubakar Malami (SAN), lo fẹsun kan Magu.

Ninu oṣu Kọkanla ọdun 2020 ni igbimọ oluwadii naa jabọ fun ijọba, amọ, wọn ko gbe abọ naa jade ninu iwe iroyin lati ri i.

Agbẹjọro Magu ni ko si koko ẹsun kan ti ijọba fi kan Magu nile ẹjọ nigba naa.

Magu loun o jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun, o si pada sẹnu iṣẹ ọlọpaa rẹ.

Lẹnu iṣẹ ọlọpaa yii ni o ti gba igbega lẹnu iṣẹ eyi to fi gboye AIG loṣu Karun un ọdun 2022.

Pẹlu oye AIG to gba yii naa ni Magu fi fẹyin ti lẹnu iṣẹ.

Ibrahim Lamorde

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹsun ti wọn fi kan Ibrahim Lamorde, alaga EFCC tẹlẹ ni pe $5bn di awati lasiko to n dari ajọ naa.

Bayii ni ile aṣofin agba l'Abuja gbe igbimọ oluwadii kan dide lati tọpinpin owo atawọn dukia ijọba ti EFCC ri gba eyi to ṣee ṣe ki wọn ti dari sibomii.

Lamorde sọ fun BBC nigba naa wi pe irọ nla ni gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun.

Alaga EFCC tẹlẹ sọ pe bi ẹni pe eeyan n ṣere mọde lawọn ẹsun ti wọn fi kan oun tori ko lẹsẹ nlẹ.

Sẹnẹtọ Peter Nwaoboshi lo da aba iwadii naa nigba ti George Uboh gba a wọle.

Lamorde ṣalaye wi pe aropọ gbogbo owo ti EFCC ri gba ati owo ti ajọ naa n gba lati ọwọ ijọba ko le to $5bn.

O ni ko ṣee ṣe ki oun dari owo ti ajọ EFCC ko ni si ibomiran.

Awọn eeyan kan ti ẹ sọ pe nnkan ti ko sọnu ni ile aṣofin agba n wa kiri lọwọ Lamorde.

Amọ, Sẹnẹtọ Bukola Saraki to jẹ aarẹ ile nigba naa sọ pe ko si nnkan aṣiri kankan ninu iwadii EFCC ti ile aṣofin agba n ṣe.

EFCC n ṣewadii lori Sẹnẹtọ Saraki gan an funra rẹ lori ipa to ko lori ọrọ Societe General Bank of Nigeria to ti kogba wọle nipinlẹ Kwara.

Oun ati iyawo rẹ, Toyin Saraki lọ si ọfiisi EFCC fun ifọrọwanilẹnuwo nigba naa.

Saraki ni oun ati gbogbo eeyan ti ọrọ kan ran iṣẹ iwadii EFCC lọwọ lori ọrọ naa.

O ni ko si nnkankan ti oun fẹ gba lori ẹsun ti wọn fi kan Lamorde.