Mo pinnu láti fi Ogogo ṣe olùbádámọ̀ràn pàtàkì nínú ìjọba mi tí mo bá di gómìnà – Yayi

Solomon Olamilekan ati Taieo Hassan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Taieo Hassan/Solomon Olamilekan

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun, Solomon Adeola, ti ọpọ mọ si Yayi ti sọ pe agbara oṣere tiata Yoruba to di oloogbe, Taiwo 'Ogogo' Hasan, loun pinnu lati yan sipo olubadamọra pataki lori ọrọ aṣa ti oun ba de ipo gomina gomina.

Yayi lo sọrọ yii lasiko to ṣabẹwo ibanikẹdun si mọlẹbi Ogogo niluu Ilaro.

Aṣofin naa juwe Ogogo gẹgẹ bii ẹgbọn, o si gboriyin fun oloogbe naa fun ipa to ko ninu idagbasoke tiata ati aṣa nilẹ Yoruba.

O sọ pe nitori iriri Ogogo lori ọrọ aṣa ni oun ṣe pinnu lati yan an gẹgẹ bii ọkan lara awọn alabaṣiṣẹ oun ti ori ba gbe oun de ipo gomina.

"Idi ti mo ṣe fẹ fun Ogogo nipo ninu ijọba mi"

Aworan Yayi atawọn eeyan nibi oju oori Taiwo Hassan Ogogo.

Oríṣun àwòrán, Yayi

Nigba to n sọrọ nile ẹbi Ogogo, o ni "Mo sọ fun Ọlọrun pe to ba kadara mi pe mo maa di gomina, ẹgbọn mi ogogo ni yoo ṣe olubadmọran pataki mi lori irinajo afẹ ati aṣa.

"Aredi ti mo ṣe pinnu bẹẹ ko ju pe o jẹ ogbontarigi oṣere, o jẹ ẹni ibilẹ ati eeyan to mọ riri aṣa.

"Ki ni mo tun n fẹ? Aamọ ṣa, riro ni ti eniyan, ṣiṣẹ ni ti Ọlọrun."

Ṣaaju ni Yayi ti kọkọ ṣọfọ iku Ogogo, to si juwe ike rẹ gẹgẹ bii ọfọ nla si agbo oṣere ni Naijiria.

O ni ipa ti Ogogo ko ninu idagbasoke aṣa ati ere tiata nilẹ Yoruba ati ni Naijiria ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin.

Lasiko ti Ogogo dubulẹ aisan, o ni oun atawọn mii sa ipa wọn, wọn si nawa si oloogbe naa ko le gbadun amọ o fi iku ṣagba gbogbo wọn.

Niṣe ni Lima, ọmọbinrin Ogogo n wa ẹkun mu lasiko abẹwo naa.

Pẹlu omije loju, Lima juwe Ogogo gẹgẹ bii baba rere si awọn ọmọ rẹ ati ọkọ rere si awọn iyawo rẹ.

Lẹyin naa lo juwe rẹ gẹgẹ bii ọrẹ oun.

Lẹyin ti wọn sin oku Ogogo siluu Ilaro ni ilana ẹsin Musulumi ni awọn jankanjankan bẹrẹ si n ṣabẹwo siluu naa lati ba mọlẹbi rẹ kẹdun.