Ó tó gẹ́! A ò fẹ́ kí Sẹ́nẹ́tọ̀ Francis Fadahunsi ṣojú wa mọ́ nílé aṣòfin àgbà l'Abuja, - Àwọn Ọ̀dọ́ Ilẹ̀ Ijesa yari

Awọn iwe ilewọ tawọn ọdọ Ilẹ Ijesa fi sẹwọde tako Sẹnẹtọ Francis Fadahunsi

Oríṣun àwòrán, BBC/Senator Francis Fadahunsi/x

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awa o fẹ ki ṣẹnẹtọ to n soju ẹkun Ifẹ Ijẹsa nipinlẹ Osun, Francis Fadahunsi, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Fada mọ nile aṣofin agba niluu Abuja.

Ohun ti gbogbo agbarijopọ awọn ọdọ Ilẹ Ijẹsa n sọ niyii nibi iwọde ti wọn ṣe l'Ọjọru ọjọ kẹsan an oṣu Késan an yii.

Ṣaaju eto idibo gomina ipinlẹ Ọsun to waye loṣu to kọja ni Sẹnẹtọ n to soju Ifẹ Ijẹsa nile igbimọ aṣofin agba l'Abuja naa ti sọrọ kan to gba ori ayelujara pe ki wọn maa pa gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu Accord ti i ṣe ẹgbẹ Gomina Ademola Adeleke, tabi ẹnikẹni to ba ti de fila ẹgbẹ oṣelu naa.

‎Ṣugbọn ohun to mu ọrọ naa wa ni bi awọn janduku kan ṣe lọ pa ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC mẹta ni Ilu Ilesa lasiko igba naa.

Eleyii lo fa ọrọ ibinu ti Sẹnẹtọ Fadahunsi sọ lẹyin iku awọn mẹta naa.

Gẹgẹ bi a ti mọ wi pe, ọrọ ki ku o maa n sun ni.

‎Eyi lo mu ki agbarijopo awọn ọdọ ilẹ Ijẹsa ko ara wọn jade lonii ọjọ kẹsan osu Kẹsan an lati ṣe iwọde tako ọrọ ti Sẹnẹtọ Fadahunsi sọ naa.

Awọn ọdọ ni awọn ko fẹ ẹni to sọ pe ki wọn maa pa gbogbo eeyan mọ.

‎Ninu ọrọ rẹ. Olatunji Ọlọrunfẹmi ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Awoko sọ nipa ọrọ ti Sẹnẹtọ Fadahunsi sọ bi ẹni ti ko fẹran awọn ọdọ ilẹ Ijẹsa ti ko si gbero ohun rere fun wọn.

Awọn iwe ilewọ tawọn ọdọ Ilẹ Ijesa fi sẹwọde tako Sẹnẹtọ Francis Fadahunsi

Olatunji tun tẹsiwaju pe oun wa lara awọn to siwaju ipolongo idibo fun Sẹnẹtọ Fadahunsi lasiko to n wa ibo lati ọdọ awọn ọmọ ilẹ Ijẹsa ni saa akọkọ ati saa keji rẹ.

‎Ṣugbọn, o ni o ya oun lẹnu pe Sẹnẹtọ Fadahunsi le sọ iru ọrọ naa si awọn to fi ibo gbe e wọle lasiko igba naa.

‎Olatunji fikun ọrọ rẹ pe ohun ti awọn n fẹ ni iwadii ododo lati ọdọ awọn ọlọpaa lati ṣe awari awọn to ṣe iku pa awọn ti janduku pa ni akoko idibo si ipo gomina Ipinlẹ Ọsun ati lati tun ṣe iwadii ọrọ ti Sẹnẹtọ Fadahunsi sọ lasiko naa.

‎Ni bayii, gbogbo ọdọ ati agba ilẹ Ijẹsa ti kọ ẹyin si Sẹnẹtọ Fadahunsi, wọn ni awọn ko si fẹ ẹ mọ lati maa soju awọn nile igbimọ aṣofin agba l'Abuja nitori ko ro ohun rere fun awọn ọmọ bíbí ilẹ Ijẹsa rara.