Oriyomi fẹ́ já ẹgbẹ́ òṣèlú Accord gbà l'Oyo, Gudugudu ni olùdíje sípò Gómìnà fẹ́gbẹ́ wa - Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/X
Awuyewuye lori ẹni to jẹ ojulowo oludije gomina fẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ Oyo ko tii tan lẹyin ti igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa tun sọ pe Alhaji Oriyomi Hamzat kii ṣe oludije sipo gomina fẹgbẹ ọhun.
Igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa fidi rẹ mulẹ nibi ipade awọn akọroyin kan ti wọn pe lonii Ọjọru ọjọ kẹsan an oṣu Kẹsan an yii pe Olakunle Busari, ti ọpọ eeyan mọ si Gudugudu ni ẹgbẹ yan gẹgẹ oludije sipo gomina nipinlẹ Oyo.
Igbimọ naa fikun ọrọ rẹ pe Oriyomi ti tasẹ agẹrẹ nipa pipe ara rẹ ni oludije sipo gomina fẹgbẹ Accord.
Bakan naa ni wọn tun koro oju si bi wọn ti ni Oriyomi n yan awọn oloye ẹgbẹ atawọn oludije to wu u ninu ẹgbẹ lati du ọkan-o-jọkan ipo oṣelu funra ra, eyi ti ẹgbẹ ko fọwọ si.
Ninu ọrọ rẹ, akapo ẹgbẹ Accord nipinlẹ Oyo, Họnarebu Nurudeen Okunola, ṣalaye nibi ipade awọn akọroyin naa wi pe ''emi o ri ibi ti oludije ti n yan awọn eeyan mẹtalelọgbọn ti yoo dije fun ipo aṣoju ile igbimọ aṣofin kaakiri ipinlẹ Oyo ri.
Ṣugbọn mo mọ wi pe ti ẹnikan ba mọ nnkan daru, Ọlọrun naa mọ nnkan tun ṣe.
Nitori anfaani ti Oriyomi ni si ileeṣẹ iroyin lo jẹ ko maa pe ara rẹ ni oludije sipo gomina fẹgbẹ Accord nipinlẹ Oyo.
Amọ, mo mọ pe bi irọ ba lọ fun ogun ọdun, ọjọ kan ni otitọ yoo ba a.''
Ọgbẹni Okunola sọ pe ki ero maa tẹle eeyan lẹyin ko tumọ si pe ẹni naa yoo wọle ibo.
O ni Ọlọrun nikan lo mọ boya Gudugudu yoo wọle ibo gomina ipinlẹ Oyo.
''A o mọ boya Oriyomi fẹ fi ''Oyo n Pe Ọ'' dibo lọdun 2027, amọ, ko si nnkan ti ẹgbẹ lọwọ si ninu gbogbo nnkan ti o n ṣe''
Akapo ẹgbẹ Accord l'Oyo sọ pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu lo maa n wa nibi ipolongo ibo, tori naa ero to wa nibi ipolongo ko tumọ si pe oludije ibo kan yoo wọle.
Ọmọba Kolade Ojo to jẹ alaga ẹgbẹ Accord nipinlẹ Oyo ti akọwe ẹgbẹ naa sọrọ lorukọ rẹ sọ pe Oriyomi wa sinu ẹgbẹ lati ja ẹgbẹ gba.
''Oriyomi ti n sọ kiri wi pe oun ni oludije sipo gomina fẹgbẹ Accord nipinlẹ Oyo, amọ, mo layọ lati sọ fun gbogbo eeyan wi pe Oriyomi kii ṣe oludipe ẹgbẹ Accord o fun ibo gomina ipinlẹ Oyo lọdun 2027.
Mi o mọ boya o fẹ fi ''Oyo N Pe Ọ'' dibo, ṣugbọn ko si nnkan kan ti ẹgbẹ lọwọ si ninu gbogbo nnkan ti Oriyomi n ṣe.
Ni igba ti a fẹ ṣe eto idibo abẹnu fun awọn oludije sipo gomina nipinlẹ Oyo ni a ti sọ fun Oriyomi wi pe ẹgbẹ ko ni mu ẹnikẹni lai dibo.
Amọ, Oriyomi ko yọju sibi eto idibo abẹnu ti a ṣe, Họnarebu Busari nikan lo wa nibẹ atawọn aṣoju INEC.
Oun si ni oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ Oyo, awọn ti Oriyomi lọ ba niluu Abuja lati na ọwọ rẹ soke gẹgẹ bii oludije sipo gomina fẹgbẹ Accord ko le gbe Oriyomi le lori,'' akọwe ẹgbẹ lo sọ bẹẹ.




























