Bí iléẹjọ́ ṣe dá EFCC lọ́wọ́ kọ́ láti ṣe ìwádìí ìṣúná gómìnà Oyo, ẹgbẹ́ APM ní ẹ̀rù Makinde ló ń ba Tinubu

Gomina Seyi Makinde ree to jokoo lori aga gomina ipinle Oyo, o n woye pẹlu bo ṣe kawọ le tabili to wa niwaju rẹ pẹlu ẹrọ gbohùngbohùn pẹlu àwòrán Tinubu

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Bola Tinubu

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ile-ẹjọ giga apapọ to wa niluu Ibadan, nipinlẹ Oyo ti gbe aṣẹ kalẹ wi pe ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu nilẹ Naijiria, EFCC ko gbọdọ ṣe iwadii tabi tọpinpin eto iṣuna ijọba ipinlẹ Oyo labẹ iṣakoso Gomina Seyi Makinde.

Onidajọ Nkeonye Maha lo gbe idajọ naa kalẹ ninu ẹsun ti ijọba ipinlẹ Oyo gbe lọ siwaju rẹ lọjọ keji, o]su Kẹfa, ọdun 2025 lati tako bi ajọ EFCC ṣe fẹẹ wa tudi eto iṣuna wọn wo.

EFCC lo gbe akanṣe iwadii dide lati ṣe agbeyẹwo awọn owo iṣẹ akanṣe ti ijọba ipinlẹ Oyo gbe jade fun awọn agbaṣẹṣe laaarin ọdun 2021 si ọdun 2025.

Ile-ẹjọ naa sọ ọ di mimọ pe pe bo tilẹ jẹ pe ajọ naa ni aṣẹ labẹ ofin lati ṣe iwadii iwa jibiti owo ati ajẹbanu, ṣugbọn to tun sọ pe iru agbara bẹẹ ko gbọdọ da lori awuyewuye tabi lilo o lọna ti ko yẹ.

Gẹgẹ bi adajọ naa ṣe sọ, o ni ajọ EFCC fẹẹ ṣe iwadii ofintoto lori owo ti wọn na fun awọn agbaṣẹṣe, bo tilẹ jẹ pe wọn ko darukọ awọn agbaṣẹṣe tabi ileeṣẹ, tabi owo to jade, tabi ẹsun aṣemaṣe.

Ile-ẹjọ wa sọ pe ajọ naa gbọdọ bọwọ fun ẹtọ labẹ ofin lojuna lati ṣe eyikeyi iwadii tabi ofintoto.

Ijọba ipinlẹ Oyo lo sọ fun ile-ẹjọ wi pe ki ajọ EFC tọka si awọn agbaṣẹṣe tabi owo to jade ninu igbesẹ lati ṣe iwadii rẹ, ki awọn le pese gbogbo iwe ẹri to yẹ fun iwadii wọn.

Ṣugbọn ṣa, lẹyin ti wọn ko gbọ ohunkohun lati ọdọ ajọ naa, eyi lo mu ki ijọba ọhun gba ile-ẹjọ lọ, lati ṣe atupalẹ ofin lori iru igbesẹ bẹẹ.

Agbẹjọro ijọba, Amofin Abiodun Aikomo sọ fun ile-ẹjọ bi ajọ EFCC ṣe fẹẹ ṣe awọn iwadii to nii ṣe pẹlu ọpọlọ ọdun ko tọna rara, o jẹ bii idunkooko, ati pe ko si ẹsun kankan to tii lẹyin

Ṣugbọn ṣa, nigba ti agbẹjọr EFCC n sọrọ ni tiẹ, I.G. Ojibor sọ pe abala kejidinlogoji ninu iwe to awọn silẹ fun wọn ni agbara lati beere fun awọn iroyin nipa ẹnikẹni, alakoso yoowu, ileeṣẹ tabi ijọba ninu igbesẹ lati ṣe iwadii ofintoto.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidajọ Maha, o gbe iwe ajọ EFCC sẹgbẹ kan, to si paṣẹ pe, niwọn igba ti ajọ naa bi agbara lati beere ibeere nipa ohun to ba ru wọn loju, iru ibeere bẹẹ gbọdọ waye lọna to yẹ, lori awọn ẹsun to ṣee foju ri ati eyi to ṣee feti gbọ, to si tun lọ ni ibamu pẹlu ẹsun ti wọn ba fi sita labẹ iwe ofin idasilẹ ajọ EFCC.

Makinde yóò gba ìjọba lọ́wọ́ Tinubu lọ́dún 2026 – APM sọ̀rọ̀

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ju gbogbo rẹ lọ, ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement (APM) ti wa ṣalaye awọn idi pataki ti Gomina Seyi Makinde yoo ṣe fidi Aarẹ Bola Tinubu rẹmi ninu eto idibo aarẹ ti ọdun 2027.

APM sọ pe awọn ipa rere ti Makinde ti ko ninu iṣakoso rẹ bii akọsilẹ iṣakoso, atunto eto ọrọ ati bi idagbasoke ṣe n de ba ifẹ ti awọn eeyan n ni jakejado agbaye.

Ẹgbẹ naa sọ pe awọn akitiyan gomina lori atunṣe si eto ọrọ aje ati iṣẹ akanṣe manigbagbe ti gbe e si ipo ti awọn ọmọ Naijiria ri gẹgẹ bi ọna abayọ lati oke.

Ninu atẹjade ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa lapapọ, Abubakar Yusuf fi sita, lasiko to n sọrọ lori ọrọ ti oludamọran pataki si aarẹ lori eto iroyin, Daniel Bwala, nipa bo ṣe bu ẹnu atẹ lu ipo oṣelu Makinde.

O sọ pe bi agbẹnuọ ileeṣẹ aarẹ ṣe n ṣe ikọlu si Makinde, fi han pe iporuru ọkan ti n ba ileeṣẹ aarẹ, lori bi gomina ṣe n gba iyi ati iyi ṣaaju eto idibo apapọ ọdun 2027.

Yusuf sọ pe kaka ki wọn maa gbeja iṣakoso aarẹ lori awọn ipa to ti ko, ileeṣẹ aarẹ wa bẹrẹ sii ṣe atako si awọn alatako nidi oṣelu.

"Igbesẹ lati gbe awọn alabaṣiṣẹpọ aarẹ dide lati maa bu ẹnu atẹ lu Gomina Makinde ṣafihan aini igboya ninu aṣeyọri iṣakoso aarẹ. Eto idibo 2027 yoo ṣafihan ẹni ti ko ṣe pataki rara ni tootọ," atẹjade naa sọ bẹẹ.

Ẹgbẹ APM tun tọka si ifọrọwerọ ti Bwala ṣe pẹlu ileeṣẹ Al Jazeera ni ibẹrẹ ọdun yii, leyi to fi sọ pe awọn ọmọ Naijiria ti mọ ọna ti iṣakoso yii n gba sọrọ jade.

"Daniel Bwala maa too ko awọn ọrọ rẹ to fi tako Gomina Makinde jẹ," atẹjade ọhun ṣalaye.

"O yẹ ki Aarẹ Tinubu tete maa ṣaniyan bayii nitori pe Gomina Makinde n bọ lati ba a du ipo, pẹlu awọn ipa rere to ti ko lawujọ, to fi mọ bo ṣe tun ipo Oyo ṣe," Yusuf sọ bẹẹ.