Kókó ìpàdé Sẹ́nẹ́tọ̀ Folarin pẹ̀lú Ààrẹ Tinubu lórí awuyewuye nípa olùdíje sípò gómìnà fẹ́gbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Oyo

Oríṣun àwòrán, Senator Sharafadeen Ali/X
Lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii ni Sẹnẹtọ Teslim Folarin ṣe ipade pẹlu Aarẹ Bola ahmed Tinubu, lojuna lati ṣatilẹyin idibo fun oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Oyo lọdun 2027, Sharafadeen Alli.
Gẹgẹ bi awọn to wa nibi ipade naa ṣe sọ fun awọn akọroyin, ileeṣẹ Aarẹ to wa ni Aso Rock niluu Abuja ni ipade ọhun ti waye.
Ipade naa ni wọn lo da lori erongba lati fi opin si gbogbo aawọ, wahala ati ikunsinu to wa laaarin awọn agbaagba ati alẹnulọrọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Oyo, ṣaaju eto idibo gomina to fẹẹ waye ninu oṣu Keji, ọdun 2027.
Folarin to ti figba kan ri ṣoju Aarin Gbungbun ipinlẹ Oyo nile igbimọ aṣofin agba nilẹ Naijiria lo du ipo gomina lọdun 2023, ṣugbọn to padanu sọwọ Gomina Seyi Makinde ti ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party.
Alli ni ẹgbẹ APC fa kalẹ lati du ipo gomina, lẹyin ọpọ faakaja to fi kọkọ waye laaarin gbogbo awọn to n foju sọna lati gba tikẹẹti ọhun bii Minisita fọrọ ina mọnamọna tẹlẹ, Adebayo Adelabu; Folarin funra rẹ ati awọn miran.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ keji, oṣu Keje, ọdun yii ni APC fa ọwọ Alli ati igbakeji rẹ, Adesoji Adedeji soke fun ipo gomina, eyi ti wọn sọ pe Aarẹ fọwọ si.
Kete ti eyi ṣẹlẹ ni Adelabu to kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii minisita lati du ipo ọhun ti sọ pe oun ko le tẹwọ gba abajade naa, to si sọ f'awọn ọmọ ẹyin rẹ lati fọkanbalẹ nitori pe erongba ti ko le fẹsẹ mulẹ ni.
Adelabu sọ pe o digba ti awọn alakoso ẹgbẹ naa lapapọ ba kede ọmọ oye fun ipo gomina Oyo koun too juwọ silẹ fẹnikẹni, nitori pe magomago ni wọn fi kede Alli.
Lara awọn to tun du u lati gba tikẹẹti naa ni igbekji gomina tẹlẹ, Rauf Olaniyan, Sẹnetọ Abdulfatai Buhari, Akeem Agbaje ati Oyedele Alao, ti gbogbo wọn si tako igbesẹ ẹgbẹ APC lori Alli ti ọn fa kalẹ.
Oniruuru wahala lo bẹ silẹ, pẹlu bi awọn tinu n bi ṣe n bẹ awọn alakoso ẹgbẹ lati tete ṣe atunṣe lori ipinnu wọn.
Ju gbogbo rẹ lọ, pẹlu gbogbo faakaja to waye naa, a gbọ pe Folarin pada juwọ silẹ, to si gba lati tẹle ipinnu ẹgbẹ.
Lasiko yii, a gbọ pe Folarin wa lara awọn alẹnulọrọ lẹgbẹ oṣelu APC ti ipa rẹ ko kere, to jẹ ọkan gboogi lara awọn ti yoo mu iṣọkan ati alaafia ba ẹgbẹ APC lasiko idibo 2027.
Bo tilẹ jẹ pe BBC ko le fidi rẹ mulẹ, ṣugbọn a gbọ pe Aarẹ ti ṣẹlẹri fun Folarin lati fi sinu awọn eto rẹ lati fun un ni ipo lati oke ati ni ipinlẹ, lẹyin idibo 2027.
Gbogbo ipalẹmọ ni wọn lo n ti lọ fun Folarin lati ba awọn ọmọ ẹyin rẹ sọrọ lori idagbasoke to waye nibi ipade to ṣe pẹlu aarẹ.
APC lo n foju sọna lati gba iṣakoso ipinlẹ Oyo lọdun 2027, lẹyin ti wọn ti padanu sọwọ Gomina Seyi Makinde lọdun 2019, ti wọn ko si tun ri ipo naa gba lọdun 2023.
Awọn oludije lẹgbẹ oṣelu APC juwọ silẹ
Gbogbo awọn adije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo ti inu n bi patapata ni wọn ti sọ pe awọn ti ṣetan lati dahun si ipe ti Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ba pe awọn lojuna lati f'opin si wahala to ṣe nilẹ lori eto idibo abẹle sipo gomina to waye laipẹ yii.
Ipinnu yii lo waye lẹyin ipade ti awọn oloṣelu naa ṣe lọtọọtọ pẹlu igbimọ to ri sọrọ eto idibo abẹle fun ipo gomina nipinlẹ Oyo, eyi ti ẹgbẹ APC gbe kalẹ lati wa ọna abayọ lori bi alaafia ati iṣọkan yoo ṣe pada jọba ninu ẹgbẹ, ṣaaju eto idibo ọdun 2027.
Ninu atẹjade abajade ipade to waye naa, ẹyi ti Sẹnetọ Olufemi Lanlehin ati Ọjọgbọn Taoheed Adedoja ti wọn jẹ alaga igbimọ oluwadii naa buwọ lu, wọn ni gbogbo awọn adije ati igun naa ni wọn ti gba lati ṣe ohun ti aarẹ ba n fẹ.
Igbimọ naa sọ pe awọn ṣe ipade pẹlu agbaagba bii igbakeji gomina tẹlẹ, Onimọ-ẹrọ Rauf Aderemi Olaniyan, Ọmọọba Asatola Ashanke, Ọmọwe Ololade Usman Bakare, Onimọ-ẹrọ Oyedele Hakeem Alao ati ỌMọwe Ayobami Lam-Adesina nibi ipade ti wọn ṣe lọjọ kẹjọ ati ọjọ kẹwaa, oṣu Keje, ọdun yii lọtọọtọ.
Wọn ni oludije miran, Ọmọwe Adewale Kolapo Kareem, ti gba lati juwọ silẹ lori wahala ati aawọ to n ṣẹlẹ, ati lati gba kamu lori ọmọ oye ti ẹgbẹ fa kalẹ.
Atẹjade naa fidi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn adije patapata ni wọn fi ẹhonu ati erongba wọn han lori ọna ti wọn gba ṣe idibo abẹle naa, ti wọn si ni lati ibẹrẹ titi de opin ni magomago fi wa.
Lẹyin gbogbo ẹhonu ti wọn fi han naa, gbogbo wọn lo pada gba lati ṣatilẹyin fun ipinnu ẹgbẹ, ki iyanju si le wa.
"Lojuna lati jẹ ki irẹpọ jọba, gbogbo awọn adije ni wọn gba lati bọwọ fun ipe Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, lati jiroro lori erongba ati ẹhonu wọn, lati le fi opin si gbogbo aawọ to wa nilẹ," atẹjade naa sọ bẹẹ.
Igbimọ ọhun wa fi ọkan gbogob awọn oludije patapata balẹ wi pe gbogbo ẹhonu wọn ni ẹgbẹ yoo dahun si, lai figba kan bo ọkan ninu, ati pe awọn yoo ṣe e bo ti tọ.
Bakan naa ni wọn tun sọ pe awọn yoo tẹsiwaju lati maa ba awọn adije yooku sọrọ, ki wọn le fi ẹnu ko lori ọna abayọ.
Adelabu fọnmú lórí bí wọ́n ṣe fa Alli kalẹ̀
Minisita tẹlẹ fọrọ ina mọnamọna nilẹ Naijiria, Adebayo Adelabu ti sọ pe bi wọn ṣe kede Sharafadeen Alli gẹgẹ bi oludije tẹgbẹ oṣelu APC fa kalẹ ko tẹle ilana.
Adelabu sọ pe afẹnujẹ lasan ni bi Alli ṣe n pe ara ni ọmọ oye fun ipo gomina ti APC fa kalẹ nipinlẹ Oyo, nitori pe awọn alakoso ẹgbẹ ko tii kede rẹ.
Agbẹnusọ Adelabu, Kọmureedi Femi Awogboro lo sọrọ naa ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọru, ọsẹ yii, to si jẹ ko di mimọ pe ẹgbẹ naa nilo lati tẹle ilana ati ofin to de eto idibo abẹle nilẹ Naijiria.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹgbẹ ko tii kede ẹnikẹni to jawe olubori ninu eto idibo abẹle naa, bẹẹ si ni wọn ko tii fi esi idibo naa sita fẹnikẹni lati ri.
Adelabu fi kun ọrọ rẹ pe bi ẹnikẹni ba lọ n kede ara rẹ gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori, ẹni naa kan n tan ara rẹ jẹ lasan, nitori pe ko lọwọ ofin ati awọn alaṣẹ ninu.





























