Mo Bimpe lérí láti gbé àwọn tó ní Lateef Adedimeji kọ́ ni bàbá àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sílé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, mo_bimpe ADEBIMPE OYEBADE/Instagram
"Ẹyin omugọ ti ẹ maa n tabuku eeyan ti n fi gbogbo igba tabuku mi lawọn oju opo yii fun ọpọ ọdun ti mo si maa n dakẹ fun yin, amọ ohun ti mi o ni i gba ni pe ki ẹ gbe iwa agọ̀ yin de ọdọ awọn ọmọ mi. Ẹ ṣọra yin! Mi o ni i lọra lati gbe igbesẹ to yẹ lori rẹ to ba doju ẹ."
Wọnyi ni ọrọ ti gbajumọ oṣerebinrin, Adebimpe Oyebade tawọn eeyan mọ si Mo Bimpe, gbe jade loju opo Instagram rẹ.
Eyi waye lẹyin ti awuyewuye kan gbode pe Lateef Adedimeji to jẹ ọkọ Mo Bimpe, kọ lo bi ni awọn Ibẹta ti wọn kede pe awọn bi loṣu Karun-ọdun yii .
Ohun to ṣẹlẹ gan-an
Ṣadeede ni ọrọ naa jẹ jade lori ayelujara, to si bẹrẹ si i tan bii ina inu ọyẹ, pe Lateef Adedimeji ti i ṣe ọkọ Mo Bimpe ti loun o fẹ ẹ mọ.
Iroyin naa sọ pe Lateef ti beere igbesẹ lati kọ Mo Bimpe to fẹ niṣu lọka silẹ.
Ẹnikan to pe ara rẹ ni @iam_Mardiyyah, loju opo X lo kọ ọ sibẹ pe ọkan lara awọn Ibẹta nilo ẹjẹ nileewosan ijọba apapọ to wa nipinlẹ Kwara.
O ni Lateef fi ẹjẹ silẹ amọ ileewosan naa kọ ẹjẹ rẹ pe ko ba ti ọmọ naa mu.
Eyi ni @iam_Mardiyyah sọ pe o fa a ti Lateef taye ti n pe ni Baba Ibẹta, fi beere fun ayẹwo ẹjẹ ti a mọ si DNA fun awọn ọmọ naa.
O ni ayẹwo si fi han pe oun kọ ni baba wọn.
Eyi lo ni o fa a ti gbajumọ oṣerekunrin naa fi ni oun ko fẹ Bimpe mọ, to si ti bẹrẹ igbesẹ ikọsilẹ pẹlu rẹ.
Labẹ ọrọ to kọ naa lo fi fọto si, eyi to ṣafihan Lateef ati Mo Bimpe ti wọn gbe awọn Ibẹta dani.
Bi iroyin naa ṣe di ohun ti wọn n pin kiri lori ẹka ayelujara ni Iya Ibẹta fi fesi loju opo rẹ Instagram rẹ, pe kawọn alahesọ dẹkun iroyin ẹlẹjẹ, bi wọn ko ba fẹ fi imu ko ata ofin.
Adebimpe kilọ pe oun ko fẹ mọ ohun ti ẹni naa pe orukọ ara rẹ, bi ko ba fi ọwọ sibi tọwọ n gbe, oun yoo fi ọrọ rẹ lọ kootu.
O ni toun ba gbe igbesẹ ofin lori ọrọ yii, oun ko ni i gba ẹbẹ rara, oun ko si fẹ gbọ ki ẹnikẹni maa beere idajọ ododo fun ẹni to wa nidii ibajẹ yii.
" Ohun to tiẹ jọ mi loju ni bo ṣe lo ayederu fọto AI pẹlu agbelẹrọ iroyin to to pọ. O ma laya o!"
Mo Bimpe lo sọ bẹẹ.
@iam_Mardiyyah ti pada kọ ohun to kọ soju opo X naa rẹ.
Ki lo ti ṣẹlẹ kọja?

Oríṣun àwòrán, Adedimeji Adetola Lateef / Instagram
Tẹ o ba gbagbe, obinrin ti oju ọmọ pọn nile ọkọ ko to di ọlọmọ ni Mo Bimpe.
Oṣerebinrin naa ṣegbeyawo pẹlu Lateef Adedimeji loṣu Kejila ọdun 2021, amọ awọn mejeeji ko tete ri ọmọ bi.
Ni gbogbo asiko ti wọn fi n wa ọmọ naa ni awọn eeyan kan maa n sọ ọrọ kobakungbe si Mo Bimpe lori aibimọ rẹ.
Bii ki wọn ni o ti fi ile ọmọ rẹ wa okiki ni ko ṣe rọmọ gbejo.
Ọtọ nigba ti ẹnikan bu u pe aṣọ lo fi n ṣakọ lori ayelujara lai ronu pe ko ti i bimọ lati ọdun bii mẹta to ti ṣegbeyawo.
Ẹnu ọrọ ẹgan bawọnyi ni Mo Bimpe wa titi di oṣu Karun-un ọdun 2025, ti oun ati Lateef kede pe awọn ti bi ibẹta ti wọn jẹ ọkunrin.
Awọn afẹnifẹre ba wọn yọ titi fun oore adipele naa,kaluku n lọ ki wọn pẹlu ẹbun, ẹkun airọmọbi si di ẹrin fun Lateef ati Adebimpe aya rẹ.
Amọ oṣu keji lẹyin ikede pe awọn bimọ ni awọn kan si tun wa bẹrẹ si i gbe kiri pe ọkọ Mo Bimpe kọ lo bimọ fun, ti wọn tun fi kun un pe igbeyawo wọn ti fẹ fori sọgi.
Amọ Mo Bimpe ti ni ibajẹ lasan leyi, ko sohun to jọ bẹẹ, yoo si lẹyin fẹni toun ba mu fi jofin.




























